Posts

Showing posts with the label Easter

Jesu O Seun/ Jesus Thank You

Writer:Pat Sczebel Adiitu agbelebu ko ye mi sibẹ, Irora ti Kalfari-- Ìwọ t'O pe t'O si mọ lu Ọmọ Rẹ T'O m'ago ikoro to yẹ ki n mu. Chorus Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ti wẹṣẹ mi nu, Jesu O seun. Irunu Ọlọrun walẹ pata, Jesu O seun. Mo ti jọta Rẹ ri, Wayi mo n ba Ọ jeun, Jesu O seun. Nipa 'rubọ pipe Rẹ la fi fa mi, O s' ọta Rẹ dọrẹ Rẹ; Ọrọ or'ọfẹ ologo Rẹ lo tu jade, Aanu at' inu're Rẹ ko lopin. Bridge Olufẹ́ ọkan mi, Mo fẹ́ ma wa fun Ọ. Translated by Ayobami Temitope  Kehinde (21/04/2017) The mystery of the cross I cannot comprehend The agonies of Calvary-- You the perfect Holy One, crushed Your Son, Who drank the bitter cup reserved for me. CHORUS Your blood has washed away my sin Jesus, thank You The Father’s wrath completely satisfied Jesus, thank You Once Your enemy, now seated at Your table Jesus, thank You By Your perfect sacrifice I’ve been brought near, Your enemy You’ve made Your friend; Pouring out the riches of Yo...

Halleluyah, Halleluyah

Writer:  Christopher Wordsworth (1807-1885), 1862 Halleluyah, Halleluyah, E gbe ohun ayo ga, E korin inudidun, K' e si yin olorun wa, Enit'a kan m'agbelebu, T' o jiya fun ese wa; Jesu Kristi Oba ogo Jinde kuro n'nu oku. Irin idabu se kuro Kristi ku, O sit un ye, O mu iye at aiku Wa l'oro ajinde Re; Krist' ti' segun, awa segun Nipa agbara nla Re, Awa o jinde pelu Re, A o ba wo 'nu ogo. Kristi jinde, akobi ni Ninu awon t' o ti sun, Awon yi ni y' o ji dide, Ni abo Re ekeji; Ikore ti won ti pon tan Nwon  nreti  Olukore, Eniti y'o mu won kuro, Ninu isa oku won. Awa jinde pelu Kristi T'O nfun wa l' ohun gbogbo Ojo, iri, ati ogo To ntan jade l' oju Re; Oluwa b' a ti wa l'aiye, Fa okan wa s'odo Re, K'awon maleka saw a jo, Ki  nwon  ko wa d,odo Re. Halleluyah, Halleluyah! Ogo ni fun Olorun; Halleluyah f' Olugbala Enit' Osegun iku....

Ija D'opin, Ogun Si Tan

Author Unknown Translated from Latin to English by Francis Pott Alleluya! Alleluya!! Alleluya!!! Ija d' opin, ogun si tan: Olugbala jagun molu: Orin ayo l' a o ma ko. Alleluya! Gbogbo ipa n' iku si lo: Sugbon Kristi f' ogun re ka: Aiye E ho iho ayo - Alleluya! Ojo meta na ti koja. O jinde kuro nin' oku: E f' ogo fun Olorun wa. -Alleluya! O d' ewon orun apadi, O s' ilekun orun sile: E korin iyin 'segun Re. - Alleluya! Jesu nipa iya t' O je, A bo lowo iku titi: Titi l' a o si ma yin O. - Alleluya! Source: Yoruba Baptist Hymnal #123 Alleluia, alleluia, alleluia! The strife is o'er, the battle done, the victory of life is won; the song of triumph has begun.  Alleluia! The powers of death have done their worst, but Christ their legions hath dispersed: let shout of holy joy outburst. Alleluia! The three sad days are quickly sped, he rises glorious from the dead: all glory to our risen Head! Allelui...

Jesu Ye Titi Aye

Words: Christian Friedrich Gellert (1715-1769), 1757 Translated by Frances E. Cox (1812-1897), 1841 Tune: St Albinus Jesu ye; titi aiye Eru iku ko ba ni mo; Jesu ye; nitorina Isa oku ko n 'ipa mo. - Alleluya! Jesu ye; lat' oni lo Iku je ona si iye; Eyi y'o je ' tunu wa 'Gbat' akoko iku ba de. - Alleluya! Jesu ye; fun wa l' O ku; Nje Tire ni a o ma se; A o f'okan funfun sin, A o f'ogo f'Olugbala. - Alleluya! Jesu ye; eyi daju, Iku at' ipa okunkun Ki y'o le ya ni kuro Ninu ife nla ti Jesu. - Alleluya! Jesu ye; gbogbo 'joba L'orun, li aiye, di Tire; E ja ki a ma tele Ki a le joba pelu Re. - Alleluya. Source: Yoruba Baptist Hymnal #125 Jesus lives! thy terrors now can no more, O death, appal us; Jesus lives! by this we know thou, O grave, canst not enthrall us. Alleluia! Jesus lives! henceforth is death but the gate of life immortal; this shall calm our trembling breath when we pass its gloomy...