Posts

E BA WA YIN OLUWA, ALLELUYA!

Image
Eni t'O f'orun sile t'O wa s'aye Lati ku fun ese araye gbogbo; E korin aleluya s'Oba mimo Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. Refrain: E ba wa yin Oluwa,  Aleluya! Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga, E ba wa yin Oluwa,  Aleluya! Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga, Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. E ba wa yin Oluwa,  Aleluya! Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. Eni t'O pa wa mo o lojojumo, Eni t'O n yo wa ninu ewu gbogbo Eni t'O n pa Israeli mo k'itogbe Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. Eni t'O n pese fun aini wa laye, Eni t'O n sore fun wa lojo gbogbo, Ore t'O n se fun wa ko l'onka rara; Eni ba more Jesu ko ba wa gbe ga. He who left heav'n and came into the world And to die for the sins of all the people Sing hallelujah unto the holy King He who knows the goodness of Jesus should praise Him. Refrain: Come and let us praise the Lord, Hallelujah! He who knows the goodness of Jesus should praise Him

Jesu O Seun/ Jesus Thank You

Writer:Pat Sczebel Adiitu agbelebu ko ye mi sibẹ, Irora ti Kalfari-- Ìwọ t'O pe t'O si mọ lu Ọmọ Rẹ T'O m'ago ikoro to yẹ ki n mu. Chorus Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ti wẹṣẹ mi nu, Jesu O seun. Irunu Ọlọrun walẹ pata, Jesu O seun. Mo ti jọta Rẹ ri, Wayi mo n ba Ọ jeun, Jesu O seun. Nipa 'rubọ pipe Rẹ la fi fa mi, O s' ọta Rẹ dọrẹ Rẹ; Ọrọ or'ọfẹ ologo Rẹ lo tu jade, Aanu at' inu're Rẹ ko lopin. Bridge Olufẹ́ ọkan mi, Mo fẹ́ ma wa fun Ọ. Translated by Ayobami Temitope  Kehinde (21/04/2017) The mystery of the cross I cannot comprehend The agonies of Calvary-- You the perfect Holy One, crushed Your Son, Who drank the bitter cup reserved for me. CHORUS Your blood has washed away my sin Jesus, thank You The Father’s wrath completely satisfied Jesus, thank You Once Your enemy, now seated at Your table Jesus, thank You By Your perfect sacrifice I’ve been brought near, Your enemy You’ve made Your friend; Pouring out the riches of Yo

Lojoojo, Oluwa/ Day By Day, Dear Lord

Image
Author:Richard of Chichester (1197 – 3 April 1253) Lojoojo, Oluwa Ohun meta mo beere K'emi le ri O sii Ki n le nife Re sii K'emi le tele O sii Lojoojo Translation by Ayobami Temitope (19/04/2017) Day by day, dear Lord of you Three things I pray: To see you more clearly, To love you more dearly, To follow you more nearly, Day by day. Source here

Olurapada, Olugbala, Ore/ Redeemer, Saviour, Friend

Image
Author: Darrell Evans Mo mo pe mo wa lokan Re 'Gba t'O gori oke lo 'Tor' O foju ayérayé ri mi 'Gba mo si wa'nu ese Olurapada, Olugbala, Ore Refrain: Olurapada, tun r'okan mi pada Olugbala, wa bo mi ki n ma dese Iwo mo ailera mi O s'otito dopin Olurapada, Olugbala, Ore Gbogbo ina t'a fi b'eyin Re je At'egun to w' ori Re Iso ta kan mo'wo ailabawon So pe 'fe Re ko lopin Olurapada, Olugbala, Ore Tor' eyi or' ofe Re laye mi Yoo ma je fun iyin Re Pel'ayo n o f'awon ade mi lele F'oruko ta fi gba mi la(x2) Translated by Ayobami Temitope Kehinde (19/04/017) I know You had me on Your mind When You climbed up on that hill For You saw me with eternal eyes While I was yet in sin Redeemer, Saviour, Friend Refrain: Redeemer redeem my heart again Savior come and shelter me from sin You're familiar with my weakness Devoted to the end Redeemer, Saviour, Friend Every stripe

Emi Anu, Oto, Ife/ Spirit of Mercy, Truth And Love

Author Unknown Emi anu, oto, ife, Ran agbara Re t' oke wa; Mu iyanu ojo oni, De opin akoko gbogbo. Ki gbogbo orile-ede, Ko orin ogo Olorun, Ki a si ko gbogbo aiye, N' ise Olurapada wa. Olutunu at' Amona, Joba ijo enia Re, K'araiye mo ibukun Re, Emi anu, oto, ife. Source: Baptist Hymnal #156 Spirit of mercy, truth and love, O shed Thine influence from above, And still from age to age convey The wonders of this sacred day. Be God’s amazing glory sung; Let all the listening earth be taught The wonders by our Savior wrought. Still o’er Thy holy Church preside; Unfailing Comfort, heavenly  Guide, In every clime, by every tongue, Still let mankind Thy blessings prove, Spirit of mercy, truth and love. Source here .

Ogo Fun Olorun Baba/ Glory Be To God The Father

Author: Horatius Bonar Ogo fun Olorun Baba, Ogo f' Olorun Omo, Ogo fun Olorun Emi, Jehofa, Metalokan; Ogo, ogo. B' aiyeraiye ti nkoja. Ogo fun Enit' o few a, T' o we abawon wa nu; Ogo fun Enit' o ra wa, T' o mu wa ba Onj' oba; Ogo, ogo, Fun Od'-agutan t' a pa. "Ogo, 'bukun, iyin lailai!" L' awon ogun orun nko; "Ola, oro, ipa, 'joba!" L' awon eda fi nyin I, Ogo, ogo, Fun Oba awon oba. Source: Baptist Hymnal #157 Glory be to God the Father, Glory be to God the Son, Glory be to God the Spirit: Great Jehovah, Three in One! Glory, glory While eternal ages run! Glory be to him who loved us, Washed us from each spot and stain; Glory be to him who bought us, Made us kings with him to reign! Glory, glory To the Lamb that once was slain! Glory to the King of angels, Glory to the Church’s King, Glory to the King of nations; Heaven and earth, your praises brin

A Fiyin Aiku Fun

Writer: Isaac Watts A f' iyin aiku fun 'Fe Olorun Baba, Fun itunu t' aiye, At' ireti t' orun: O ran 'Mo Re aiyeraiye Lati ku fun ese t' a da. T' Olorun Omo ni Ogo lailai pelu, T' o f' eje Re ra wa N'nu egbe ainipekun : O ye, O joba nisiyi, O si nri eso iya Re. Wole fun oruko, Olorun emi lai, Enit' agbara Re So elese d' aye: On l' o par' ise 'gbala wa, L' o si f' ayo orun k' okan. 'Wo Olodumare, L' ola ye titi lai, Eni Metalokan, T' O tobi, t' O l' ogo: Nibiti ipa ero pin, 'Gbagbo bori, ife sin yin. Source: Baptist Hymnal #158 We give immortal praise To God the Father’s love, For all our comforts here, And better hopes above; He sent His own eternal Son, To die for sins that man had done. To God the Son belongs Immortal glory too, Who bought us with His blood From everlasting woe: And now He lives, and now He r