Posts

Showing posts from 2016

Mo faye atife mi fun/My life, my love I give to Thee

Words: Ralph E. Hudson (1843-1901) Mo f'aye at'ife mi fun Od'aguntan to ku fun mi; Je ki n le je olotito, Jesu Olorun mi. N o wa f'Eni t'O ku fun mi, Aye mi yo si dun pupo; N o wa f'Eni to ku fun mi, Jesu Olorun mi. Mo gbagbo pe Iwo n gbani 'Tori 'Wo ku k'emi le la; Emi yo si gbekele O, Jesu Olorun mi. Iwo t'O ku ni Kalfari, Lati so mi dominira; Mo yara mi soto fun O, Jesu Olorun mi. My life, my love I give to Thee, Thou Lamb of God who died for me; O may I ever faithful be, My Savior and my God! I’ll live for Him who died for me, How happy then my life shall be! I’ll live for Him who died for me, My Savior and my God! I now believe Thou dost receive, For Thou hast died that I might live; And now henceforth I trust in Thee, My Savior and my God! O Thou who died on Calvary, To save my soul and make me free, I’ll consecrate my life to Thee, My Savior and my God!

Elese E Yipada

Image
Words: Charles Wesley Elese e yi pada, Ee se ti e o fi ku? Eleda nyin ni n bere; T' O fe ki e ba On gbe: Oran nla ni O nbi nyin, Ise owo Re ni nyin, A! enyin alailope, Ee se t'e o ko, 'fe Re. Elese e yi pada, Ee se ti e o fi ku? Olugbala ni n bere, Enit' o gb' emi nyin la; Iku Re y'o j' asan bi? E o tun kan mo 'gi bi? Eni 'rapada, ee se Ti e o gan ore Re? Elese e yi pada Ee se ti e o fi ku? Emi Mimo ni n bere Ti nf' ojo gbogbo ro nyin E ki o ha gb' ore Re? E o ko iye sibe? A ti nwa yin pe, ee se T' e n bi Olorun ninu? Iyemeji ha nse nyin Pe ife ni Olorun, E ki o ha gb' oro Re? K'e gba ileri Re gbo? W' Oluwa nyin l' odo nyin, Jesu n sun: w' omije Re Eje Re pelu n ke pe, "Ee se ti e o fi ku?" Source: Yoruba Baptist Hymnal #175 Sinners, turn: why will you die? God, your maker, asks you why. God, who did your being give, Gave ...

Wa S'adura Ooro

Author: James Montgomery Wa s'adura ooro, Kunle k'a gbadura; Adura ni opa Kristiani, Lati b'Olorun rin. Losan, wole labe, Apat' ayeraye; Itura ojiji Re dun, Nigba t'orun ba mu. Jẹ ki gbogbo ile, Wa gbadura l'ale; Ki ile wa di t'Olorun, Ati 'bode orun.   Nigbat' od'oganjo, Je k'a wi l'emi, pe, Mo sun, sugbon okan mi ji Lati ba O sona. Come to the morning prayer, Come let us kneel and pray; Prayer is the Christian pilgrim's staff To walk with God all day. At noon, beneath the Rock Of Ages, rest and pray; Sweet is that shadow from the heat, When the sun smites by day. At eve, shut to the door, Round the home-altar pray, And finding there "the House of God," At "heaven's gate" close the day. When midnight seals our eyes, Let each in spirit say, "I sleep, but my heart waketh, Lord, With Thee to watch and pray."

Baba Mi Gbo Temi/Holy Father, Hear Me

Words: Edward Henry Bickersteth, 1881 Baba mi gbo temi 'Wo ni Alabo mi, Ma sunmo mi titi; Oninure julo! Jesu Oluwa mi, Iye at'ogo mi, K'igba naa yara de, Ti n o de odo Re. Olutunu julo, 'Wo ti n gbe inu mi, 'Wo to mo aini mi, Fa mi, k'o si gba mi. Mimo, mimo, mimo, Ma fi mi sile lai, Se mi n'ibugbe Re, Tire nikan lailai. Holy Father, hear me; thou art my defender, be thou ever near me, loving, true and tender. Jesus, blessèd Savior, Lord of life and glory, grant me now thy favour as I kneel before thee. Comforter benignest, who abiding in me all my need divinest, move me, draw me, win me. Holy, holy, holy, come, and leave me never, thine abode most lowly, only thine for ever.

