N'nu Krist' Nikan/ In Christ Alone
Authors: Stuart Townend & Keith Getty N'nu Krist' nikan nireti mi, O'n n'imọlẹ, agbar', orin mi; Igun-ile yii, Apata yii, Wa sibẹ nin' ọda 'ti'ji. Ifẹ giga, ibalẹ okan, 'Gbati 'bẹru, idamu pin! Olutunu, Oun ni mo ni, Ninu 'fẹ Kristi mo duro. N'nu Krist' nikan, t'O wa leeyan Ọlọrun to wa bí ìkókó! Ẹbun 'fẹ yii at' ododo T'awọn t'O wa gbala kẹgan: Lori igi ti Jesu ku, Irunu Ọlọrun walẹ- Tori pẹ'ṣẹ wa lo gberu; Ninu 'ku Kristi ni mo ye. Nibẹ 'nu 'lẹ l'oku Rẹ wa Imọlẹ aye t'ookun pa: Lẹyin eyi lọjọ ologo O ji dide kuro 'nu oku! B'O si ti duro n'iṣẹgun Mo bọ lọwọ egun ẹṣẹ, Mo jẹ Tirẹ, Oun temi- Emi ta fẹjẹ Kristi ra. Niye, niku, ko si 'foya, Agbara Kristi 'nu mi ni; Lati 'bẹrẹ titi dopin, Jesu gba ayanmo mi mu. Ogun eṣu, ete aye Ki yoo le gba mi lowo Rẹ, 'Ti y' O fi de, tabi pe mi N o duro 'nu agbara Kristi. Translat