Oluwa Mi Mo N Jade Lo
Charles Wesley, Hymns and Sacred Poems, 1749 . OLUWA mi, mo njade lo, Lati se ise ojo mi; Iwo nikan l' emi o mo, L' oro, l' ero ati n' ise. Ise t' O yan mi l' anu Re Je ki nle se tayotayo; Ki nr' oju Re n'nu ise mi, K' emi si fi ife Re han. Dabobo mi lowo 'danwo, K' O pa okan mi mo kuro Lowo aniyan aiye yi, Ati gbogbo ifekufe. Iwo t'oju Re r' okan mi, Ma wa lowo otun mi lai, Ki nma sise lo l' ase Re, Ki nf' ise mi gbogbo fun O. Jeki nreru Re t'o fuye, Ki nma sora nigbagbogbo, Ki nma f' oju si nkan t' orun, Ki nsi mura d' ojo ogo. Ohunkohun t' O fi fun mi, Jeki nle lo fun ogo Re, Ki nf' ayo sure ije mi, Ki mba O rin titi d' orun. Source: Yoruba Baptist Hymnal #56 Forth in Thy Name, O Lord, I go, My daily labor to pursue; Thee, only Thee, resolved to know In all I think or speak or do. The task Thy wisdom hath assigned, O let me cheerfully fulfill; In a...