Pelu Iwa Mimo/ Take Time To Be Holy

William D. Longstaff Pelu iwa mimo, b' Oluwa s' oro Gbe 'nu Re n' gbagbogbo je onje iye, B' onigbagbo s' ore, Ran ailera lowo; Ma gbagbe nigbakan, wa ibukun Re. Pelu iwa mimo, Aiye nkoja lo, Gbadura ni koko, si Jesu nikan B' iwo ba now Jesu, wo yio dabi Re, Awon ore yio ri Jesu n'nu 'wa re. Pelu iwa mimo, je k' On ma to o; Ohun t' o wu ko de, ma foya rara; Banuje tab' ayo, tele Jesu re, Ma wo Olugbala, gbeke l' oro Re. Pelu iwa mimo, f' okan re bale, F' On s 'alakoso iwa on ise re; Emi Re yio to o, s' orisun ife, Yio si mu o ye, ibugbe orun. Source: YBH #404 Take time to be holy, speak oft with thy Lord; Abide in Him always, and feed on His Word. Make friends of God’s children, help those who are weak, Forgetting in nothing His blessing to seek. Take time to be holy, the world rushes on; Spend much time in secret, with Jesus alone. By looking to Jesus, like Him thou shalt be...

Gbogbo Aye, Gbe Jesu Ga

Author: Edward Perronet Gbogbo aye, gbe Jesu ga, Angeli', e wole fun: E mu ade Oba Re wa, Se l'Oba awon oba. E se l'Oba, eyin Martir' Ti n kepe n' ite Re; Gbe gbongbo-igi Jesse ga, Se l' Oba awon oba. Enyin iru-omo Israel', Ti a ti rapada; E ki Enit' o gba nyin la. Se l' Oba awon oba. Gbogbo enia elese, Ranti 'banuje nyin; E te 'kogun nyin s' ese Re, Se l' Oba awon oba. Ki gbogbo orile-ede, Ni gbogbo agbaiye; Ki nwon ki "Kabiyesi," Se l' Oba awon oba. A ba le pel' awon t' orun, Lati ma juba Re; K' a ba le jo jumo korin, Se l' Oba awon oba. Source: Yoruba Baptist Hymnal #136 All hail the power of Jesus' name! Let angels prostrate fall; Bring forth the royal diadem, And crown Him Lord of all.  Crown him, ye martyrs of your God,  who from his altar call;  Extol the Stem of Jesse's Rod,  and crown him Lord of all.  Ye chosen seed of Israel's ...

Ona Ara L'Olorun Wa/God Moves in a Mysterious Way

Words: Will­iam Cow­per Ona ara l' Olorun wa Ngba sise Re l' aiye; A nri 'pase Re lor' okun, O ngun igbi l' esin. Ona Re enikan ko mo, Awamaridi ni; O pa ise ijinle mo, O sin se bi Oba. Ma beru mo, enyin mimo, Orun t' o su be ni, O kun fun anu: y'o  rojo Ibukun sori nyin. Mase da Oluwa l' ejo, Sugbon gbeke re le; 'Gbat o ro pe O binu, Inu Re dun si . Ise Re fere ye wan a, Y'o ma tan siwaju; Bi o tile koro loni, O mbo wa dun lola. Afoju ni alaigbagbo, Ko mo 'se Olorun; Olorun ni Olutumo, Y'o m' ona Re ye ni. God moves in a mysterious way His wonders to perform; He plants His footsteps in the sea And rides upon the storm. Deep in unfathomable mines Of never failing skill He treasures up His bright designs And works His sovereign will. Ye fearful saints, fresh courage take; The clouds ye so much dread Are big with mercy and shall break In blessings on you...

Gbo 'Gbe Ayo/Hark the Glad Sound

Philip Doddridge, 1702-1751 Gbo 'gbe ayo! Oluwa de, Jesu t' a seleri; Ki gbogbo okan mura de, K' ohun mura ko ' rin O de lati t' onde sile, L' oko eru Esu; 'Lekun 'de fo niwaju Re, Sekeseke 'rin da. O delarin 'baje aiye Lati tan 'mole Re, Lati fun awon afoju N' iriran f' oju  won. O de! 'Tinu f' okan 'rora, Iwosan f' agbogbe; O de pel' opo 'sura Re Fun awon talaka. Hosanna wa, Oba 'lafia Ao kede bibo Re; Gbogbo orun y'o ma korin Oruko t' a feran. Hark the glad sound! The Savior comes, The Savior promised long; Let every heart prepare a throne And every voice a song. He comes the prisoners to release, In Satan's bondage held. The gates of brass before Him burst, The iron fetters yield.   He comes from thickest films of vice To clear the mental ray And on the eyeballs of the blind To pour celestial day.   He c...

