Posts

Showing posts from December, 2013

FREE MUSIC DOWNLOAD

Hi friends, I just released three singles. You can download them free of charge from this link:   www.reverbnation.com/ preciousay

ISUN KAN WA

William Cowper, 1731-1800 Isun kan wa to kun feje, O yo niha Jesu. Elese mokun ninu re, O bo ninu ebi. Gba mo figbagbo risun naa, Ti n san fun ogbe Re, Irapada dorin fun mi Ti n o ma ko titi. Ninu orin to dun ju lo, Lemi o korin Re: 'Gba t'akololo ahon yii Ba dake niboji. Mo gbagbo p'O pese fun mi (Bi mo tile saiye) Ebun ofe ta feje ra, Ati duru wura. Duru ta towo'Olorun se, Ti ko ni baje lai: T'a o ma fi yin Baba wa, Oruko Re nikan. Source: YB Hymnal #232 There is a fountain filled with blood, Drawn from Immanuel’s veins, And sinners plunged beneath that flood Lose all their guilty stains: The dying thief rejoiced to see That fountain in His day; And there may I, though vile as he, Washed all my sins away: Dear dying Lamb, Thy precious blood Shall never lose its pow’r, Till all the ransomed church of God Are safe, to sin no more: E’er since by faith I saw the stream Thy flowing wounds supply, Redeeming love has been...

IGBAGBO MI DURO LORI

By Edward Mote Igbagbo mi duro lori Eje atododo Jesu N'ko je gbekele ohun kan Leyin oruko nla Jesu Mo duro le Krist' apata Ile miran, iyanrin ni B'ire ije mi tile gun Ore-ofe Re ko yi pada Bo ti wu k'iji na le to Idakoro mi ko ni ye Mo duro le Krist' apata Ile miran iyanrin ni Majemu ati eje Re L'emi o ro mo b'ikunmi de Gbati ohun aye bo tan O je ireti nla fun mi Mo duro le Krist' apata Ile miran iyanrin ni Gbat'ipe kehin ba si dun A! m ba le wa lodo Jesu Ki nwo ododo Re nikan Ki n duro niwaju ite Mo duro le Krist' apata Ile miran iyanrin ni My hope is built on nothing less Than Jesus’ blood and righteous; No merit of my own I claim But wholly lean on Jesus’ name. On Christ, the solid rock, I stand; All other ground is sinking sand. When darkness veils his lovely face, I ret on his unchanging grace; In every high and story gale My anchor holds within the veil. On Christ, the solid rock, I stand; All oth...

MO TI NI JESU LORE

By  William Charles Fry (1837–1882) Mo ti ni Jesu lore O j'ohun gbogbo fun mi Oun nikan larewa ti okan mi fe Oun nitanna ipado Oun ni Enikan naa To le we mi nu kuro nin'ese mi Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori Oun n'Itanna Ipado Irawo Owuro Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori Oun n'Itanna Ipado Irawo Owuro Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe O gbe gbogbo banuje At'irora mi ru O j'Odi agbara mi n'gba danwo Tori Re mo k'ohun gbogbo Ti mo ti fe sile O si f'agbara Re gbe okan mi ro Bi aye tile ko mi Ti Satan' dan mi wo Jesu yoo mu mi d'opin irin mi Oun n'Itanna ipado Irawo Owuro Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe Oun ki yo fi mi sile Be ki yo ko mi nihin Niwon ti m'ba figbagbo pofin Re mo O jodi ina yi mi ka N k'y'o beru-keru Y'o fi manna Re bokan mi t'ebi npa Gba m'b...

ENI KAN NBE TO FERAN WA

Author: Marianne Nunn (1778-1847) Enikan nbe to feran wa A! O fe wa! Ife Re ju t'iyekan lo A! O fe wa! Ore aye nko wa sile Boni dun, ola le koro Sugbon Ore yi ki ntan ni A! O fe wa! Iye ni fun wa ba ba mo A! O fe wa! Ro, ba ti je ni gbese to A! O fe wa! Eje Re lo si fi ra wa Nin'aginju l'O wa wa ri O si mu wa wa sagbo Re A! O fe wa! Ore ododo ni Jesu A! O fe wa! O fe lati ma bukun wa A! O fe wa! Okan wa fe gbo ohun Re Okan wa fe lati sunmo Oun na ko si ni tan wa ke A! O fe wa! Oun lo je ka ridariji A! O fe wa! Oun o le ota wa sehin A! O fe wa! Oun o pese 'bukun fun wa Ire la o ma ri titi Oun o fi mu wa lo sogo A! O fe wa! One is kind above all others, Oh, how He loves! His is love beyond a brother’s, Oh, how He loves! Earthly friends may fail or leave us, One day soothe, the next day grieve us; But this Friend will ne’er deceive us: Oh, how He loves! ’Tis eternal life to know Him, Oh, how He loves! Think, oh, think how ...

