Yin Oluwa Olodumare / Praise to the Lord, the Almighty

Author: Joachim Neander

Yin Oluwa 
Olodumare, Ọba Ẹlẹda
Yin ọkan mi
To r’on ni ‘lera ati ‘gbala rẹ
Ẹyin t’ẹ gbọ, 
Ẹ sunmọ tẹmpili Rẹ 
Ẹ ba mi f’ayọ juba Rẹ.

Yin Oluwa, 
Ẹni t’O jọba lor’ ohun gbogbo 
To dabobo, 
To si gbe ọ ro labẹ iyẹ Rẹ 
O ha ri pe 
Gbogbo ohun to tọ lo ṣe 
B’ O ti lana n’ipilẹṣẹ?

Yin Oluwa, 
Ẹni to da ọ t'ẹ̀rù, tìyanu 
M'ara rẹ le 
To gbe ọ ró nígbà tí o ṣubú 
L'aini, ẹ̀dùn
Ko ha fun ọ n'itura? 
O f'ìyẹ́ anu Rẹ̀ bo ọ.
 
Yin Oluwa 
To n bukun ’ṣẹ rẹ to si n gbeja rẹ; 
L’otitọ 're ati anu rẹ n tọ ọ lẹyin 
Ronu lọtun Ohun t’Oluwa le ṣe, 
Ẹni to fifẹ yan ọ lọrẹ.

Yin Oluwa, 
Ẹni, n'gba t' awọn iji n jagun, 
Ẹni, n'gba t' awọn 'ṣẹ̀dá 
N runú, si n ja yi ọ ka, 
Mu wọn dákẹ́ 
Sọ 'binu wọn d' alafia 
To mú 'jì, omi dákẹ́ jẹ́.
 
Yin Oluwa, Ẹni, nigba okunkun ẹṣẹ n pọ sii, 
Ẹni, nigba awọn eeyan buburu n gberu sii, 
Tan mọle Rẹ̀, O l' ẹ̀rù alẹ́ danu, 
F'anu yi awọn mimọ ka

Yin Oluwa! 
Ki gbogb’ẹya ara mi juba Rẹ 
Ki gbogbo ohun t’o 
L’ẹmi wa pẹlu iyin Rẹ. 
Jeki iro 
Amin dun jakejado, 
Layọ la o juba rẹ titi. Amin.

Verses 1, 2, 4 and 7 sourced from CAC GHB 95 with some modifications by me.

Verses 3, 5 and 6 translated by Ayobami Temitope Kehinde on January 24, 2025

Praise to the Lord!
The Almighty, the King of creation!
O my soul, praise Him,
For He is thy health and salvation!
All ye who hear,
Now to His temple draw near;
Join me in glad adoration.

Praise to the Lord!
Who o’er all things so wondrously reigneth,
Shelters thee under His wings,
Yea, so gently sustaineth;
Hast thou not seen
How thy desires have been
Granted in what He ordaineth?

Praise to the Lord,
Who hath fearfully, wondrously, made thee;
Health hath vouchsafed
And, when heedlessly falling, hath stayed thee.
What need or grief
Ever hath failed of relief?
Wings of His mercy did shade thee.

Praise to the Lord,
Who doth prosper thy work and defend thee;
Surely His goodness
And mercy here daily attend thee.
Ponder anew
What the Almighty can do,
If with His love He befriend thee!

Praise to the Lord, Who, when tempests their warfare are waging,
Who, when the elements
Madly around thee are raging,
Biddeth them cease,
Turneth their fury to peace,
Whirlwinds and waters assuaging.

Praise to the Lord,
Who, when darkness of sin is abounding,
Who, when the godless
Do triumph, all virtue confounding,
Sheddeth His light,
Chaseth the horrors of night,
Saints with His mercy surrounding.

Praise to the Lord,
O let all that is in me adore Him!
All that hath life and breath,
Come now with praises before Him! Let the Amen
Sound from His people again,
Gladly for aye we adore Him!

Comments

Popular posts from this blog

JESU NI BALOGUN OKO

E BA WA YIN OLUWA, ALLELUYA!

Mo N Tesiwaju Lona Na