Yin Oluwa Olodumare / Praise to the Lord, the Almighty
Author: Joachim Neander Yin Oluwa Olodumare, Ọba Ẹlẹda Yin ọkan mi To r’on ni ‘lera ati ‘gbala rẹ Ẹyin t’ẹ gbọ, Ẹ sunmọ tẹmpili Rẹ Ẹ ba mi f’ayọ juba Rẹ. Yin Oluwa, Ẹni t’O jọba lor’ ohun gbogbo To dabobo, To si gbe ọ ro labẹ iyẹ Rẹ O ha ri pe Gbogbo ohun to tọ lo ṣe B’ O ti lana n’ipilẹṣẹ? Yin Oluwa, Ẹni to da ọ t'ẹ̀rù, tìyanu M'ara rẹ le To gbe ọ ró nígbà tí o ṣubú L'aini, ẹ̀dùn Ko ha fun ọ n'itura? O f'ìyẹ́ anu Rẹ̀ bo ọ. Yin Oluwa To n bukun ’ṣẹ rẹ to si n gbeja rẹ; L’otitọ 're ati anu rẹ n tọ ọ lẹyin Ronu lọtun Ohun t’Oluwa le ṣe, Ẹni to fifẹ yan ọ lọrẹ. Yin Oluwa, Ẹni, n'gba t' awọn iji n jagun, Ẹni, n'gba t' awọn 'ṣẹ̀dá N runú, si n ja yi ọ ka, Mu wọn dákẹ́ Sọ 'binu wọn d' alafia To mú 'jì, omi dákẹ́ jẹ́. Yin Oluwa, Ẹni, nigba okunkun ẹṣẹ n pọ sii, Ẹni, nigba awọn eeyan buburu n gberu sii, Tan mọle Rẹ̀, O...