Laarin Gbungbun Oye/ In The Bleak Midwinter

Author: Christina Rossetti
Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde


Láàrín gbùngbùn ọyẹ́
Ìjì dídì ń sọkún
Ayé le bí irin
Omi bí òkúta
Yìnyín bọ́ lórí yìnyín
Lórí yìnyín
Láàrín gbùngbùn ọyẹ́
Lọ́jọ́ ọjọ́un

Ọlọ́run wa, ọ̀run kò gbàá, 
Ayé kò lè gbée ró
Ọ̀run, ayé yóò kọjá lọ
'Gb' Ó bá wá jọba.
Láàrín gbùngbùn ọyẹ́
Ìbùjẹ́ ẹran tó fún
Olúwa Alágbára
Jésù Kristi. 

Ó tó f' Ẹni tí Kérúbù
Ń sìn lọ́saǹ lóru:
Ọmú tó kuń fún wàrà
Koríko ilé ẹran
Ó tó f' Ẹni t'Angel'
Ń wólẹ̀ fún o,
Màálù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí
Tí ń júbà Rẹ̀

Angel' nípò dépò
'Bá péjọ síbẹ̀
Kérúbù, Séráfù
'Bá wa 'nú afẹ́fẹ́;
Ṣùgbọn Màmá Rẹ̀ nìkan,
Wúndíá pẹ̀l' áyọ́
Fi ìfẹnukonu
Sin Àyànfẹ́.

Kínni mo lè fi fún Un,
Èmi òṣì, àre
Ǹ bá j' olúṣ'àgùntàn,
Ǹ bá fún Un l' ọ̀d'àgùntàn
Ǹ bá jẹ́ Amòye
Ǹ bá sápá tèmi, —
Síbẹ ohun mo ní, mo fún Un, —
Ọkàn mi.

Translated by Ayobami Temitope Kehinde Dec 15, 2018.

Get the audio here.







In the bleak mid-winter
Frosty wind made moan;
Earth stood hard as iron,
Water like a stone;
Snow had fallen, snow on snow,
Snow on snow,
In the bleak mid-winter
Long ago.

Our God, heaven cannot hold Him
Nor earth sustain,
Heaven and earth shall flee away
When He comes to reign:
In the bleak mid-winter
A stable-place sufficed
The Lord God Almighty —
Jesus Christ.

Enough for Him, whom Cherubim
Worship night and day,
A breastful of milk
And a mangerful of hay;
Enough for Him, whom Angels
Fall down before,
The ox and ass and camel
Which adore.

Angels and Archangels
May have gathered there,
Cherubim and seraphim
Thronged the air;
But only His Mother
In her maiden bliss
Worshipped the Beloved
With a kiss.

What can I give Him,
Poor as I am? —
If I were a Shepherd
I would bring a lamb;
If I were a Wise Man
I would do my part, —
Yet what I can I give Him, —
Give my heart.






"In the Bleak Midwinter" is a Christmas carol based on a poem by the English poet Christina Rossetti. The poem was published, under the title "A Christmas Carol", in the January 1872 issue of Scribner's Monthly.
The poem first appeared set to music in The English Hymnal in 1906 with a setting by Gustav Holst.
Harold Darke's anthem setting of 1911 is more complex and was named the best Christmas carol in a poll of some of the world's leading choirmasters and choral experts in 2008.

Continue reading here.

Comments

  1. Thank you so much... God bless you
    I can only encourge you to please keep it up

    ReplyDelete
  2. Thank you so much for this.
    I can only encourge you to please keep it up

    ReplyDelete

Post a Comment

Popular posts from this blog

JESU NI BALOGUN OKO

E BA WA YIN OLUWA, ALLELUYA!

Mo N Tesiwaju Lona Na