Baba Orun/Heavenly Father

Author Unknown Translator: Ayobami Temitope Kehinde Baba orun, emi mo iyi Re Baba orun, emi mo iyi Re Mo nife, juba Re Mo wole n’waju Re Baba orun, emi mo iyi Re Omo ’lorun, O ti n’iyanu to Omo ’lorun, O ti n’iyanu to O s’okan wa di mimo Ran Emi Mimo sinu wa Omo ’lorun, O ti n’iyanu to Emi Mimo, itunu nla ni O Emi Mimo, itunu nla ni O O n to wa, O n dari, O n gbenu okan wa Emi Mimo, itunu nla ni O Heavenly Father, I appreciate you Heavenly Father, I appreciate you I love You, adore You, I bow down before you Heavenly Father, I appreciate you Son of God, what a wonder You are Son of God, what a wonder You are You’ve cleansed our souls from sin Sent the Holy Ghost within Son of God, what a wonder You are Holy Ghost, what a comfort You are Holy Ghost, what a comfort You are You lead us, You guide us You live right inside us Holy Ghost, what a wonder You are

Mo Mo Pe Oludande Mi N Be

Author: Jessie Brown Pounds Mo mo pe Oludande mi n be Y'o tun duro ni aye yi Mo mo pe O fun mi ni iye Ore-ofe n be l'owo Re Refrain: Mo mo pe Jesu n be ni aaye Y'o tun duro ni aye yi Mo mo pe O fun mi ni iye Ore-ofe n be l'owo Re Mo mo pe' leri Re ko le ye Oro Re ye titi lailai B'iku tile pa ara mi run Emi yo ri lojukoju Mo mo pe O n pese aye de mi 'Biti O wa l'emi y'o wa O n pa mi mo titi d'igbana O n pada bo lati mu mi Source: Iwe Orin Irapada Ti Ijo Aposteli Naa #776 I know that my Redeemer liveth, And on the earth again shall stand; I know eternal life He giveth, That grace and power are in His hand. Chorus: I know, I know that Jesus liveth, And on the earth again shall stand; I know, I know that life He giveth, That grace and power are in His hand. I know His promise never faileth, The word He speaks, it cannot die; Tho' cruel death my flesh assaileth, Yet I shall see Him by and by< I ...

Ile Ayo Kikun Kan N Be

Words of verses by Isaac Watts (1709) Words of refrain by Anonymous Ile ayo kikun kan n be Bit' awon mimo n gbe Ko soru af' osan titi Irora ko si be Refrain: Ounje iye ni awa n je Kanga iye ni awa n mu Enit' o ba mu kanga yii Oungbe ki y'o gbe mo lailai Bayi ni Jesu wi, "Oungbe ki y'o gbe mo." Bayi ni Jesu wi, "Oungbe ki y'o gbe mo." Enit' o ba mu kanga yii Oungbe ki y'o gbe mo lailai Orisun iye n be nibe Itanna ti ki re Iku n'iboju ti ko je K'a r'ile ewa yi 'Yemeji wa 'ba le fo lo K'a le aigbagbo lo K'a fi 'gbagbo wo Kenan wa Ile wara, oyin A ba le goke bi Mose K'a wo 'le naa lookan Ikun bi odo nla Jordan K'y'o ba wa leru mo Source: Iwe Orin Irapada Ti Ijo Aposteli Na #782 There is a land of pure delight, where saints immortal reign, infinite day excludes the night, and pleasures banish pain. Refrain: We’re feeding on the living br...

Sinmi Le Apa Ayeraye/Leaning On The Everlasting Arms

Image
Anthony J. Showalter and Elisha A. Hoffman , pub.1887 Idapo didun, ayo atoke wa ’Sinmi le apa ayeraye Ibukun pupo, ifokanbale ’Sinmi le apa ayeraye Refrain: Sinmi, sinmi Eru ko ba mi, aya ko fo mi Sinmi, sinmi Sinmi le apa ayeraye Bo ti dun to lati rin ajo yii ’Sinmi le apa ayeraye B'ona na ti n’mole sii lo'jumo ’Sinmi le apa ayeraye N o se wa foya, n o se wa beru, ’Sinmi le apa ayeraye Okan mi bale, Jesu sunmo mi ’Sinmi le apa ayeraye Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde, 2016 What a fellowship, what a joy divine, Leaning on the everlasting arms; What a blessedness, what a peace is mine, Leaning on the everlasting arms. Refrain: Leaning, leaning, Safe and secure from all alarms; Leaning, leaning, Leaning on the everlasting arms. Oh, how sweet to walk in this pilgrim way, Leaning on the everlasting arms; Oh, how bright the path grows from day to day, Leaning on the everlasting arms. What have I to dread, what have I to...

