Posts

Showing posts from October, 2018

Oba aiku, Airi, Orisun Ogbon/Immortal, Invisible God Only Wise

William Cowper, 1731-1800 Oba aiku, airi, orisun ogbon T'O wa n'nu imole toju ko le wo, Olubukunjulo, Ologojulo, Alagbara, Olusegun, 'Wo la yin. Laisimi, laiduro, ni idakeje, O n joba lo, O ko si se alaini; Giga ni idajo Re bi oke nla, Ikuku Re b'isun ire at'ife. O nte gbogbo eda alaye lohun, Nipa imisi Re won gbe igbe won A n dagba, a n gbile bi ewe igi, A si n ro; sugbon bakanaa l'Olorun. Baba nla Ologo, Imole pipe Angeli Re n juba, won bo oju won: Gbogbo 'yin la o mu wa, sa je ka ri O Ka ri olanla imole to bo O. Source: CAC Hymnal #99 Verse 4 retranslated by Ayobami Temitope Kehinde Oct 23, 2018. Immortal, invisible, God only wise, In light inaccessible hid from our eyes, Most blessed, most glorious, the Ancient of Days, Almighty, victorious, Thy great name we praise. Unresting, unhasting, and silent as light Nor wanting nor wasting, Thou rulest in might Thy justice like mountains high soaring above Thy clouds wh

Oluwa Ran Mi Nise/Look and Live

Author: William A. Ogden (1841-1897) Oluwa ran mi ni ‘se, Aleluya! Iwo ni n o je ise na fun; A ko s‘inu Oro Re, Aleluya! P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye. Egbe Wo, k‘o ye, Arakunrin, Wo Jesu ki o si ye, A ko s‘inu Oro Re, Aleluya! P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye. A ran mi n‘ise ife,  Aleluya!  N o j‘isena fun o ore mi; Ise lat‘ oke wa ni; Aleluya! Jesu so, mo mo pe oto ni. A n‘owo iye si O, Aleluya! A o fi ‘ye ailopin fun O; T‘o ba wo Jesu nikan, Aleluya! Wo o, On nikan l‘o le gbala. Ma wi fun o bi mo se wa, Aleluya! Sodo Jesu to so mi dotun Mo gbagbo n'nu oruko Re, Aleluya! Mo gbekele O si gb'okan mi. Egbe  Source: Verses 1-3 from CAC Hymnal #208 Verse 4 translated by Ayobami Temitope Kehinde, October 23, 2018 I’ve a message from the Lord, hallelujah! This message unto you I’ll give, ’Tis recorded in His word, hallelujah! It is only that you “look and live.” Refrain: "Look and live", my brother live Look to Jesus now, and live; ’T

Gbagbo Awon 'Ya Wa / Faith of Our Mothers

Author:  Arthur Bardwell Patten Gbagbo awon 'ya wa, 'gbagbo aaye Nn' orin at'adura, ale; N' alo at' ife eba ina, Ibagbe re si wa yi wa ka, 'Gbagbo' awon 'ya wa, aaye ni, Ao di o mu titi d'opin. 'Gbagbo awon 'ya wa, aaye ni, 'Bi 'gbekele 't' or'ofe ti nwa Yiya si mimo re ba a le je, 'Bere iran olola nla; Igbagbo 'ya wa, ife ni, Ao di o mu titi d'opin. 'Gbagbo awon 'ya wa nfona han ni, Nnu 'reti at' aigbagbo odo, B'oju at'ona wa tile sookun, T'ao ko tile le r'itoju Re. 'Gbagbo Iya wa, ti Kristi ni, Ao di o mu titi d'opin. 'Gbagbo Iya wa, ti Kristi ni, N'otito to ta 'jewo way o, O ntoju 'le o si gba ijo la, Iwa wa si nf' emi re han; 'Gbagbo 'ya wa ti Kristi ni, Ao di o mu titi d'opin. Source: Yoruba Baptist Hymnal #619 Faith of our mothers, living still  In cradle song and bedtime prayer, In nurs'

Kábíyèsí O, Hòsánnà O

Author: Segun Roberts Kábíyèsí o, hòsánnà o Ẹ yin Jésù Kristì Ọba àìkú Kabiyesi o, hosanna o Ẹ yin Jésù Kristì Ọba àìkú Ègbè Ẹ gbé E ga, Ẹ yin Jésù o Ẹ yin Jésù Kristì Ọba àìkú [Repeat] Wá ká yin Jésù, ará mi ò Ọba mímọ́ Jésù, Ọba àìrí Wá júbà Jésù Olúwa ò Yin Elédùmarè Ọba àìkú Ègbè Ọbańgijì yé o, Olúwa ò Wá gbọpẹ́ wá gba ìyìn àwa ọmọ Rẹ Ángẹ́lì lọ́run ẹ bá wa yìn Ẹ yin Jésù Krístì Ọba àìkú Ègbè Alelúyà sí Ọ Olúwà o Ọpẹ́, ọlá, ìyìn sí Olùbùkún Ho-hosanna, alelúyà o Ẹ yin Jésù Krístì Ọba àìkú Ègbè Unquestionable God, hosanna to You Praise Jesus Christ the immortal King Unquestionable God, hosanna to You Praise Jesus Christ the immortal King Refrain Lift Him up, oh now  praise Jesus Praise Jesus Christ the immortal King Come let’s praise Jesus o my brethren Holy King Jesus, the immortal King Come and worship Jesus the Lord Praise the Almighty, the immortal King Refrain The Most