Posts

Showing posts from April, 2024

Ọkàn, O Ha Ń Ṣàárẹ̀ / O Soul, Are You Weary

Author: Lemmel, Helen Howarth Ọkàn, o ha ń ṣàárẹ̀, o ń dààmú Òkùn ṣú kò sí ìmọ́lẹ̀ 'Mọ́lẹ̀ wà t'o bá w'Olùgbàlà 'Yè lọ́pọ̀lọpọ̀ àt' ọ̀fẹ́  Kọ ojú rẹ sí Jésù  Wò ojú ìyanu Rẹ̀  Àwọn nǹkan ayé yóò si di bàìbàì  N'nú 'mọ́lẹ̀ ògo, or' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Láti 'kú lọ s' íyè àínìpẹ̀kun O kọjá, a sì tẹ̀le lọ Lórí i wa ẹ̀ṣẹ̀ kò lágbára  Àwá ju aṣẹ́gun lọ  Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ k'yo' kùnà, Ó lérí Gbà á gbọ́, yóò dára fún ọ  Sì lọ sí ayé tí ń kú lọ  Sọ ti ìgbàlà pípé' Rẹ̀  Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 12th April, 2024 O soul, are you weary and troubled? No light in the darkness you see? There’s light for a look at the Saviour, And life more abundant and free! Turn your eyes upon Jesus, Look full in His wonderful face, And the things of earth will grow strangely dim, In the light of His glory and grace. Through death into life everlasting He passed, and we follow Him there; O’er us sin no more h

MO FERAN RE JESU / MY JESUS I LOVE THEE

Authors: James H. Duffel (1862); William R. Featherston (1862) Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi Mo feran re Jesu ju t'ateyin wa  Mo feran Re ni iye ati ni iku  N o ma yin Oruko Re gba m' ba wa laye  Gba temi mi ba n lo tojo mi n buse  Sibe n o feran Re tit'ojo aye mi  Ile ewa wonni bo ti dara to  N o dapo mawon mimo lati maa yin o Pelu ade wura lem'o ma yin O N o feran Re Jesu laye ati lorun  Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi  N o feran Re ju tateyin lo. Source: Orin Duru My Jesus, I love thee, I know thou art mine; For thee all the follies of sin I resign; My gracious Redeemer, my Saviour art thou; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I love thee because thou hast first loved me And purchased my pardon on Calvary’s tree; I love thee for wearing the thorns on thy brow; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I’ll lo

Jesu to Lewa Ju/ Fairest Lord Jesus

Author: Unknown Jesu to lẹwa ju, adari ẹda gbogbo Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan N o mọ riri Rẹ, n o bu ọla fun Ọ 'Wọ, ogo, ayọ, ade ọkan mi. Didara lawọn ọdan, sibẹ igi 'gbo dara ju Ta wọ pel' ogo igba 'ruwe Jesu dara julọ, Jesu funfun julọ O mọkan 'banujẹ kọrin Didara ni oorun, sibẹ oṣupa dara ju, Ati awọn irawọ ti n tan Jesu mọle ju wọn, Jesu tan ju wọn lọ Ju gbogbo angẹli ni ọrun Olugbala arẹwa, Oluwa ilẹ gbogbo, Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan! Ogo ati ọla, iyin ati' juba, Ko jẹ Tirẹ titi lailai. Translated by Ayọbami Temitọpẹ Kẹhinde on 3rd April, 2024 Fairest Lord Jesus, ruler of all nature O thou of God and man the Son Thee will I cherish, Thee will I honour Thou, my soul's glory, joy, and crown Fair are the meadows, fairer still the woodlands Robed in the blooming garb of spring Jesus is fairer, Jesus is purer Who makes the woeful heart to sing Fair is the sunshine, fairer still the moonlight And all the