Featured post

KRIST' KI 'JOBA RE DE

Words: Lewis Hensley, 1867 Music: St. Cecilia, Kingsland Krist' ki 'joba Re de, Ki ase Re bere; F' opa-rin Re fo Gbogbo...

Thursday, 26 November 2015

Olorun Awa Fe

Olorun awa fe,
Ile t' ola Re wa;
Ayo ibugbe Re
Ju gbogbo ayo lo.

Ile adura ni,
Fun awon omo Re
Jesu si wa nibe,
Lati gbo ebe won.

Awa fe ase Re,
Ti nte okan l' orun
Iwo l' onje iye,
Ti onigbagbo nje.

Awa fe oro Re,
Oro alafia
T' itunu at 'iye
Oro ayo titi.

Awa fe orin Re,
Ti a nko l' aiye yi;
Sugbon awa fe mo,
Orin ayo t' orun.

Jesu Oluwa wa,
Busi 'fe wa nihin;
Mu wa de 'nu ogo,
Lati yin O titi.

Source: Yoruba Baptist Hymnal #42

3 comments: