Gbo Ohun Jesu Ti N Ke Pe
Author: Daniel March , 1868. Gbo ohun Jesu ti n ke pe, Tani yoo sise loni? Oko pon pupo fun 'kore, Tani yi o lo ka a? Kikankikan l'Oluwa npe Ebun nla lo fi fun o. Tani yo fayo dahun pe, "Emi ni'i ran mi, ran mi." Biwo ko le la okun lo, Lati wa 'won keferi, O le ri won nitosi re, Won wa lenu ona re; Bo ko le fi wura tore, O le fi baba tore, Die to si se fun Jesu, 'Yebiye ni loju Re. Bo ko le soro b'angeli, Bo ko le wasu bi Paul' Iwo le so tife Jesu, O le so ti iku re; Biwo ko le ji elese Ninu ewu idajo, 'Wo le ko awon omode Li ona t'Olugbala. Biwo ko le kagbalagba, Krist' Olusaguntan ni, "Bo awon od'-aguntan Mi Gbe ounje ti won lodo," O le je pe awon 'mode To ti fi owo re to, Ni yoo wa larin oso re Gbat'o ba de'le rere. Ma jek'eniyan gbo wipe, "Ko si nkan temi le se," Nigba twon keferi nku, Ti Oluwa si n pe o, Fayo gba ise t'O pe o Kise Re je ayo r