Posts

Showing posts from October, 2014

Aye Si N Be Nile Od'aguntan

Words: Horatius Bonar (1808-1889), 1872 Music: Cantus (Uzziah C. Burnap, 1895) Aye si n be nile Od'agutan Ewa ogo Re n pe O pe ma bo Wole, wole, wole nisisiyi Ojo lo tan, orun si fere wo, Okunkun de tan, mole n koja lo Wole, wole, wole nisisiyi Ile iyawo na kun fun ase! Wole, wole to Oko 'yawo: Wole, wole, wole nisisiyi. "Aye si n be!" ilekun si sile, Ilekun ife: iwo ko pe ju, Wole, wole, wole nisisiyi Wa gbebun 'fe ayeraye lofe! Wole, wole, wole nisisiyi. Kiki ayo lo wa nibe, wole! Awon Angel lo npe o fun ade; Wole, wole, wole nisisiyi. Lohun rara nipe ife naa ndun! Wa, ma jafara, wole ase naa. Wole, wole, wole nisisiyi. O n kun, o n kun! Ile ayo na n kun! Yara! mase pe, ko kun ju fun o. Wole, wole, wole nisisiyi. Kile to su, ilekun na le ti! 'Gbana, o kabamo! "O se! O se!" O se! O se! Ko saye mo, o se! "Yet there is room": the Lamb's bright hall of song, With its fair glory, beckons thee along;

FUN MI NIWA PELE

Fun mi niwa pele, okan tutu; Ifarabale bi toluwa mi; Irele o'n suuru atopo iyonu Ninu ohun gbogbo ki n jo Jesu. Fun mi nitelorun nipokipo Ko le rele juyi ta bi Jesu Fun mi nitunu Re atiranlowo Re Ninu ohun gbogbo, ki n jo Jesu. Fun mi ni itara sipa Tire; Aniyan atife sohun torun Fun mi niwa mimo, ikorira ese Ninu ohun gbogbo ki n jo Jesu. Fun mi ni igbagbo atireti Fun mi layo'gbala ninu Jesu; Femi iye fun mi, fun mi lade ogo 'Gbati mo ba jinde ki n jo Jesu. Give me a gentle heart filled with meekness diligent heart like thine Jesus, my lord humbleness and patience a heart of compassion, in every small detail to be like him. Give me contentment in all conditions be it even humbler than his lowly birth give me thou thy comfort give me also thy help in every small detail to be like him. Give me enthusiasm in things of thine earnestness and more love for things of heaven give me a holy heart give me hatred for sin in every small de

Mo Fe Ki N Dabi Jesu

Author: W. Meynell Whittemore  Mo fe ki n dabi Jesu Ninu iwa pele Ko seni to gboro 'binu Lenu Re lekan ri. Mo fe ki n dabi Jesu, Ladura n'gbagbogbo Lori oke ni Oun nikan Lo pade Baba Re. Mo fe ki n dabi Jesu, Emi ko ri ka pe Bi won ti korira Re to O senikan nibi. Mo fe ki n dabi Jesu Ninu ise rere Ka le wi nipa temi pe, "O se'won to le se" Mo fe ki ndabi Jesu To fiyonu wipe "Je komode wa sodo mi" Mo fe je ipe Re. Sugbon n ko dabi Jesu O si han gbangba be; Jesu fun mi lore-ofe Se mi ki n dabi Re. I want to be like Jesus, So lowly and so meek, For no one marked an angry word That every heard Him speak. I want to be like Jesus, So frequently in prayer; Alone upon the mountain-top, He met His Father there. I want to be like Jesus, I never, never find That He, though persecuted, was To any one unkind. I want to be like Jesus, Engaged in doing good, So that of me it may be said, `She hath done what she could

Olorun Odun To Koja

Words: Isaac Watts (1674-1748), 1719 Olorun odun to koja, Iret'eyi ti nbo: Ib'isadi wa ni iji, Atile wa lailai. Labe ojiji ite Re lawon eniyan Re n gbe! Tito lagbara Re nikanso Abo wa si daju. Kawon oke ko to duro Tabi ka to daye Lailai Iwo ni Olorun Bakanna, lailopin. Egberun odun loju Re Bi ale kan lo rí; B'iso kan l'afemojumo Kí oorun ko to la. Ojo wa bi odo sisan, Opo lo si n gbe lo; Won n lo, won di eni  'gbagbe Bi ala ti a n ro. A mu eje a'tebe wa Wa si waju 'te Re Iwo yio je Olorun wa A t'ipin wa lailai Olorun odun to koja Iret'eyi ti nbo: Ib'isadi wa ni iji, Atile wa lailai. O God, our help in ages past, our hope for years to come, our shelter from the stormy blast, and our eternal home: Under the shadow of thy throne, thy saints have dwelt secure; sufficient is thine arm alone, and our defense is sure. Before the hills in order stood, or earth received her frame, from everlasting thou ar

