Fi 'Bùkún F'Ólúwa, Ìwọ Ọkàn Mi / Bless the Lord Oh My Soul
Songwriters: Jonas Myrin / Matt Redman
Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Òrùn ti jí Ojúmọ́ tún ti mọ́ Ó tó àkókò láti kọrin Rẹ síi Ohun tó lè dé Ohun tó lè wà níwájú mi Jẹ́ kí n máa kọrin t'ìrọ̀lẹ́ bá dé Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ O pọ̀ nífẹ̀ẹ́ O lọ́ra láti bínú Oókọ Rẹ ńlá Onínúure ni Ọ́ Fun gbogbo oore Rẹ N óò maa kọrin títí Ìdí ẹgbàrún Fọ́kàn mi láti wá Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Lọ́jọ́ náà 'Gb' okun mi bá ń ṣákì Tópin súnmọ́ T' àkókò mi dé Síbẹ̀ ọkàn mi Yóò kọrin àìlópin Ọdún ẹgbàrún Àti títí láí Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀ Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ | Bless the Lord oh my soul Oh my soul Worship His Holy name Sing like never before Oh my soul I'll worship Your Holy name The sun comes up It's a new day dawning It's time to sing Your song again Whatever may pass And whatever lies before me Let me be singing When the evening comes Bless the Lord oh my soul Oh my soul Worship His Holy name Sing like never before Oh my soul I'll worship Your Holy name You're rich in love And You're slow to anger Your name is great And Your heart is kind For all Your goodness I will keep on singing Ten thousand reasons For my heart to find Bless the Lord oh my soul Oh my soul Worship His Holy name Sing like never before Oh my soul I'll worship Your Holy name Bless You Lord And on that day When my strength is failing The end draws near And my time has come Still my soul will Sing Your praise unending Ten thousand years And then forevermore Bless the Lord oh my soul Oh my soul Worship His Holy name Sing like never before Oh my soul I'll worship Your Holy name Bless You Lord Source: LyricFind |
Comments
Post a Comment