MO TI SELERI JESU

By John Ernest Bode (February 13, 1816 – October 6, 1874) Mo ti seleri Jesu Lati sin O dopin Ma wa lodo mi titi Baba mi Ore mi Emi k'yo beru ogun B'Iwo ba sun mo mi Emi ki yo si sina B'O ba fona han mi Je ki n mo p'O sunmo mi 'Tori'baje aye Aye fe gba okan mi Aye fe tan mi je Ota yi mi kakiri Lode ati ninu Sugbon Jesu sunmo mi Dabo bo okan mi Je ki emi ko ma gbo Ohun Re, Jesu mi Ninu igbi aye yi Titi nigbagbogbo So ko fokan mi bale Te 'ri okan mi ba So kemi le gbo Tire 'Wo Olutoju mi 'Wo ti seleri Jesu F'awon to tele O Pe ibikibi t'O wa Lawon yoo si wa Mo ti seleri Jesu Lati sin O dopin Je ki n ma to O lehin Baba mi, Ore mi Je ki n ma ripase Re Ki n le ma tele O Agbara Re nikan ni Ti m' ba le tele O To mi, pe mi, si fa mi Di mi mu de opin Si gba mi si odo Re Baba mi, Ore mi O Jesus, I have promised To serve Thee to the end; Be Thou forever near me, My Master and my Friend; I shall not...

GBA AYE MI OLUWA

Frances Ridley Havergal (1874) Gba aye mi, Oluwa Mo ya si mimo fun O Gba gbogbo akoko mi Ki won kun fun iyin re Gba owo mi ko si je Ki n ma lo fun ife Re Gba ese mi ko si je Ki won ma sare fun O Gba ohun mi je ki n ma Korin f'Oba mi titi Gba ete mi, je ki won Ma jise fun O titi Gba wura, fadaka mi Okan nki o da duro Gba ogbon mi, ko si lo Gege bi o ba ti fe Gba 'fe mi fi se Tire Ki yo tun je temi mo Gbokan mi, Tire ni se Ma gunwa nibe titi Gba feran mi, Oluwa Mo fi gbogbo re fun O Gbemi paapa latoni Ki n je Tire titi lai. Take my life and let it be Consecrated, Lord, to Thee. Take my moments and my days, Let them flow in endless praise. Take my hands and let them move At the impulse of Thy love. Take my feet and let them be  Swift and beautiful for Thee.  Take my voice and let me sing, Always, only for my King.  Take my lips and let them be  Filled with messages from Thee.  Take my silver and my gold,  Not ...

Olugbala Gbohun Mi

Words: Fanny Crosby Olugbala gbohun mi Gbohun mi, gbohun mi Mo wa sodo Re gba mi Nibi agbelebu Emi se, sugbon O ku Iwo ku, Iwo ku Fi anu Re pa mi mo Nibi agbelebu Oluwa jo gba mi Nk'y'o bi O n'inu mo Alabukun gba mi Nibi agbelebu Bi n o ba tile segbe N o bebe, n o bebe Iwo ni Ona, iye Nibi agbelebu Ore ofe Re ta gba Lofe ni, lofe ni Foju anu Re wo mi Nibi agbelebu Feje mimo Re we mi Fi we mi, fi we mi Ri mi sinu ibu Re Nibi agbelebu Gbagbo lo le fun wa ni Dariji, dariji Mo figbagbo ro mo O Nibi agbelebu Loving Saviour, hear my cry, Hear my cry, hear my cry; Trembling to Thine arms I fly: O save me at the Cross! I have sinn'd, but Thou hast died, Thou hast died, Thou hast died; In Thy mercy let me hide: O save me at the Cross! Lord Jesus, receive me, No more would I grieve Thee, Now, blessed Redeemer, O save me at the Cross! Tho' I perish I will pray, I will pray, I will pray; Thou of life the Living Way: O...