GBORI RE SOKE ALAARE

Image
Mary M. Weinland, 1887 Gbori re soke alare Tori ayo n bo lowuro Olorun so n'nu oro Re Pe ayo ma n bo lowuro Refrain: Ayo ma n bo lowuro/2x Ekun le pe titi dale Sugbon ayo n bo lowuro Eyin mimo ma beru mo Tori ayo n bo lowuro Eyin olofo nuju nu Tori ayo n bo lowuro E yo oru fere koja Tori ayo n bo lowuro Ooro to logo yoo si de Tori ayo n bo lowuro Ki gbogbo wa ma yo loni Tori ayo n bo lowuro Olorun yoo n'omije nu Tori ayo n bo lowuro Oh, weary pilgrim, lift your head: For joy cometh in the morning! For God in His own Word hath said That joy cometh in the morning! Joy cometh in the morning! Joy cometh in the morning! Weeping may endure for a night, But joy cometh in the morning! Ye trembling saints, dismiss your fears: For joy cometh in the morning! Oh, weeping mourner, dry your tears: For joy cometh in the morning! Let every burdened soul look up: For joy cometh in the morning! And every trembling sinner hope: For joy cometh in

NIPA IFE OLUGBALA

Words: Mary B. Peters Nigba ife Olugbala, Ki yo si nkan Oju rere Re ki pada Ki yo si nkan Owon l'Eje to wo wa san Pipe ledidi oor'ofe Agbara lowo to n gba ni Ko le si nkan Bi a wa ninu iponju Ki yo si nkan Igbala kikun ni tiwa Ki yo si nkan Igbekele Olorun dun Gbigbe ninu Kristi lere Emi si n so wa di mimo Ko le si nkan Ojo ola yio dara Ki yo si nkan 'Gbagbo le korin n'nu'ponju Ki yo si nkan A gbekele'fe Baba wa Jesu fun wa lohun gbogbo Ni yiye tabi ni kiku Ko le si nkan Through the love of God our Savior, All will be well; Free and changeless is His favor; All, all is well. Precious is the blood that healed us; Perfect is the grace that sealed us; Strong the hand stretched out to shield us; All must be well. Though we pass through tribulation, All will be well; Ours is such a full salvation; All, all is well. Happy still in God confiding, Fruitful, if in Christ abiding, Holy through the Spirit’s guiding, All must

Gbati Ipe Oluwa Ba Dun

Words & Music:   James M. Black , 1893 Gbati ipe Oluwa ba dun T'akoko ba si pin T'imole owuro mimo n tan lailai; Gbat'awon ta ti gbala Yo pejo soke odo naa, Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe. Gba ta n pe oruko lohun Gba ta n pe oruko lohun Gba ta n pe oruko lohun Gba ta n pe oruko lohun N o wa nbe. Looro daradara tawon Oku mimo y'o dide Togo ajinde Jesu o je tiwon Gba t'awon ayanfe Re yo Pejo nile lok'orun, Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe. Je ka sise f'Oluwa Latowuro titi dale Ka soro 'fe yanu ati'toju Re; Gbat aye ba dopin tise Wa Si pari nihin, Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe. When the trumpet of the Lord shall sound, and time shall be no more, And the morning breaks, eternal, bright and fair; When the saved of earth shall gather over on the other shore, And the roll is called up yonder, I’ll be there. When the roll, is called up yon-der, When the roll, is called up yon-der, When the roll, is call

IWO HA N BERU P'OTA YOO SEGUN

Words: Ada Blenkhorn Iwo ha n beru p'ota yoo segun? Ookun su lode osi su ju ninu? Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole Refrain: Je ki 'ran oorun wole/2x Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole. Igbagbo re n kere 'nu 'ja tiwo fe? Olorun ko ha gbo adura re bi? Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole Iwo fe fi ayo lo soke orun? Ko si oorun mo bi ko se imole? Si ferese ati ilekun sile Je ki 'ran oorun wole Do you fear the foe will in the conflict win? Is it dark without you—darker still within? Clear the darkened windows, open wide the door, Let a little sunshine in. Let a little sunshine in, Let a little sunshine in; Clear the darkened windows, Open wide the door, Let a little sunshine in. Does your faith grow fainter in the cause you love? Are your prayers unanswered by your God above? Clear the darkened windows, open wide the door, Let a little sunshine in. Would you go rejoicing in the