Posts

Showing posts from December, 2014

Onigbagbo E Bu Sayo

Author: John E. Bowers Onigbagbo e bu sayo! Ojo nla loni fun wa Korun fayo korin kikan, Kigbo atodan gberin E ho! E yo! Okun atodo gbogbo. E jumo yo, gbogbo eda, Laye yi ati lorun, Ki gbogbo ohun alaaye Nile, loke, yin Jesu E fogo fun Oba nla ta bi loni. Gbohun yin ga, "Om'Afrika" Eyin iran Yoruba; Ke "Hosanna" lohun gooro Jake jado ile wa. Koba gbogbo, Juba Jesu Oba wa. E damuso! E damuso! E ho ye! Ke si ma yo, Itegun Esu fo wayi, "Iru-omobinrin" de. Halleluyah! Olurapada, Oba. E gbohun yin ga, Serafu, Kerubu, leba ite; Angeli ateniyan mimo, Pelu gbogbo ogun orun. E ba wa yo! Odun idasile de. Metalokan, Eni Mimo Baba Olodumare Emi Mimo, Olutunnu, Jesu, Olurapada, Gba iyin wa 'Wo nikan logo ye fun. Christians lift your voice in praises On this memorable day Sing in gladness, let your voices Sing all over vale and dale Laud Hosannas, laud Hosannas, Sea and streams all join the strain. Come ye peo

WA EYIN OLOOTO

Words: John Francis Wade Wa eyin olooto Layo ati'segun Wa kalo, wa kalo si Betlehem Wa ka lo wo o! Oba awon Angeli! E wa ka lo juba Re/2X E wa ka lo juba Kristi Oluwa Olodumare ni, Imole Ododo, Ko si korira inu wundia; Olorun paapaa ni Ti a bi, ti a ko da; Angeli, e korin, Korin itoye Re, Ki gbogbo eda orun si gberin: Ogo f'Olorun Li oke orun, Nitooto, a wole F'Oba ta bi loni; Jesu, Iwo lawa n fi ogo fun, 'Wo Omo Baba, T'O mara wa wo! O come, all ye faithful, joyful and triumphant! O come ye, O come ye to Bethlehem! Come and behold him, born the King of angels; O come, let us adore him, O come, let us adore him, O come, let us adore him, Christ the Lord! God of God, Light of Light eternal, lo, he abhors not the virgin’s womb; Son of the Father, begotten, not created; Sing, choirs of angels, sing in exultation, sing, all ye citizens of heaven above: “Glory to God, all glory in the highest!” Yea, Lord, we greet thee, bor

GBO OHUN ALORE

Words: Horatius Bonar Gbo ohun alore, Ji, ara, ji; Jesu ma fere de, Ji, ara, ji, Omo oru ni sun, Omo imole leyin, Ti yin logo didan, Ji, ara, ji. So fegbe to ti ji, Ara, sora; Ase Jesu daju, Ara, sora; E se b'olusona Nilekun Oluwa yin Bi O tile pe de, Ara, sora. Gbo ohun iriju, Ara, sise; Ise na kari wa, Ara, sise; Ogba Oluwa wa, Kun fun'se nigba gbogbo Yoo si fun wa lere, Ara sise. Gbo ohun Oluwa wa, E gbadura; Be fe kinu Re dun E gbadura; Ese 'mu beru wa, Alailera si ni wa; Ni ijakadi yin, E gbadura Ko orin ikehin, Yin, ara, yin; Mimo ni Oluwa. Yin, ara, yin: Ki lo tun ye ahon, To fere b'Angel' korin, T'y'o ro lorun titi, Yin, ara, yin. Hark! ’tis the watchman’s cry, Wake, brethren, wake! Jesus our Lord is nigh; Wake, brethren, wake! Sleep is for sons of night; Ye are children of the light, Yours is the glory bright; Wake, brethren, wake! Call to each waking band, Watch, brethren, watch! Clear is

Aajin Jin, Oru Mimo

Words: Joseph Mohr Aajin jin, oru mimo, Ookun su, mole de, Awon Olus'aguntan n sona, Omo to wa loju orun,   Sinmi n'nu alafia   Sinmi n'nu alafia. Aajin jin, oru mimo, Mole de, ookun sa, Oluso aguntan gborin Angel', Kabiyesi aleluya Oba.   Jesu Olugbala de   Jesu Olugbala de. Aajin jin, oru mimo, 'Rawo orun tan mole Wo awon Amoye ila orun Mu ore won wa fun Oba wa,   Jesu Olugbala de   Jesu Olugbala de. Aajin jin, oru mimo, 'Rawo orun tan 'mole Ka pelu awon Angel korin, Kabiyesi aleluya Oba   Jesu Olugbala de   Jesu Olugbala de. Silent night! Holy night! All is calm, all is bright ’round yon virgin mother and child! Holy infant, so tender and mild, sleep in heavenly peace, sleep in heavenly peace. Silent night! Holy night! Shepherds quake at the sight. Glories stream from heaven afar, heavenly hosts sing: “Alleluia! Christ the Savior is born! Christ the Savior is born!” Silent night! Holy night! Son of God, love