Jesu Ni Gbogbo Aye Fun Mi

Author: Will L. Thompson (1847-1909) Jesu ni gbogbo aye fun mi Iye at'ayo mi Agbara mi lojojumo Laisi Re mo subu Ni'banuje Oun ni mo to Nitori ko s'eni bi Re Ni'banuje O m'ayo wa Ore mi. Jesu ni gbogbo aye fun mi Ore nigba 'danwo Fun ibukun Oun ni mo to Mo ni lopolopo O morun ran, o mojo ro Ikore wura si n po si Orun ojo at'ikore Ore mi Jesu ni gbogb'aye fun mi Nko si ni tan Oun je O ti buru to bi mo se Gbat'Oun ko tan mi je? Ni tito Re nko le sina O n toju mi losan loru Ni tito Re losan loru Ore mi Jesu ni gbogb'aye fun mi Nko fe elomiran N o gbekele nisisiyi T'ojo aye nkoja Aye ewa lodo Re na Aye ewa ti ko lopin Iye, ayo ainipekun Ore mi Jesus is all the world to me, my life, my joy, my all; He is my strength from day to day, without Him I would fall: when I am sad, to Him I go; no other one can cheer me so; when I am sad, He makes me glad; He's my friend. Jesus is all the world to me, ...

A WE O?

  Elisha Albright Hoffman (1839-1929) O ti to Jesu f'agbara 'wenumo? A we o nin'eje Odo-aguntan? Iwo ha ngbekele oore-ofe Re? Refrain A we O Nin'eje Nin'ej'Od'aguntan fun okan Aso re a funfun o si mo laulau A we o nin'eje Odo-aguntan? O m ba Olugbala rin lojojumo? A we o nin'eje Odo-aguntan? O simi le Eniti a kan mo'gi? A we o nin'eje Odo-aguntan? Aso re funfun lati pad'Oluwa? O mo lau nin'eje Odo-aguntan? Okan re mura fun'le didan loke? Ka we o nin'eje Odo-aguntan? Have you been to Jesus for the cleansing pow’r? Are you washed in the blood of the Lamb? Are you fully trusting in His grace this hour? Are you washed in the blood of the Lamb? Are you washed in the blood, In the soul-cleansing blood of the Lamb? Are your garments spotless? Are they white as snow? Are you washed in the blood of the Lamb? Are you walking daily by the Savior’s side? Are you washed in the blood of the Lamb? Do ...

TUN MU WA SOJI

W. P. Mackay A yin O'lorun nitor'Omo 'fe Re Fun Jesu ti o ku to si lo soke Halleluyah, tire logo Halleluyah, Amin Halleluyah, Tire logo Tun mu wa soji A yin O'lorun f'emi imole Re To f'Olugbala han t'O mu 'mole wa Ogo ati'yin f'Odaguntan ta pa To mu gbogb'ese wa lo to w'eri wa nu Sa mu wa soji, f'ife Re k'okan wa K'okan gbogbo gbina fun ina orun We praise Thee, O God!  for the Son of Thy love ,  For Jesus who died  and is now gone above. Hallelujah! Thine the glory. Hallelujah! Amen. Hallelujah! Thine thee glory. Revive us again. We praise Thee, O God! F or Thy Spirit of light, Who hath shown us our Saviour,  and scattered our night. All glory and praise  to the Lamb that was slain, Who hath borne all our sins,  and hath cleansed ev’ry stain. Revive us again;  fill each heart with Thy love; May each soul be rekindled  with fire from above.

ARE MU O, OKAN RE PORURU

Edmund Simon Lorenz (1854-1942) Are mu O, okan re poruru? So o fun Jesu: Ibanuje dipo ayo fun o? So o fun Jesu nikan. So o fun Jesu; so o fun Jesu Oun lore ti yoo mo Ko tun sore Ati'yekan bi Re So o fun Jesu nikan Asun-dakun omije lo nsun bi? So o fun Jesu, so o fun Jesu, O l'ese to farasin f'eniyan So o fun Jesu nikan 'Banuje teri okan re ba bi? So o fun Jesu, so o fun Jesu O ha nsaniyan ojo ola bi? So o fun Jesu nikan Ironu iku mu o damu bi? So o fun Jesu, so o fun Jesu Okan re nfe ijoba Jesu bi! So o fun Jesu nikan Are you weary, are you heavy hearted? Tell it to Jesus, tell it to Jesus. Are you grieving over joys departed? Tell it to Jesus alone. Tell it to Jesus, tell it to Jesus, He is a friend that’s well known. You’ve no other such a friend or brother, Tell it to Jesus alone. Do you fear the gathering clouds of sorrow? Tell it to Jesus, tell it to Jesus. Are you anxious what shall be tomorrow? Tell it to Jesus alone....

