Ìyanu, Aláàánú Olùgbàlà / Wonderful, Merciful Saviour
Authors: Dawn Rodgers / Eric Wyse
Ìyanu, Olùgbàlà aláàánú, Olùràpadà, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n
Ta ni 'bá rò p' Ọ̀d'àgùntàn
Lè gbọkàn èèyàn là Àní, O gbọkàn ènìyàn là Olùdámọ̀ràn, Olùtùnú, Olùpamọ́ Ẹ̀mí ta fẹ́ fà mọ́ra O fún wa n'rètí gbọkàn wa Ti rìnnà ṣáko lọ Àní, a ti rìnnà ṣáko lọ. Ègbè Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Èdùmàrè, Baba àìlópin, O fẹ́ wa ní òtítọ́ N'nú àìlera wa la wólẹ̀ Níwájú ìtẹ́ Rẹ Àní, ní iwájú ìtẹ́ Rẹ Ègbè Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (30/04/2020) |
Wonderful, merciful Saviour
Precious Redeemer and Friend Who would've thought that a Lamb could Rescue the souls of men Oh, You rescue the souls of men Counselor, Comforter, Keeper Spirit we long to embrace You offer hope when our hearts have Hopelessly lost our way Oh, we've hopelessly lost the way Refrain You are the One that we praise You are the One we adore You give the healing and grace Our hearts always hunger for Oh, our hearts always hunger for Almighty, infinite Father Faithfully loving Your own Here in our weakness You find us Falling before Your throne Oh, we're falling before Your throne Refrain You are the One that we praise You are the One we adore You give the healing and grace Our hearts always hunger for Oh, our hearts always hunger for Songwriters: Dawn Rodgers / Eric Wyse Wonderful, Merciful Saviour lyrics © Warner Chappell Music, Inc Source: LyricFind |
Comments
Post a Comment