'Bi 'Sadi Nla L'Olorun Wa / A Mighty Fortress is Our God
Author: Martin Luther (1529) 'Bi'sadi nla l'Ọlọrun wa, Odi wa ti ko le yẹ; Olùrànlọ́wọ́ n'nu igbi, Idanwo to yi wa ka 'Tori ọta 'gba nni, Tun fẹ ṣe wa n'ibi; Agbara re si pọ, Pẹlu ikorira, Ko s'iru rẹ ni aye yi. A ko gbẹkẹl' agbara wa, Tori yo ja wa kulẹ Ti ko ba si pe Ẹni naa, Ti Ọlọrun yan fun wa O fẹ m'Ẹni naa bi? Jesu Kristi ni iṣe Oluwa Ologun, Ẹni ayeraye, Yoo si ṣẹgun ni dandan. B'ẹmi aimọ ni gbogb'aye, N halẹ lati bo wa mọlẹ; A ki o bẹru 'tor'Ọlọrun Fẹ ṣẹgun nípasẹ̀ wa; Ọm' alade okunkun, Ẹ̀rù rẹ̀ ko ba wa A o bori 'runu rẹ Iparun rẹ daju Ọr' Ọlọ́run yoo bii ṣubu Ọrọ yẹn ju agbara aye lọ, Ṣíọ̀ sí wọn, o wa titi, Ẹ̀mí at' awọn ẹ̀bùn Rẹ̀ Jẹ tiwa nipasẹ Jesu. Ẹrù, ará lè lọ, At' ara kiku yìí Won le pa ara yìí: Oot' Ọlọ́run sì wà Ìjọba Rẹ̀ wà títí láí. Source: Hymnaro #703 (Some adjustments made in the translation by me, Ayobami Temitope Keh...