Posts

Showing posts from June, 2023

FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH

Image
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye,  Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka  Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun.  Fun iyanu wakati  Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan,  Ọmọ 'ya, obi, ọmọ,  Ọrẹ aye, ọrẹ oke,  Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ  Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ,  Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth  For the glory of the skies,  For the love which from our birth  Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise,  This our hymn of grat...

E Yin! E Yin!/Praise Him! Praise Him!

Author: Fanny J. Crosby (1869) E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'orin aye, e kede 'fe nla Re! E kii! E kii! Eyin angeli ologo; F'ipa at'ola f'oruko Re mimo! B'Olus'aguntan, Jesu yoo s'awon 'mo Re, Lapa Re lo n gbe won lojojumo. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! Fun ese wa, o jiya, o si ku. Apata wa, ireti 'gbala ailopin, E kii! E kii! Jesu t'a kan mo'gi. E ro iyin Re! O ru ibanuje wa; Ife nla, to yanu, to jin, to ki. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'iro hosanna ko gba orun kan! Jesu Olugbala joba titi aye; E dee lade! Woli, Al'fa, Oba! Krist' n pada bo! Lori aye n'isegun, Agbara, ogo - t'Oluwa nii se. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (06/06/2023) Praise Him! Praise Him!  Jesus, our blessed Redeeme...