Fi 'Bùkún F'Ólúwa, Ìwọ Ọkàn Mi / Bless the Lord Oh My Soul
Songwriters: Jonas Myrin / Matt Redman Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Òrùn ti jí Ojúmọ́ tún ti mọ́ Ó tó àkókò láti kọrin Rẹ síi Ohun tó lè dé Ohun tó lè wà níwájú mi Jẹ́ kí n máa kọrin t'ìrọ̀lẹ́ bá dé Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ O pọ̀ nífẹ̀ẹ́ O lọ́ra láti bínú Oókọ Rẹ ńlá Onínúure ni Ọ́ Fun gbogbo oore Rẹ N óò maa kọrin títí Ìdí ẹgbàrún Fọ́kàn mi láti wá Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Lọ́jọ́ náà 'Gb' okun mi bá ń ṣákì Tópin súnmọ́ T' àkókò mi dé Síbẹ̀ ọkàn mi Yóò kọrin àìlópin Ọdún ẹgbàrún Àti títí láí Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Translated to Yoruba on 23/07/2024 by A...