Posts

Showing posts with the label Christmas Carol

Gbo 'gbe ayo! Oluwa de / Hark! The Glad Sound

Author:Philip Doddridge Gbo 'gbe ayo! Oluwa de, Jesu t' a seleri; Ki gbogbo okan mura de, K' ohun mura ko ' rin O de lati t' onde sile, L' oko eru Esu; 'Lekun 'de fo niwaju Re, Sekeseke 'rin da.     O delarin 'baje aiye Lati tan 'mole Re, Lati fun awon afoju N' iriran f' oju  won. O de! 'Tunu f' okan 'rora, Iwosan f' agbogbe; O de pel' opo 'sura Re Fun awon talaka. Hosanna wa, Oba 'lafia Ao kede bibo Re; Gbogbo orun y'o ma korin Oruko t' a feran. Source: YBH #90 Hark, the glad sound! The Savior comes, the Savior promised long! Let ev'ry heart prepare a throne, and ev'ry voice a song. He comes the pris'ners to release, in Satan’s bondage held; the gates of brass before Him burst, the iron fetters yield. He comes from thickest films of vice To clear the mental ray And on the eyeballs of the blind To pour celestial day.

Laarin Gbungbun Oye/ In The Bleak Midwinter

Image
Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìjì dídì ń sọkún Ayé le bí irin Omi bí òkúta Yìnyín bọ́ lórí yìnyín Lórí yìnyín Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Lọ́jọ́ ọjọ́un Ọlọ́run wa, ọ̀run kò gbàá,  Ayé kò lè gbée ró Ọ̀run, ayé yóò kọjá lọ 'Gb' Ó bá wá jọba. Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìbùjẹ́ ẹran tó fún Olúwa Alágbára Jésù Kristi.  Ó tó f' Ẹni tí Kérúbù Ń sìn lọ́saǹ lóru: Ọmú tó kuń fún wàrà Koríko ilé ẹran Ó tó f' Ẹni t'Angel' Ń wólẹ̀ fún o, Màálù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí Tí ń júbà Rẹ̀ Angel' nípò dépò 'Bá péjọ síbẹ̀ Kérúbù, Séráfù 'Bá wa 'nú afẹ́fẹ́; Ṣùgbọn Màmá Rẹ̀ nìkan, Wúndíá pẹ̀l' áyọ́ Fi ìfẹnukonu Sin Àyànfẹ́. Kínni mo lè fi fún Un, Èmi òṣì, àre Ǹ bá j' olúṣ'àgùntàn, Ǹ bá  fún Un l' ọ̀d'àgùntàn Ǹ bá jẹ́ Amòye Ǹ bá sápá tèmi, — Síbẹ ohun mo ní, mo fún Un, — Ọkàn mi. Trans

Gbogb' Ọkàn Mí Yọ̀ Lálẹ́ Yìí / All My Heart This Night Rejoices

Image
Author: Paul Gerhardt English Translator: Catherine Winkworth Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Gbogb' ọkàn mí yọ̀ lálẹ́ yìí Bí mo tí ń gbọ́ Nílé lóko Ohùn áńgelì dídùn “A bí Krist'”, akọrin ń kọrin Títí i- bi gbogbo Yóò fi rinlẹ̀ fáyọ̀. ‘Jagunsẹ́gun ń jáde lọ lónì í Ó borí ọ̀tá, ẹ̀ṣẹ̀, ’Bìnújẹ́, ’kú, ’pò òkú Ọlọ́run dèèyàn láti gbà wá Ọmọ Rẹ̀, Ó jọ́kan Pẹ̀l' ẹ̀jè wa títí. A ṣì ń bẹ̀rù ’bín' Ọlọ́run, T’Ó fi fún wa Lọ́fẹ̀ ‘Ṣura Rẹ̀ tó ga jù? Láti rà wa padà l'Ó fún wa L’Ọmọ Rẹ̀ Látorí ’tẹ́ Ipá Rẹ ní ọrùn Ó d'Ọ̀dọ́ Àgùntàn t'Ó mú Ẹ̀ṣẹ̀ lọ́ Ó sì ṣe Ìpẹ̀tùsí  kíkún Ó fẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: Ìran wa Níp' oor'ọ̀fẹ́ Rẹ̀ a yẹ fún ògo. Gbóhùn kan láti ’bùjẹ́ ’ran Dídùn ni, Ó ń bẹ̀bẹ̀, “Sá fún ’dààmú, ewù Ará, ẹ ti gbà ’dásílẹ̀ Lọ́wọ́ ibi, Ohun ẹ nílò Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Wá wàyí, lé bànújẹ́ lọ Gbogbo yín, Lọ́kọ̀kan,

Gbo 'Gbe Ayo/Hark the Glad Sound

Philip Doddridge, 1702-1751 Gbo 'gbe ayo! Oluwa de, Jesu t' a seleri; Ki gbogbo okan mura de, K' ohun mura ko ' rin O de lati t' onde sile, L' oko eru Esu; 'Lekun 'de fo niwaju Re, Sekeseke 'rin da. O delarin 'baje aiye Lati tan 'mole Re, Lati fun awon afoju N' iriran f' oju  won. O de! 'Tinu f' okan 'rora, Iwosan f' agbogbe; O de pel' opo 'sura Re Fun awon talaka. Hosanna wa, Oba 'lafia Ao kede bibo Re; Gbogbo orun y'o ma korin Oruko t' a feran. Hark the glad sound! The Savior comes, The Savior promised long; Let every heart prepare a throne And every voice a song. He comes the prisoners to release, In Satan's bondage held. The gates of brass before Him burst, The iron fetters yield.   He comes from thickest films of vice To clear the mental ray And on the eyeballs of the blind To pour celestial day.   He c

GBO OHUN ALORE

Words: Horatius Bonar Gbo ohun alore, Ji, ara, ji; Jesu ma fere de, Ji, ara, ji, Omo oru ni sun, Omo imole leyin, Ti yin logo didan, Ji, ara, ji. So fegbe to ti ji, Ara, sora; Ase Jesu daju, Ara, sora; E se b'olusona Nilekun Oluwa yin Bi O tile pe de, Ara, sora. Gbo ohun iriju, Ara, sise; Ise na kari wa, Ara, sise; Ogba Oluwa wa, Kun fun'se nigba gbogbo Yoo si fun wa lere, Ara sise. Gbo ohun Oluwa wa, E gbadura; Be fe kinu Re dun E gbadura; Ese 'mu beru wa, Alailera si ni wa; Ni ijakadi yin, E gbadura Ko orin ikehin, Yin, ara, yin; Mimo ni Oluwa. Yin, ara, yin: Ki lo tun ye ahon, To fere b'Angel' korin, T'y'o ro lorun titi, Yin, ara, yin. Hark! ’tis the watchman’s cry, Wake, brethren, wake! Jesus our Lord is nigh; Wake, brethren, wake! Sleep is for sons of night; Ye are children of the light, Yours is the glory bright; Wake, brethren, wake! Call to each waking band, Watch, brethren, watch! Clear is

O De

O de, Kristi Oluwa, Lat'ibugbe Re lorun, Lat'ite alafia, O wa si aginju wa. Alade Alana De lati ru 'ponju wa; O de, lati f'imole, Le okun oru wa lo. Jesus Christ the Lord has come, From His Father's throne above. From above the throne of peace. He came to this wilderness. Christ the Lord the Prince of Peace Come to bear all our burden, He has come to give us light, Drives away all our nightmare. Source: Hymnaro #92 Aroyehun ©2013