Posts

Showing posts with the label Jesus Christ

Gbogb' Ọkàn Mí Yọ̀ Lálẹ́ Yìí / All My Heart This Night Rejoices

Image
Author: Paul Gerhardt English Translator: Catherine Winkworth Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Gbogb' ọkàn mí yọ̀ lálẹ́ yìí Bí mo tí ń gbọ́ Nílé lóko Ohùn áńgelì dídùn “A bí Krist'”, akọrin ń kọrin Títí i- bi gbogbo Yóò fi rinlẹ̀ fáyọ̀. ‘Jagunsẹ́gun ń jáde lọ lónì í Ó borí ọ̀tá, ẹ̀ṣẹ̀, ’Bìnújẹ́, ’kú, ’pò òkú Ọlọ́run dèèyàn láti gbà wá Ọmọ Rẹ̀, Ó jọ́kan Pẹ̀l' ẹ̀jè wa títí. A ṣì ń bẹ̀rù ’bín' Ọlọ́run, T’Ó fi fún wa Lọ́fẹ̀ ‘Ṣura Rẹ̀ tó ga jù? Láti rà wa padà l'Ó fún wa L’Ọmọ Rẹ̀ Látorí ’tẹ́ Ipá Rẹ ní ọrùn Ó d'Ọ̀dọ́ Àgùntàn t'Ó mú Ẹ̀ṣẹ̀ lọ́ Ó sì ṣe Ìpẹ̀tùsí  kíkún Ó fẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: Ìran wa Níp' oor'ọ̀fẹ́ Rẹ̀ a yẹ fún ògo. Gbóhùn kan láti ’bùjẹ́ ’ran Dídùn ni, Ó ń bẹ̀bẹ̀, “Sá fún ’dààmú, ewù Ará, ẹ ti gbà ’dásílẹ̀ Lọ́wọ́ ibi, Ohun ẹ nílò Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Wá wàyí, lé bànújẹ́ lọ Gbogbo yín, Lọ́kọ̀kan,...