Wọn Yoo Ṣe 'Ranti / Only Remembered
A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀ T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo, Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. ÈGBÈ: Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe, Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa, Lati maa kore oko t' a ti gbìn?, Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé, Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii, Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa, Eso ikore at' on t' a ti ṣe. 'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀, T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn, 'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀, T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe. | Fading away like the stars of the morning, Refrain Only remembered, only remembered, Shall we be missed though by others succeeded, Only the truth that in life we have spoken, Source: Hallowed Hymns, New and Old #185 |
Comments
Post a Comment