Iye Wa Ni Wiwo, Eni Ta Kan Mogi

Words: Miss Amelia Matilda Hull Iye wa ni wiwo, Eni t'a kan mo'gi Iye wa nisisiyi fun o; Nje wo O elese k' o le ri igbala, Wo Enit' a kan mo 'gi fun o. Refrain: Wo! wo! wo k' o ye, Iye wa ni wiwo Enit'a kan mo gi Iye wa nisisiyi fun o. Kil' o se ti On fi dabi Bi a ko gb' ebi re ru Jesu! Eje 'wenumo se san lati iha Re, B' iku Re ko j' etu f' ese re? Ki s' ekun 'piwada ati adura re, Eje na l' o s' etutu f' okan; Gbe eru ese re lo si odo Eni, Ti o tit a eje na sile. Ma siyemeji s' ohun t' Olorun wi, Ko s'ohun t'o ku lati se mo, Ati pe On yio wa nikehin aiye, Y'o si s'asepari ise Re. Nje wa f'ayo gba iye ainipekun, Ni owo Jesu ti fifun ni; Si mo daju pe iwo ko si le ku lai, N'gbati Jesu Ododo re wa. Source: Yoruba Baptist Hymnal #177 There is life for a look at the Crucified One, There is life at this moment for thee; Then look, sinner, look unto H...

E Yin Oba Ogo / Praise The King of Glory

Author: Eliza Edmunds Hewitt Eyin Oba ogo, Oun ni Olorun Yin fun 'se 'yanu ti o ti fihan O wa pelu awon ero mimo l'ona O si je imole won l'osan l'oru. Refrain Eyin Angel 'didan, lu duru wura Ki gbogbo yin juba, t'e nwo oju re Ni gbogbo 'joba re, b'aye ti nyi lo Ise re y'o ma yin Ise re y'o ma yin Fi ibukun fun Oluwa okan mi. E yin fun 'rapada ti gbogbo okan E yin fun orisun imularada Fun inu rere ati itoju re Fun 'daniloju pe O ngbo adura, E yin fun idanwo bi okun ife, T'o nso wa po mo awon ohun orun Fun 'gbagbo ti n'segun , 'reti ti ki sa Fun ile ogo t'O ti pese fun wa. Praise the king of Glory, He is God alone, Praise Him for the wonders He to us hath shown; For His promised presence, All the pilgrim way, For the flaming pillar, and the cloud by day. Refrain: Praise Him, shining angels, s trike your harps of gold, All His hosts adore Him, who His face behold; Throug...

Jerusalem T'orun

Writer: Samuel Crossman Tune: Christchurch Jerusalem t' orun, Orin mi, ilu mi! Ile mi bi mba ku, Ekun ibukun mi; Refrain: Ibi ayo! Nigbawo ni, Ngo r' oju re, Olorun mi? Odi re, ilu mi, T' a fi pearl se l' oso; 'Lekun re ndan fun 'yin, Wura ni ita re! Orun ki ran nibe, Beni ko s' osupa; A ko wa iwonyi, Kristi n' imole ibe. Nibe l' Oba mi wa, T' a da l' ebi l' aiye, Angeli nkorin fun, Nwon si nteriba fun. Patriak' igbani, Par' ayo won nibe; Awon woli, nwon nwo Omo Alade won. Nibe ni mo le ri Awon apostili, At' awon akorin Ti nlu harpu wura. Ni agbala wonni, Ni awon martir' wa; Nwon wo aso ala, Ogo bo ogbe won. T' emi yi sa su mi, Ti mo ngb' ago kedar! Ko si 'ru yi l' oke, Nibe ni mo fe lo. English Version Jerusalem on high, My song and city is, My home whene’er I die, The centre of my bliss; Refrain Oh, happy place! When shall I be, My God, with T...

