Posts

Showing posts with the label He brought me out of the miry clay in Yoruba

O Fa Mi Yo Ninu Erofo/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbogbe labe 'binu  Jehofa, Ninu ogbun ti ese mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu erofo, T'O fi 'yonu fa mi yo sojo wura Egbe: O fa mi yo ninu erofo O gbese mi sori apata O f'orin sin' okan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata egbe Re, Isise mi mule, n o duro nibi; Ko sewu isubu 'gba mo wa nihin, Sugbon n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owuro, l'ale n o maa koo titi ni; Okan mi kun fayo, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o korin aanu iyanu Re si mi, N o yin tit' aye yoo fi mo p'O dara; N o korin 'gbala nile leyin odi, K'opo le gbotito Re k'ọn si gbaa gbo. N o royin ogbun ati okunkun re, N o yin Baba mi to gbo adura mi; N o korin titun, orin ayo t'ife, N o si gberin pel' awon mimo loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. My heart was distressed ...