BO TI DUN LATI GBA JESU

Louisa M. R. Stead, c. 1850-1917 Bo ti dun lati gba Jesu Gbo gege bi oro Re Ka simi lor'ileri Re Sa gbagbo l'Oluwa wi Jesu, Jesu, emi gbagbo Mo gbekele n'gbagbogbo Jesu, Jesu, Alabukun Ki nle gbekele O si Bo ti dun lati gba Jesu Ka gbeje wenumo Re Igbagbo ni ki a fi bo Sin'eje 'wenumo na Bo ti dun lati gba Jesu Ki nk'ara ese sile Ki ngb'ayo, iye, isimi Lati odo Jesu mi Mo yo mo gb'eke mi le O Jesu mi, Alabukun Mo mo pe o wa pelu mi 'N'toju mi titi d'opin. ’Tis so sweet to trust in Jesus, Just to take Him at His Word; Just to rest upon His promise, And to know, “Thus saith the Lord!” Jesus, Jesus, how I trust Him! How I’ve proved Him o’er and o’er; Jesus, Jesus, precious Jesus! Oh, for grace to trust Him more! Oh, how sweet to trust in Jesus, Just to trust His cleansing blood; And in simple faith to plunge me ’Neath the healing, cleansing flood! Yes, ’tis sweet to trust in Jesus, Just from sin and sel...

KO SORE BI JESU ONIRELE

  Johnson Oatman Jr. (1856-1926) Ko s'ore bi Jesu onirele Ko s'okan! Ko s'okan! Ko s'elomi to le w'okan wa san Ko s'okan! Ko s'okan! Jesu mo gbogbo idaamu wa Yo toju wa d'opin ojo Ko s'ore bi Jesu onirele Ko s'okan! Ko s'okan! Ko s'ore bi Re to ga ni Mimo Ko s'okan! Ko s'okan! Ko s'ore to tutu to n'irele Ko s'okan! Ko sokan! Ko s'akoko ti Oun ko sun mo wa Ko s'okan! Ko s'okan! Ko  s'oru tife Re ko tu won n'nu Ko s'okan! Ko s'okan! Eni kan ha ti r'ore yi nko ni? Ko s'okan! Ko s'okan! Tabe'elese ri ko ni gba oun la? Ko s'okan! Ko s'okan! Ebun kan ha wa bi Jesu fun wa? Ko s'okan! Ko s'okan! Yo ha ko fun wa ka nile l'orun? Ko je ko! Ko je ko! There's not a Friend like the lowly Jesus: No, not one! no, not one! None else could heal all our souls' diseases: No, not one! no, not one! Jesus knows all about our strugg...

WA SODO JESU

Image
Words: George F. Root, 1870 Wa sodo Jesu, ma se duro N'nu oro Re lo ti fona han wa O duro ni arin wa loni O n wi jeje pe, " Wa" Egbe Ipade wa yio je ayo Gb'okan wa ba bo lowo ese A o si wa pelu Re Jesu Ni ile wa lailai Je k'omode wa A! Gb'ohun Re Je kokan gbogbo fo fun ayo Ki a si yan A layanfe wa Ma duro, sugbon wa Tun ro, O wa pelu wa loni F'eti s'ofin Re ko si gboran Gbo b'ohun Re ti n wi pele pe, "Wa, omo mi, e wa!" Come to the Savior, make no delay; Here in His Word He has shown us the way; Here in our midst He’s standing today, Tenderly saying, “Come!” Refrain Joyful, joyful will the meeting be, When from sin our hearts are pure and free; And we shall gather, Savior, with Thee, In our eternal home . “Suffer the children!” oh, hear His voice! Let ev’ry heart leap forth and rejoice; And let us freely make Him our choice; Do not delay, but come. Think once again, He’s with us today; Heed...

KA TO SUN OLUGBALA WA

Image
I will never forget this hymn (the Yoruba translation) that was a popular go-to-bed hymn in those days when I was growing up. It's a song rich in meaning: WORDS BY JAMES EDMESTON.  MUSIC BY GEORGE C. STEBBINS. Ka to sun Olugbala wa Fun wa nibukun ale A jewo ese wa fun O Iwo lo le gba wa la Bi ile tile su dudu Okun ko le se wa mo Iwo eni ti kii saare So awon eniyan Re Ni irele a fara wa Sabe abo Re Baba Jesu 'Wo to sun bi awa Se orun wa bi tire Emi mimo rado bo wa So wa lokunkun oru Tit'awa yo fi ri ojo Imole ayeraye B'iparun tile yi wa ka Ti ofa n fo wa koja Awon angeli yi wa ka Awa o wa lailewu Sugbon biku ba ji wa pa T'ibusun wa diboji Je kile mo wa sodo Re Layo atalafia.  Source: Yoruba Baptist Hymnal #61 Saviour, breathe an evening blessing Ere repose our spirits seal; Sin and want we come confessing: Thou canst save, and Thou canst heal. Though the night be dark and dreary, Darkness cannot hide from Thee; Thou art He wh...