Alleluya! Kọrin sí Jésù! / Alleluia! Sing to Jesus!
Author: William Chatterton Dix (1866) Alleluya! Kọrin sí Jésù! Tirẹ̀ lọ̀pá, Tirẹ̀ nìtẹ́; Alleluya! Ó jagunmólú, Tirẹ̀ nìkan ni ìsẹ́gun Gbọ́! orin Sion' 'írọ̀rùn Sán àrá bí ìgbì omi Jésù láti ilẹ̀ gbogbo Rà wá padà pẹ̀l' ẹ́jẹ̀ Rẹ̀. Allelúyà! Kò fi wá sílẹ̀ Láti ṣọfọ bí òrukàn Alleluya! O súnmọ́ wa 'Gbàgbọ́ kìí bèèrè pé báwo: Bí 'kukù tilẹ̀ bojúu Rẹ̀ Lẹ́yìn ogójì ọjọ́ A óò ha gbàgbé ìlérí Rẹ̀, 'Mo wà pẹ̀lú yín dópin.' Alleluya! Àkàrà ángẹ́l', 'Wọ lóunjẹ àti wíwà wa Alleluya! Níhìn ẹlẹ́ṣẹ̀— Ń sá tọ́ Ọ́ ní ojúmọ́: Olùbẹ̀bẹ̀, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́sẹ, Olùràpadà, bẹ̀bẹ̀ fún mi, Níb' orin àwọn ẹni mímọ́ Ti n la òkun krístálì jà. Alleluya! Ọba àìkú, Olúwa àwọn olúwa tiwa; Alleluya! Ọmọ Mary, Ayé nìtisẹ̀, ọ̀run nìtẹ́: Ìwọ gba ikele kọjá Olórí Àlùfáà wa; Àlùfáà àti ìrúbọ Ni àsè Yúkárístì. Translated t...