JESU NI BALOGUN OKO
 Author Unknown     Jesu ni Balogun oko  E mase je ka foya  Olutoko wa ni Jesu  Y'o mu oko wa gunle   Refrain:   E ma se beru  E kun fun ayo  Nitori Jesu l'oga oko  Bo ti wu k'iji na le to  Y'o mu oko wa gunle    Eyin ero t'o wa l'oko  E kepe Jesu nikan  K'e si gbeke yin le Jesu  Y'o mu oko wa gunle   Olugbala 'wa toro Re  Mu igb'omi pa roro  Iwo t'o rin lori omi  T'o sun, beni ko si nkan   Kil' ohun to nba yin leru  Eyin omo 'gun Kristi  Bi Jesu ba wo ' nu oko  Awa y'o fi 'gbi rerin   'Gbati 'gbi aye yi ba nja  Lor' okun ati n'ile  Abo kan mbe ti o daju  Lodo Olugbala wa   Lowo kiniun at' ekun  Lowo eranko ibi  Jesu y'o dabobo Tire  Jesu y'o pa Tire mo   Metalokan Alagbara  Dabobo awa omo Re  Lowo a'tegun ati 'ji  Je k'awa k' alleluyah   Ogo ni fun Baba loke  Ogo ni fun Omo Re  Ogo ni fun Emi Mimo  Metalokan l'ope ye.  Jesus is the Captain of the ship,  So, do no let us ...