Lai Lodo Oluwa

Words: James Montgomery, 1835. Music: English melody "Lai lodo Oluwa!" Amin, beni k'o ri, Iye wa ninu oro na, Aiku ni titi lai, Nihin ninu ara, Mo sako jinna si; Sibe alale ni mo nfi, Ojo kan sunmole! Ile Baba loke, Ile okan mi ni; Emi nfi oju igbagbo Wo bode wura re! Okan mi nfa pupo, S' ile na ti mo fe, Ile didan t' awon mimo Jerusalem t' orun. Awosanma dide, Gbogbo ero mi pin; Bi adaba Noa, mo nfo Larin iji lile. Sugbon sanma kuro, Iji si rekoja, Ayo ati alafia Si gba okan mi kan. L' oro ati l' ale L' osan ati l' oru, Mo ngbo orin orun, bori Rudurudu aiye, Oro ajinde ni, Hiho isegun ni, Lekan si, "Lai lod' Oluwa." Amin, beni ko ri. Source: Yoruba Baptist Hymnal #538 “Forever with the Lord!” Amen, so let it be! Life from His death is in that word ’Tis immortality. Here in the body pent, Absent from Him I roam, Yet nightly pitch my moving tent A day’s march nearer home My Fat...

Mo Mo P'Oludande Mi N Be

Words By Samuel Medley (1775) Tune: Duke Street "Mo mo p'Oludande mi n be;" Itunu nla l'eyi fun mi! O mbe, Enit' o ku lekan; O mbe, Orin iye mi lai. O mbe, lati ma bukun mi, O si mbebe fun mi loke; O mbe, lati ji mi n'boji, Lati gba mi la titi lai. O mbe, Ore korikosun. Ti y'o pa mi mo de opin; O mbe, emi o ma korin, Woli, Alufa, Oba mi. O mbe, lati pese aye, Y'o si mu mi de 'be l'ayo; O mbe, ogo l' oruko Re; Jesu, okanna titi lai. O mbe, mo bo low' aniyan; O mbe, mo bo lowo ewu; A! ayo l' oro yi fun mi, "Mo mo p' Oludande mi mbe!" Source: Yoruba Baptist Hymnal #140 I know that my Redeemer lives! What joy this blest assurance gives! He lives, he lives, who once was dead; he lives, my ever-living Head! He lives triumphant from the grave; he lives eternally to save; he lives exalted, throned above; he lives to rule his church in love. He lives to bless me with his love; he l...

Ose, Ose Rere

Ose, ose rere, Iwo ojo 'simi; O ye k' a fi ojo kan, Fun Olorun rere; B' ojo mi tile m' ekun wa, Iwo n' oju wa nu; Iwo ti s' ojo ayo, Emi fe dide re. Ose, ose rere, A k'yo sise loni; A o f' ise wa gbogbo Fun aisimi ola, Didan l' oju re ma dan, 'Wo arewa ojo; Ojo mi nso ti lala, Iwo nso t' isimi. Ose, ose rere, Ago tile nwipe, F' Eleda re l' ojo kan, T' O fun O ni mefa; A o f' ise wa sile, Lati lo sin nibe, Awa ati ore wa, Ao los' ile adua. Ose, ose rere, Wakati re wu mi; Ojo orun n' iwo se, 'Wo apere orun, Oluwa je ki njogun 'Simi lehin iku, Ki nle ma sin O titi, Pelu enia Re. Source: Yoruba Baptist Hymnal #37 Hallowed Day and Holy Thou holy day of rest We ought to give one full day To God, the good and kind Other days bring the tear drops Thou wipes the tears away Thou art a day of gladness I love thy happy morn. Hallowed Day and Holy There is no work today ...

A BAPTIS' WA SINU IKU

Unable to find author A baptis' wa sinu iku, Nipa itebo 'mi; A sin wa 'nu 'boji Jesu, A sin wa pelu Re. A ba Krist' ku k' a ba ye se, K' a le ji pelu Re, K' a le jere ebun titun T' y'o mu wa ye f' oke. Emi, fi ara Re fun wa; K' oro wa ko le je Ireti Oluwa l' oke, At' ifarahan Krist'. Fun igbagbo wa li ogo, Ayo ati ade, Lat' aiye k' a le wa l' oke K' a joko pelu Krist'. Source: Yoruba Baptist Hymnal #377 We are baptised unto His death, By water baptism; And we go down into the grave, Buried with Christ Jesus. Buried with Christ to sin no more, That we may rise in Him, That we may partake of new grace That fits us for the skies. O Holy Ghost, come unto us, That all our words may be The hope of His soon appearing, And Christ's revelation. Lord, let our faith be glorified Our joy and crow fulfil; To live a life of heav'n on earth, On high to reign with the...

