Posts

Mimo, Mimo / Holy, Holy

Author: Jimmy Owens (1972)  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde Mimo, mimo, mimo, mimo, Mimo, mimo, Olodumare; A gbokan wa soke si O lati fi ife wa han, Mimo, mimo, mimo, mimo. Baba Oloore, Baba Oloore A soriire p'a je omo Re, Baba Oloore; A gbori wa soke si O lati fi ife wa han, Baba Oloore, Baba Oloore. Jesu owon, Jesu owon A yo pupo p'O ra wa pada, Jesu owon; A gbowo wa soke si O lati fi ife wa han, Jesu owon, Jesu owon.    Emi Mimo, Emi Mimo, Wa kunnu okan wa lotun, Emi Mimo; A gbohun wa soke si O lati fi ife wa han, Emi Mimo, Emi Mimo. Holy, holy, holy, holy, Holy, holy, Lord God Almighty; And we lift our hearts before You as a token of our love, Holy, holy, holy, holy. Gracious Father, gracious Father, We're so blest to be Your children, gracious Father; And we lift our heads before You as a token of our love, Gracious Father, gracious Father. Precious Jesus, precious Jesus, We're so glad that You...

Halleluyah! Ogo Ni Fun Baba / Hallelujah! Glory To The Father

Author Unknown  Translated to English by Ayobami Temitope Kehinde Ẹ jẹ ka jumọ f'ọpẹ f'Ọlorun  Orin iyin, at'ọpẹ lo yẹ wa   Iyanu n'ifẹ Rẹ si gbogbo wa   Ẹ kọrin 'yin s'  Ọba Olore wa    Chorus:   Halleluyah! Ogo ni fun Baba   A f'ijo ilu yin Ọlọrun wa   Alaye ni o yin Ọ bo ti yẹ   Halleluyah! Ogo ni fun Baba     Ki l'a fi san j'awọn t'iku ti pa?   Iwọ lo f'ọwọ wọ wa di oni   'Wọ lo n sọ wa to n gba wa lọw'ewu   Ẹ kọrin 'yin s'Olutọju wa     Ohun wa ko dun to lati kọrin   Ẹnu wa ko gboro to fun ọpẹ   B'awa n'ẹgbẹrun ahọn nikọkan   Wọn kere ju lati gb'ọla Rẹ ga Let us give thanks to God together Songs of praises and thanks are befitting Marvelous is Your love to all of us Oh sing praises to our Gracious King Chorus: Hallelujah! Glory to the Father We praise ou...

Laarin Gbungbun Oye/ In The Bleak Midwinter

Image
Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìjì dídì ń sọkún Ayé le bí irin Omi bí òkúta Yìnyín bọ́ lórí yìnyín Lórí yìnyín Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Lọ́jọ́ ọjọ́un Ọlọ́run wa, ọ̀run kò gbàá,  Ayé kò lè gbée ró Ọ̀run, ayé yóò kọjá lọ 'Gb' Ó bá wá jọba. Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìbùjẹ́ ẹran tó fún Olúwa Alágbára Jésù Kristi.  Ó tó f' Ẹni tí Kérúbù Ń sìn lọ́saǹ lóru: Ọmú tó kuń fún wàrà Koríko ilé ẹran Ó tó f' Ẹni t'Angel' Ń wólẹ̀ fún o, Màálù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí Tí ń júbà Rẹ̀ Angel' nípò dépò 'Bá péjọ síbẹ̀ Kérúbù, Séráfù 'Bá wa 'nú afẹ́fẹ́; Ṣùgbọn Màmá Rẹ̀ nìkan, Wúndíá pẹ̀l' áyọ́ Fi ìfẹnukonu Sin Àyànfẹ́. Kínni mo lè fi fún Un, Èmi òṣì, àre Ǹ bá j' olúṣ'àgùntàn, Ǹ bá  fún Un l' ọ̀d'àgùntàn Ǹ bá jẹ́ Amòye Ǹ bá sápá tèmi, — Síbẹ ohun mo ní, mo fún Un, — Ọkàn mi. Trans...

