Posts

Showing posts with the label laarin gbungbun oye

Laarin Gbungbun Oye/ In The Bleak Midwinter

Image
Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìjì dídì ń sọkún Ayé le bí irin Omi bí òkúta Yìnyín bọ́ lórí yìnyín Lórí yìnyín Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Lọ́jọ́ ọjọ́un Ọlọ́run wa, ọ̀run kò gbàá,  Ayé kò lè gbée ró Ọ̀run, ayé yóò kọjá lọ 'Gb' Ó bá wá jọba. Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìbùjẹ́ ẹran tó fún Olúwa Alágbára Jésù Kristi.  Ó tó f' Ẹni tí Kérúbù Ń sìn lọ́saǹ lóru: Ọmú tó kuń fún wàrà Koríko ilé ẹran Ó tó f' Ẹni t'Angel' Ń wólẹ̀ fún o, Màálù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí Tí ń júbà Rẹ̀ Angel' nípò dépò 'Bá péjọ síbẹ̀ Kérúbù, Séráfù 'Bá wa 'nú afẹ́fẹ́; Ṣùgbọn Màmá Rẹ̀ nìkan, Wúndíá pẹ̀l' áyọ́ Fi ìfẹnukonu Sin Àyànfẹ́. Kínni mo lè fi fún Un, Èmi òṣì, àre Ǹ bá j' olúṣ'àgùntàn, Ǹ bá  fún Un l' ọ̀d'àgùntàn Ǹ bá jẹ́ Amòye Ǹ bá sápá tèmi, — Síbẹ ohun mo ní, mo fún Un, — Ọkàn mi. Trans...