Ọkàn, O Ha Ń Ṣàárẹ̀ / O Soul, Are You Weary
Ọkàn, o ha ń ṣàárẹ̀, o ń dààmú Òkùn ṣú kò sí ìmọ́lẹ̀ 'Mọ́lẹ̀ wà t'o bá w'Olùgbàlà 'Yè lọ́pọ̀lọpọ̀ àt' ọ̀fẹ́ Kọ ojú rẹ sí Jésù Wò ojú ìyanu Rẹ̀ Àwọn nǹkan ayé yóò si di bàìbàì N'nú 'mọ́lẹ̀ ògo, or' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Láti 'kú lọ s' íyè àínìpẹ̀kun O kọjá, a sì tẹ̀le lọ Lórí i wa ẹ̀ṣẹ̀ kò lágbára Àwá ju aṣẹ́gun lọ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ k'yo' kùnà, Ó lérí Gbà á gbọ́, yóò dára fún ọ Sì lọ sí ayé tí ń kú lọ Sọ ti ìgbàlà pípé' Rẹ̀ Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 12th April, 2024 |
Source: Baptist Hymnal 1991 #320 |
Comments
Post a Comment