Posts

Showing posts with the label Jesus

Gbogb' Ọkàn Mí Yọ̀ Lálẹ́ Yìí / All My Heart This Night Rejoices

Image
Author: Paul Gerhardt English Translator: Catherine Winkworth Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Gbogb' ọkàn mí yọ̀ lálẹ́ yìí Bí mo tí ń gbọ́ Nílé lóko Ohùn áńgelì dídùn “A bí Krist'”, akọrin ń kọrin Títí i- bi gbogbo Yóò fi rinlẹ̀ fáyọ̀. ‘Jagunsẹ́gun ń jáde lọ lónì í Ó borí ọ̀tá, ẹ̀ṣẹ̀, ’Bìnújẹ́, ’kú, ’pò òkú Ọlọ́run dèèyàn láti gbà wá Ọmọ Rẹ̀, Ó jọ́kan Pẹ̀l' ẹ̀jè wa títí. A ṣì ń bẹ̀rù ’bín' Ọlọ́run, T’Ó fi fún wa Lọ́fẹ̀ ‘Ṣura Rẹ̀ tó ga jù? Láti rà wa padà l'Ó fún wa L’Ọmọ Rẹ̀ Látorí ’tẹ́ Ipá Rẹ ní ọrùn Ó d'Ọ̀dọ́ Àgùntàn t'Ó mú Ẹ̀ṣẹ̀ lọ́ Ó sì ṣe Ìpẹ̀tùsí  kíkún Ó fẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: Ìran wa Níp' oor'ọ̀fẹ́ Rẹ̀ a yẹ fún ògo. Gbóhùn kan láti ’bùjẹ́ ’ran Dídùn ni, Ó ń bẹ̀bẹ̀, “Sá fún ’dààmú, ewù Ará, ẹ ti gbà ’dásílẹ̀ Lọ́wọ́ ibi, Ohun ẹ nílò Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Wá wàyí, lé bànújẹ́ lọ Gbogbo yín, Lọ́kọ̀kan,...

Halleluyah, Halleluyah

Writer:  Christopher Wordsworth (1807-1885), 1862 Halleluyah, Halleluyah, E gbe ohun ayo ga, E korin inudidun, K' e si yin olorun wa, Enit'a kan m'agbelebu, T' o jiya fun ese wa; Jesu Kristi Oba ogo Jinde kuro n'nu oku. Irin idabu se kuro Kristi ku, O sit un ye, O mu iye at aiku Wa l'oro ajinde Re; Krist' ti' segun, awa segun Nipa agbara nla Re, Awa o jinde pelu Re, A o ba wo 'nu ogo. Kristi jinde, akobi ni Ninu awon t' o ti sun, Awon yi ni y' o ji dide, Ni abo Re ekeji; Ikore ti won ti pon tan Nwon  nreti  Olukore, Eniti y'o mu won kuro, Ninu isa oku won. Awa jinde pelu Kristi T'O nfun wa l' ohun gbogbo Ojo, iri, ati ogo To ntan jade l' oju Re; Oluwa b' a ti wa l'aiye, Fa okan wa s'odo Re, K'awon maleka saw a jo, Ki  nwon  ko wa d,odo Re. Halleluyah, Halleluyah! Ogo ni fun Olorun; Halleluyah f' Olugbala Enit' Osegun iku....