Nigba Igbi Aye Ba Dide Si O / Ro 'Bukun Re / Count Your Blessings
 Author: Johnson Oatman Jr (1856-1952)     Nigba igbi aiye ba dide si o,  T' okan re baje pe gbogbo nkan segbe,  Siro ibukun re, ka won lokokan,  Enu y'o ya o fun nkan t' Oluwa t'se.   Refrain  Ro 'bukun re ka won lokokan,  Ro ohun t' Olorun se fun o;  Ro 'bukun re, ka won lokokan,  Ro 'bukun re, ri nkan t' Olorun ti se.   Eru aniyan ha ti n pa okan re?  Agbelebu ti 'wo nru ha si wuwo?  Siro ibukun re le 'yemeji lo,  Iwo y'o si korin b' ojo ti nkoja.   Nigbat' ini elomi kun o loju,  Ranti Krist n 'oro aimoye fun o,  Siro ibukun re t' owo ko le ra,  At' ere re lorun, ile re l' oke   Beni larin ija b' o ti wu ko ri,  Mase ba okan je mo p' Olorun mbe,  Siro ibukun re, Angeli y'o wa,  Fun ranwo on 'tunu d'opin ajo re.   Source: YBH #658  When upon life’s billows you are tempest tossed,  When you are discouraged, thinking all is lost,  Count your many blessings name them one by one,  And it will surp...