O De

O de, Kristi Oluwa, Lat'ibugbe Re lorun, Lat'ite alafia, O wa si aginju wa. Alade Alana De lati ru 'ponju wa; O de, lati f'imole, Le okun oru wa lo. Jesus Christ the Lord has come, From His Father's throne above. From above the throne of peace. He came to this wilderness. Christ the Lord the Prince of Peace Come to bear all our burden, He has come to give us light, Drives away all our nightmare. Source: Hymnaro #92 Aroyehun ©2013

Wo Oju Sanma

Wo oju sanma ohun ni, Wo lila orun ooro; Ji loju orun, okan mi, Dide ko si ma sora; Olugbala Tun n pada bo wa saye. Ope ti mo ti n reti Re, L'are lokan mi n duro, Aye ko ni ayo fun mi, Nibi ti ko tan 'mole, Olugbala, 'Gbawo n'Iwo o pada? Igbala mi sunm' etile, Oru fere koja na, Je ki n wa nipo irele, Ki n s'afojusona Re, Olugbala Titi n o fi roju Re. Je ki fitila mi ma jo, Ki n ma sako kiri mo, Ki n sa ma reti abo Re, Lati mu mi lo sile; Olugbala Yara k'O ma bo kankan. Behold, see yonder horizon Behold the morning sunrise Wake from thy deep sleep, thou my heart Arise and be thou watchful; Blessed Saviour, blessed Saviour Coming again to the earth It's long I've been expecting Thee My weary heart long doth wait The world has no more joy for me, E'er its light has become dark Blessed Saviour, blessed Saviour, When will Thou come back again My salvation doth draw nearer The dark night is almost gone Let

Ma Wole, Jesu Ta N Reti

Ma wole, Jesu ta n reti, Ta bi lati gba ni la! Gba wa low'ese ate'eru; Ka ri'sinmi ninu Re. Ipa ati'tunu Israel', Ireti awon mimo; Olufe gbogbo orile, Ayo okan ti n reti. A bi O lati gbeda la, Eniyan--sugbon Olorun-- Lati joba lai ninu wa, Mu 'joba rere re wa. Nipa Emi Re to wa lai, Nikan joba ninu wa; Nipa 'toye Re to po to Gbe wa site ogo Re. Long expected, our Lord Jesus, Born to give us salvation, Redeem us from fear and sin Give us peace eternally/2x Pow’r, peace and joy for Israel, The hope of righteous men, Lover of the entire nations; Joy for the expectant souls/2x Born to give us salvation, God born of human flesh To reign in heart for ever, Send down Thou good governance/2x By the Spirit forever more, Reign forever in our souls By the great mercies forever, Reign with You all ever more /2x Source: Hymnaro #88 Aroyehun ©2013

AYO BAYE

Words: Isaac Watts (1674-1748), 1719 Ayo baye: Oluwa de! Kaye gba Oba re; Kokan gbogbo pes'aye fun Un, Ki gbogbo eda korin. Ayo baye: Jesu joba; Ki eniyan korin; Gbati ohun gbogbo laye Tun n ro iro iro ayo. Kese at'ikanu ye wa Kile ye hu egun; O wa lati da ibukun Sori egun gbogbo. O n fotito joba laye, O si m' oril 'ede Jeri ogo at'oto Re, At'iyanu 'fe Re. Joy to the world! the Lord is come: let earth receive her King; let every heart prepare him room, and heaven and nature sing. Joy to the world! the Savior reigns; let us our songs employ, while fields and floods, rocks, hills and plains repeat the sounding joy. No more let sins and sorrows grow, nor thorns infest the ground; he comes to make his blessings flow far as the curse is found. He rules the world with truth and grace, and makes the nations prove the glories of his righteousness, and wonders of his love.

Igbagbo Mi N Wo O

Words: Ray Palmer, 1830 Igbagbo mi n wo O, Iwo Od'Aguntan, Olugbala, Jo, gbo adura mi Mese mi gbogbo lo Kemi latoni lo si je tire. Ki ore-ofe Re, Filera fokan mi, Mu mi tara; Biwo ti ku fun mi, A! kife mi si O, Ko ma gbona titi, Ina iye. Gba mo rin lokunkun, Tibinu yi mi ka, Samona mi, Mokunkun lo loni, N'omije anu nu, Lai, ma je ki n sako Li odo Re. Gbati aye ba pin, Todo tutu iku, Nsan lori mi: Jesu, ninu ife, Mu kifoya mi lo, Gbe mi doke orun Bokan ta ra. My faith looks up to Thee, Thou Lamb of Calvary, Savior divine! Now hear me while I pray, take all my guilt away, O let me from this day be wholly Thine! May Thy rich grace impart Strength to my fainting heart, my zeal inspire! As Thou hast died for me, O may my love to Thee, Pure warm, and changeless be, a living fire! While life’s dark maze I tread, And griefs around me spread, be Thou my guide; Bid darkness turn to day, wipe sorrow’s tears away, Nor let me ever stray from

