Posts

Jerusalem T'orun

Writer: Samuel Crossman Tune: Christchurch Jerusalem t' orun, Orin mi, ilu mi! Ile mi bi mba ku, Ekun ibukun mi; Refrain: Ibi ayo! Nigbawo ni, Ngo r' oju re, Olorun mi? Odi re, ilu mi, T' a fi pearl se l' oso; 'Lekun re ndan fun 'yin, Wura ni ita re! Orun ki ran nibe, Beni ko s' osupa; A ko wa iwonyi, Kristi n' imole ibe. Nibe l' Oba mi wa, T' a da l' ebi l' aiye, Angeli nkorin fun, Nwon si nteriba fun. Patriak' igbani, Par' ayo won nibe; Awon woli, nwon nwo Omo Alade won. Nibe ni mo le ri Awon apostili, At' awon akorin Ti nlu harpu wura. Ni agbala wonni, Ni awon martir' wa; Nwon wo aso ala, Ogo bo ogbe won. T' emi yi sa su mi, Ti mo ngb' ago kedar! Ko si 'ru yi l' oke, Nibe ni mo fe lo. English Version Jerusalem on high, My song and city is, My home whene’er I die, The centre of my bliss; Refrain Oh, happy place! When shall I be, My God, with T...

Lai Lodo Oluwa

Words: James Montgomery, 1835. Music: English melody "Lai lodo Oluwa!" Amin, beni k'o ri, Iye wa ninu oro na, Aiku ni titi lai, Nihin ninu ara, Mo sako jinna si; Sibe alale ni mo nfi, Ojo kan sunmole! Ile Baba loke, Ile okan mi ni; Emi nfi oju igbagbo Wo bode wura re! Okan mi nfa pupo, S' ile na ti mo fe, Ile didan t' awon mimo Jerusalem t' orun. Awosanma dide, Gbogbo ero mi pin; Bi adaba Noa, mo nfo Larin iji lile. Sugbon sanma kuro, Iji si rekoja, Ayo ati alafia Si gba okan mi kan. L' oro ati l' ale L' osan ati l' oru, Mo ngbo orin orun, bori Rudurudu aiye, Oro ajinde ni, Hiho isegun ni, Lekan si, "Lai lod' Oluwa." Amin, beni ko ri. Source: Yoruba Baptist Hymnal #538 “Forever with the Lord!” Amen, so let it be! Life from His death is in that word ’Tis immortality. Here in the body pent, Absent from Him I roam, Yet nightly pitch my moving tent A day’s march nearer home My Fat...

Mo Mo P'Oludande Mi N Be

Words By Samuel Medley (1775) Tune: Duke Street "Mo mo p'Oludande mi n be;" Itunu nla l'eyi fun mi! O mbe, Enit' o ku lekan; O mbe, Orin iye mi lai. O mbe, lati ma bukun mi, O si mbebe fun mi loke; O mbe, lati ji mi n'boji, Lati gba mi la titi lai. O mbe, Ore korikosun. Ti y'o pa mi mo de opin; O mbe, emi o ma korin, Woli, Alufa, Oba mi. O mbe, lati pese aye, Y'o si mu mi de 'be l'ayo; O mbe, ogo l' oruko Re; Jesu, okanna titi lai. O mbe, mo bo low' aniyan; O mbe, mo bo lowo ewu; A! ayo l' oro yi fun mi, "Mo mo p' Oludande mi mbe!" Source: Yoruba Baptist Hymnal #140 I know that my Redeemer lives! What joy this blest assurance gives! He lives, he lives, who once was dead; he lives, my ever-living Head! He lives triumphant from the grave; he lives eternally to save; he lives exalted, throned above; he lives to rule his church in love. He lives to bless me with his love; he l...

