Posts

Showing posts from November, 2014

JESU NI BALOGUN OKO

Image
Author Unknown Jesu ni Balogun oko E mase je ka foya Olutoko wa ni Jesu Y'o mu oko wa gunle Refrain: E ma se beru E kun fun ayo Nitori Jesu l'oga oko Bo ti wu k'iji na le to Y'o mu oko wa gunle Eyin ero t'o wa l'oko E kepe Jesu nikan K'e si gbeke yin le Jesu Y'o mu oko wa gunle Olugbala 'wa toro Re Mu igb'omi pa roro Iwo t'o rin lori omi T'o sun, beni ko si nkan Kil' ohun to nba yin leru Eyin omo 'gun Kristi Bi Jesu ba wo ' nu oko Awa y'o fi 'gbi rerin 'Gbati 'gbi aye yi ba nja Lor' okun ati n'ile Abo kan mbe ti o daju Lodo Olugbala wa Lowo kiniun at' ekun Lowo eranko ibi Jesu y'o dabobo Tire Jesu y'o pa Tire mo Metalokan Alagbara Dabobo awa omo Re Lowo a'tegun ati 'ji Je k'awa k' alleluyah Ogo ni fun Baba loke Ogo ni fun Omo Re Ogo ni fun Emi Mimo Metalokan l'ope ye. Jesus is the Captain of the ship, So, do no let us ...