Láyọ̀, Láyọ̀, La Júbà Rẹ / Joyful, Joyful, We Adore Thee
Author: Henry J. van Dyke Láyọ̀ láyọ̀, la júbà Rẹ Ológo at' Onífẹ́ Ọkàn wa ṣí bí ododo Ti ń ṣí sí òòrùn lókè Yọ 'kukù ẹ̀ṣẹ̀ o'n 'bànújẹ́ Móòkùn 'yèméjì kúrò Olùfúnni láyọ̀ àìkú Fìmọ́lẹ̀ ọjọ́ kúnnú wa. Iṣẹ́ Rẹ fayọ̀ yí Ọ ka Ay' ọ̀run tàn 'tànṣán Rẹ 'Ràwọ̀, áńgẹ́l' ń k ọrin sí Ọ Àárín gbùngbùn 'yìn pipe Pápá, igbó, pẹ̀tẹ́lẹ̀, òkè, Àkùrọ̀, òkun didan Ohùn ẹyẹ, orísun t'ó ń ṣàn Pè wá latí yọ̀ n'nú Rẹ Ò ń fifún ni, Ò ń dáríjì Ol'bùkún, Alábùkún 'Wọ l' orísun ayọ̀ ìyè Ìjìnlẹ̀ ìsimi 'Wọ Baba wa, Krist' Ẹ̀gbọ́n wa Tirẹ làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Kọ́ wá ba ti ń fẹ́ ara wa Gbé wa sáyọ̀ àtòkèwá Ẹ̀dá gbogbo gberin ayọ̀ Táwọn 'ràw' òórọ̀ bẹ̀rẹ̀ Baba 'fẹ́ ń jọba lori wa Ẹ̀gbọ́n 'fẹ́ so wá papọ̀ Lórin títí, a ń tẹ̀ síwájú Aṣẹ́gun láàrin ìjà Orin ayọ̀ gbé wa sókè N'nú orin ...