Bibeli Mimo Torun

Words: John Burton, Sr., Youth’s Mon­i­tor in Verse, 1803. Bibeli mimo torun Owon isura temi! 'Wo ti n wi bi mo ti ri, 'Wo ti n so bi mo ti wa. 'Wo nko mi, bi mo sina, 'Wo n f'ife Oluwa han; 'Wo lo si n to ese mi, 'Wo lo n dare at'ebi. 'Wo ni ma tu wa ninu, Ninu wahala aye, 'Wo n ko ni, nipa 'gbagbo Pe a le segun iku. 'Wo lo n so tayo ti n bo, Ati 'parun elese; Bibeli mimo torun, Owon isura temi. Holy Bible, Book divine, Precious treasure, thou art mine; Mine to tell me whence I came; Mine to teach me what I am. Mine to chide me when I rove; Mine to show a Savior’s love; Mine thou art to guide and guard; Mine to punish or reward. Mine to comfort in distress; Suffering in this wilderness; Mine to show, by living faith, Man can triumph over death. Mine to tell of joys to come, And the rebel sinner’s doom; O thou holy Book divine, Precious treasure, thou art mine.

Itan Iyanu Tife

Author: J. M. Driver (1892) Itan iyanu tife! So fun mi leekan si, Itan iyanu tife! Ti n dun leti kikan! Awon angeli rohin re, awon oluso si gbagbo, Elese iwo ki yoo gbo, itan iyanu tife? Iyanu!/3X Itan iyanu tife! Itan iyanu tife! Biwo tile sako Itan iyanu tife!Sibe o n pe loni; Latori oke Kalfari, lati orisun Krystali; Lat isedale aye; Itan iyanu tife! Itan iyanu tife! Jesu ni isimi; Itan iyanu tife! Fun awon olooto, To sinmi nilu nla orun, pel' awon to saju wa lo; Won n kan orin ayo orun: Itan iyanu tife! Wonderful story of love; Tell it to me again; Wonderful story of love; Wake the immortal strain! Angels with rapture announce it, Shepherds with wonder receive it; Sinner, oh, won’t you believe it? Wonderful story of love. Wonderful! Wonderful! Wonderful, wonderful story of love. Wonderful story of love; Though you are far away; Wonderful story of love; Still He doth call today; Calling from Calvary’s mountain, Down from the crystal-br

O N To Mi Lo

Author: Gilmore, Joseph Henry O n to mi lo iro 'bukun, Oro torun tu mi ninu, Ohun tio wu kemi se Sibe Olorun n to mi lo. Refrain: O n to mi lo, O n to mi lo, Owo Re lo fi n to mi lo, Lotito ni mo fe tele E Nitoriti O n to mi lo Nigba miran tiponju wa, Nigba miiran logba Eden Leba odo lokun 'ponju, Sibe Olorun n to mi lo. Oluwa mo dowo Re mu N ko ni kun, n ko ni ibanuje, Fohun 'yowu ti mo le ri Niwon t'Olorun mi n to mi Nigba 'se mi laye ba pin, Toor'ofe Re fun mi nisegun, Emi ko ni beru iku, Niwon t'Olorun mi n to mi. He leadeth me! O blessed thought, O words with heav’nly comfort fraught; Whate’er I do, where’er I be, Still ’tis Christ’s hand that leadeth me. He leadeth me, he leadeth me; by his own hand he leadeth me: his faithful follower I would be, for by his hand he leadeth me. Sometimes mid scenes of deepest gloom, sometimes where Eden's flowers bloom, by waters calm, o'er troubled sea, still '

To Won Baba Si O

Author Unknown To won, Baba si O, To won si O; Awon omo wonyi Ti O fun ni, Nipa 'fe Re orun, To won Baba si O, To won, Baba si O, To won si O. Gbati aye ba n dan Ko won lona Re, Ma je kohun etan Mu won sina. Kuro nipa 'danwo To won Baba si O, To won, Baba si O, To won si O. Fun 'ru won ni Jesu Wa lomode, O si gbaye ese Lailabawon; A! 'Tori Re ma sai To won Baba si O, To won, Baba si O, To won si O. 'Gbagbo mi le sai pe Sibe mo mo Pawon ore wonyi 'Wo yoo gba won; A! Gb' okan won sodo Ko si to won si O To won, Baba si O, To won si O. Source: YBH #430 (I adjusted line 2 of verse 2) Guide them, Father to thee, guide them to Thee All these thy great children, that Thou giveth Lord, By Thy heav'nly love, Guide them Father to Thee Guide them, Father to thee, guide them to Thee When this life is sweet, train them Thy way, Let not deceitful treasure mislead them all, Away from temptation, guide them Father to Thee