Posts

Showing posts with the label alleluia

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yo Ninu Erofo/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbogbe labe 'binu  Jehofa, Ninu ogbun ti ese mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu erofo, T'O fi 'yonu fa mi yo sojo wura Egbe: O fa mi yo ninu erofo O gbese mi sori apata O f'orin sin' okan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata egbe Re, Isise mi mule, n o duro nibi; Ko sewu isubu 'gba mo wa nihin, Sugbon n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owuro, l'ale n o maa koo titi ni; Okan mi kun fayo, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o korin aanu iyanu Re si mi, N o yin tit' aye yoo fi mo p'O dara; N o korin 'gbala nile leyin odi, K'opo le gbotito Re k'ọn si gbaa gbo. N o royin ogbun ati okunkun re, N o yin Baba mi to gbo adura mi; N o korin titun, orin ayo t'ife, N o si gberin pel' awon mimo loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. My heart was distressed ...

Halleluyah, Halleluyah

Writer:  Christopher Wordsworth (1807-1885), 1862 Halleluyah, Halleluyah, E gbe ohun ayo ga, E korin inudidun, K' e si yin olorun wa, Enit'a kan m'agbelebu, T' o jiya fun ese wa; Jesu Kristi Oba ogo Jinde kuro n'nu oku. Irin idabu se kuro Kristi ku, O sit un ye, O mu iye at aiku Wa l'oro ajinde Re; Krist' ti' segun, awa segun Nipa agbara nla Re, Awa o jinde pelu Re, A o ba wo 'nu ogo. Kristi jinde, akobi ni Ninu awon t' o ti sun, Awon yi ni y' o ji dide, Ni abo Re ekeji; Ikore ti won ti pon tan Nwon  nreti  Olukore, Eniti y'o mu won kuro, Ninu isa oku won. Awa jinde pelu Kristi T'O nfun wa l' ohun gbogbo Ojo, iri, ati ogo To ntan jade l' oju Re; Oluwa b' a ti wa l'aiye, Fa okan wa s'odo Re, K'awon maleka saw a jo, Ki  nwon  ko wa d,odo Re. Halleluyah, Halleluyah! Ogo ni fun Olorun; Halleluyah f' Olugbala Enit' Osegun iku....