Ose, Ose Rere

Ose, ose rere, Iwo ojo 'simi; O ye k' a fi ojo kan, Fun Olorun rere; B' ojo mi tile m' ekun wa, Iwo n' oju wa nu; Iwo ti s' ojo ayo, Emi fe dide re. Ose, ose rere, A k'yo sise loni; A o f' ise wa gbogbo Fun aisimi ola, Didan l' oju re ma dan, 'Wo arewa ojo; Ojo mi nso ti lala, Iwo nso t' isimi. Ose, ose rere, Ago tile nwipe, F' Eleda re l' ojo kan, T' O fun O ni mefa; A o f' ise wa sile, Lati lo sin nibe, Awa ati ore wa, Ao los' ile adua. Ose, ose rere, Wakati re wu mi; Ojo orun n' iwo se, 'Wo apere orun, Oluwa je ki njogun 'Simi lehin iku, Ki nle ma sin O titi, Pelu enia Re. Source: Yoruba Baptist Hymnal #37 Hallowed Day and Holy Thou holy day of rest We ought to give one full day To God, the good and kind Other days bring the tear drops Thou wipes the tears away Thou art a day of gladness I love thy happy morn. Hallowed Day and Holy There is no work today ...

A BAPTIS' WA SINU IKU

Unable to find author A baptis' wa sinu iku, Nipa itebo 'mi; A sin wa 'nu 'boji Jesu, A sin wa pelu Re. A ba Krist' ku k' a ba ye se, K' a le ji pelu Re, K' a le jere ebun titun T' y'o mu wa ye f' oke. Emi, fi ara Re fun wa; K' oro wa ko le je Ireti Oluwa l' oke, At' ifarahan Krist'. Fun igbagbo wa li ogo, Ayo ati ade, Lat' aiye k' a le wa l' oke K' a joko pelu Krist'. Source: Yoruba Baptist Hymnal #377 We are baptised unto His death, By water baptism; And we go down into the grave, Buried with Christ Jesus. Buried with Christ to sin no more, That we may rise in Him, That we may partake of new grace That fits us for the skies. O Holy Ghost, come unto us, That all our words may be The hope of His soon appearing, And Christ's revelation. Lord, let our faith be glorified Our joy and crow fulfil; To live a life of heav'n on earth, On high to reign with the...

KRIST' KI 'JOBA RE DE

Words: Lewis Hensley, 1867 Music: St. Cecilia, Kingsland Krist' ki 'joba Re de, Ki ase Re bere; F' opa-rin Re fo Gbogbo ipa ese. Ijoba ife da, Ati t' Alafia? Gbawo ni irira Yio tan bi t'orun? Akoko na ha da, T' ote yio pari, Ika at' ireje, Pelu ifekufe? Oluwa joo, dide, Wa n'nu agbara Re; Fi ayo fun awa Ti o nsaferi Re Eda ngan ooko Re, 'Koko nje agbo Re; Iwa 'tiju pupo Nfihan pe 'fe tutu. Ookun bole sibe, Ni ile keferi: Dide 'Rawo ooro, Dide, mase wo mo. Amin. Source: Yoruba Baptist Hymnal #149 English Thy kingdom come, O God! Thy rule, O Christ begin! Break with thine iron rod the tyrannies of sin! Where is thy reign of peace, and purity and love? When shall all hatred cease, as in the realms above? When comes the promised time that war shall be no more, oppression, lust, and crime shall flee thy face before? We pray thee, Lord, arise, and come in thy great might; revive our lon...

Ija D'opin, Ogun Si Tan

Author Unknown Translated from Latin to English by Francis Pott Alleluya! Alleluya!! Alleluya!!! Ija d' opin, ogun si tan: Olugbala jagun molu: Orin ayo l' a o ma ko. Alleluya! Gbogbo ipa n' iku si lo: Sugbon Kristi f' ogun re ka: Aiye E ho iho ayo - Alleluya! Ojo meta na ti koja. O jinde kuro nin' oku: E f' ogo fun Olorun wa. -Alleluya! O d' ewon orun apadi, O s' ilekun orun sile: E korin iyin 'segun Re. - Alleluya! Jesu nipa iya t' O je, A bo lowo iku titi: Titi l' a o si ma yin O. - Alleluya! Source: Yoruba Baptist Hymnal #123 Alleluia, alleluia, alleluia! The strife is o'er, the battle done, the victory of life is won; the song of triumph has begun.  Alleluia! The powers of death have done their worst, but Christ their legions hath dispersed: let shout of holy joy outburst. Alleluia! The three sad days are quickly sped, he rises glorious from the dead: all glory to our risen Head! Allelui...