IFE ORUN

Ife orun, o ti dun to!
Gbawo ni n o ri t'okan mi
Y'o kun fun kiki re?
Okan mi n pongbe lati mo
Riri ife irapada;
Ife Kristi si mi.

Ife Re n'ipa ju iku;
Oro Re awamaridi!
Awon Angeli paapaa
Wa ijinle ife yi ti.
Won ko le mo iyanu na,
Giga ati'bu re.

Olorun nikan l'O le mo,
I ba je tan kale loni;
L'okan okuta yi!
Ife nikan ni mo n toro,
Ko je ipin mi Oluwa:
K'ebun yi je temi.

Emi i ba le joko lai,
Bi Maria, lese Jesu;
Keyi je ayo mi;
Ko janiyan atife mi,
Ko si j'orun fun mi laye
Lati ma gbohun Re.

Source: YBH #266

Comments

Popular posts from this blog

JESU NI BALOGUN OKO

E BA WA YIN OLUWA, ALLELUYA!

Mo N Tesiwaju Lona Na