FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye, Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun iyanu wakati Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan, Ọmọ 'ya, obi, ọmọ, Ọrẹ aye, ọrẹ oke, Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ, Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth For the glory of the skies, For the love which from our birth Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise, This our hymn of grat...