KRIST' KI 'JOBA RE DE

Words: Lewis Hensley, 1867 Music: St. Cecilia, Kingsland Krist' ki 'joba Re de, Ki ase Re bere; F' opa-rin Re fo Gbogbo ipa ese. Ijoba ife da, Ati t' Alafia? Gbawo ni irira Yio tan bi t'orun? Akoko na ha da, T' ote yio pari, Ika at' ireje, Pelu ifekufe? Oluwa joo, dide, Wa n'nu agbara Re; Fi ayo fun awa Ti o nsaferi Re Eda ngan ooko Re, 'Koko nje agbo Re; Iwa 'tiju pupo Nfihan pe 'fe tutu. Ookun bole sibe, Ni ile keferi: Dide 'Rawo ooro, Dide, mase wo mo. Amin. Source: Yoruba Baptist Hymnal #149 English Thy kingdom come, O God! Thy rule, O Christ begin! Break with thine iron rod the tyrannies of sin! Where is thy reign of peace, and purity and love? When shall all hatred cease, as in the realms above? When comes the promised time that war shall be no more, oppression, lust, and crime shall flee thy face before? We pray thee, Lord, arise, and come in thy great might; revive our lon...

Ija D'opin, Ogun Si Tan

Author Unknown Translated from Latin to English by Francis Pott Alleluya! Alleluya!! Alleluya!!! Ija d' opin, ogun si tan: Olugbala jagun molu: Orin ayo l' a o ma ko. Alleluya! Gbogbo ipa n' iku si lo: Sugbon Kristi f' ogun re ka: Aiye E ho iho ayo - Alleluya! Ojo meta na ti koja. O jinde kuro nin' oku: E f' ogo fun Olorun wa. -Alleluya! O d' ewon orun apadi, O s' ilekun orun sile: E korin iyin 'segun Re. - Alleluya! Jesu nipa iya t' O je, A bo lowo iku titi: Titi l' a o si ma yin O. - Alleluya! Source: Yoruba Baptist Hymnal #123 Alleluia, alleluia, alleluia! The strife is o'er, the battle done, the victory of life is won; the song of triumph has begun.  Alleluia! The powers of death have done their worst, but Christ their legions hath dispersed: let shout of holy joy outburst. Alleluia! The three sad days are quickly sped, he rises glorious from the dead: all glory to our risen Head! Allelui...

Jesu Ye Titi Aye

Words: Christian Friedrich Gellert (1715-1769), 1757 Translated by Frances E. Cox (1812-1897), 1841 Tune: St Albinus Jesu ye; titi aiye Eru iku ko ba ni mo; Jesu ye; nitorina Isa oku ko n 'ipa mo. - Alleluya! Jesu ye; lat' oni lo Iku je ona si iye; Eyi y'o je ' tunu wa 'Gbat' akoko iku ba de. - Alleluya! Jesu ye; fun wa l' O ku; Nje Tire ni a o ma se; A o f'okan funfun sin, A o f'ogo f'Olugbala. - Alleluya! Jesu ye; eyi daju, Iku at' ipa okunkun Ki y'o le ya ni kuro Ninu ife nla ti Jesu. - Alleluya! Jesu ye; gbogbo 'joba L'orun, li aiye, di Tire; E ja ki a ma tele Ki a le joba pelu Re. - Alleluya. Source: Yoruba Baptist Hymnal #125 Jesus lives! thy terrors now can no more, O death, appal us; Jesus lives! by this we know thou, O grave, canst not enthrall us. Alleluia! Jesus lives! henceforth is death but the gate of life immortal; this shall calm our trembling breath when we pass its gloomy...

