WA BA MI GBE
By Henry F. Lite Wa ba mi gbe, ale fere le tan Okunkun su, Oluwa ba mi gbe Bi oluranlowo miran baye Iranwo alaini, wa ba mi gbe. Ojo aye mi n sare lo s'opin Ayo aye n ku, ogo re n womi Ayida at'ibaje ni mo n ri 'Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe. Mo n fe ri O ni wakati gbogbo Ki lo le segun esu b'ore Re Ta lo le samona mi bi Re? N'nu banuje at'ayo, ba mi gbe. Pelu 'bukun Re, eru ko ba mi Ibi ko wuwo, ekun ko koro Oro iku da? Isegun isa da? N o segun sibe b'Iwo ba mi gbe. Ki n f'oro Re ni wakati iku Se'mole mi, si toka si orun B'aye ti n koja, kile orun mo Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe. Source: YBH 599 Abide with me; fast falls the eventide; The darkness deepens; Lord with me abide. When other helpers fail and comforts flee, Help of the helpless, O abide with me. Swift to its close ebbs out life’s little day; Earth’s joys grow dim; its glories pass away; Change and decay in all around I see; O Thou who chan...