Jesu N Pe WA L'osan l'oru

Image
Author: Cecil Frances Alexander (1852) Jesu npe wa l' osan, l' oru Larin irumi aiye; Lojojumo l' a ngb' ohun Re Wipe, "Kristian, tele Mi." Awon Apostili 'gbani, Ni odo Galili ni; Nwon ko ile, ona sile, Gbogbo nwon si nto lehin. Jesu npe wa larin lala Aiye wa buburu yi; Larin Afe aiye, O nwi Pe, "Kristian, e feran Mi." Larin ayo at' ekun wa, Larin 'rora on osi, Tantan L' O npe l' ohun rara Pe, "Kristian, e feran Mi." Olugbala, nip' anu Re, Je ki a gbo ipe Re, F' eti 'gboran fun gbogbo wa, K' a fe O ju aiye lo. Jesus calls us: o'er the tumult Of our life's wild, restless sea; Day by day his sweet voice soundeth Saying, "Christian, follow me." As, of old, apostles heard it By the Galilean lake, Turned from home and toil and kindred, Leaving all for his dear sake. Jesus calls us from the worship Of the vain world's golden store, From each idol t...

Fun Wa N'le Onigbagbo

Image
Author: B.B McKinney Fun wa n’le onigbagbo Ile ti a nkeko Bibeli Ile ti a nlepa ‘fe Baba Ta f’ewa ife re de lade Fun wa n’le Onigbagbo /2ce Fun wa n’le Onigbagbo Nibi ti Baba j’olotito Ile t’o t’akete si ibi Ile t’o kun f’ayo ‘fe at’orin Fun wa n’le onigbagbo /2ce Fun wa n’le Onigbagbo ‘le t’iya nsise b’oba obinrin Fihan p’ona re lo dara ju Ile ti ngba Jesu l’alejo Fun wa n’le Onigbagbo /2ce Fun wa n’le onigbagbo Ni’bi ti an nto awon omode L’ati mo Kristi t’o feran won Ile t’ina adura tin jo Fun wa n’le onigbagbo /2ce *From Hymn Book for All Churches in Africa: Yoruba & English with Halleluyah Chorus Aroyehun Edition. God, give us Christian homes! Homes where the Bible is loved and taught, Homes where the master’s will is sought, Homes crowned with beauty thy love hath wrought; God, give us Christian homes; God, give us Christian homes! God, give us Christian homes! Homes where the father is true and strong, Homes that are free from the blig...

A O Sise!

Words: Fanny J Crosby, 1869 Music: W. Howard Doane, 1871 A o sise ! A o sise! Om'Olorun ni wa, Jek' a tele ona ti Oluwa wa to; K' a f' imoran Re so agbara wa d' otun, K' a fi gbogbo okun wa sise t' a o se. Refrain: Foriti ! Foriti ! Foriti ! Foriti ! K' a reti, k' a s' ona Titi Oluwa yio fi de. A o sise ! A o sise ! Bo awon t' ebi npa, Ko awon alare lo s' orisun iye! Ninu agbalebu l' awa o ma s' ogo, Nigbat' a ba nkede pe, "Ofe n'igbala," A o sise ! A o sise ! Gbogbo wa ni yio se, Ijoba okunkun at'iro yio fo, Ao si gbe oruko Jehofah leke, won, Ninu orin iyin wa pe, "Ofe n'igbala," A o sise ! A o sise !  L'agbara Oluwa, Agbada at'ade yio si je ere wa; Ile awon oloto yio si je ti wa, Gbogbo wa o jo ho pe, "Ofe n'igbala," To the work! to the work! We are servants of God, Let us follow the path that our Master has trod; With the might of His p...

Mo Fe O N'gbagbogbo

Author: An­nie S. Hawks, 1872 Mo fe O n'gbagbogbo, Oluwa Olore Ko s' ohun ti nfun ni L' alafia bi Tire. Refrain: Mo fe O, a! mo fe O, Ni wakati gbogbo; Bukun mi Olugbala, Mo wa s' odo Re. Mo fe O n' gbagbogbo, Duro ti mi, Idanwo ko n' ipa Gbat' O wa nitosi. Mo fe O n' gbagbogbo, L' ayo tab' irora; Yara wa ba mi gbe, K' aiye mi ma j' asan. Mo fe O n'gbagbogbo, Ko mi ni ife Re; K' O je k'ileri Re Se si mi li ara. Mo fe O n'gbagbogbo, Ologo julo; Se mi n' Tire toto, Omo alabukun. I need Thee every hour, Most gracious Lord; No tender voice like Thine can peace afford. Refrain I need Thee, O I need Thee; Every hour I need Thee; O bless me now, my Savior, I come to Thee. I need Thee every hour, stay Thou nearby; Temptations lose their power when Thou art nigh. I need Thee every hour, In joy or pain; Come quickly and abide, Or life is in vain. I need Thee every ...