Gbogb' Ọkàn Mí Yọ̀ Lálẹ́ Yìí / All My Heart This Night Rejoices

Image
Author: Paul Gerhardt English Translator: Catherine Winkworth Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Gbogb' ọkàn mí yọ̀ lálẹ́ yìí Bí mo tí ń gbọ́ Nílé lóko Ohùn áńgelì dídùn “A bí Krist'”, akọrin ń kọrin Títí i- bi gbogbo Yóò fi rinlẹ̀ fáyọ̀. ‘Jagunsẹ́gun ń jáde lọ lónì í Ó borí ọ̀tá, ẹ̀ṣẹ̀, ’Bìnújẹ́, ’kú, ’pò òkú Ọlọ́run dèèyàn láti gbà wá Ọmọ Rẹ̀, Ó jọ́kan Pẹ̀l' ẹ̀jè wa títí. A ṣì ń bẹ̀rù ’bín' Ọlọ́run, T’Ó fi fún wa Lọ́fẹ̀ ‘Ṣura Rẹ̀ tó ga jù? Láti rà wa padà l'Ó fún wa L’Ọmọ Rẹ̀ Látorí ’tẹ́ Ipá Rẹ ní ọrùn Ó d'Ọ̀dọ́ Àgùntàn t'Ó mú Ẹ̀ṣẹ̀ lọ́ Ó sì ṣe Ìpẹ̀tùsí  kíkún Ó fẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: Ìran wa Níp' oor'ọ̀fẹ́ Rẹ̀ a yẹ fún ògo. Gbóhùn kan láti ’bùjẹ́ ’ran Dídùn ni, Ó ń bẹ̀bẹ̀, “Sá fún ’dààmú, ewù Ará, ẹ ti gbà ’dásílẹ̀ Lọ́wọ́ ibi, Ohun ẹ nílò Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Wá wàyí, lé bànújẹ́ lọ Gbogbo yín, Lọ́kọ̀kan,...

Oba aiku, Airi, Orisun Ogbon/Immortal, Invisible God Only Wise

William Cowper, 1731-1800 Oba aiku, airi, orisun ogbon T'O wa n'nu imole toju ko le wo, Olubukunjulo, Ologojulo, Alagbara, Olusegun, 'Wo la yin. Laisimi, laiduro, ni idakeje, O n joba lo, O ko si se alaini; Giga ni idajo Re bi oke nla, Ikuku Re b'isun ire at'ife. O nte gbogbo eda alaye lohun, Nipa imisi Re won gbe igbe won A n dagba, a n gbile bi ewe igi, A si n ro; sugbon bakanaa l'Olorun. Baba nla Ologo, Imole pipe Angeli Re n juba, won bo oju won: Gbogbo 'yin la o mu wa, sa je ka ri O Ka ri olanla imole to bo O. Source: CAC Hymnal #99 Verse 4 retranslated by Ayobami Temitope Kehinde Oct 23, 2018. Immortal, invisible, God only wise, In light inaccessible hid from our eyes, Most blessed, most glorious, the Ancient of Days, Almighty, victorious, Thy great name we praise. Unresting, unhasting, and silent as light Nor wanting nor wasting, Thou rulest in might Thy justice like mountains high soaring above Thy clouds whic...

Oluwa Ran Mi Nise/Look and Live

Author: William A. Ogden (1841-1897) Oluwa ran mi ni ‘se, Aleluya! Iwo ni n o je ise na fun; A ko s‘inu Oro Re, Aleluya! P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye. Egbe Wo, k‘o ye, Arakunrin, Wo Jesu ki o si ye, A ko s‘inu Oro Re, Aleluya! P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye. A ran mi n‘ise ife,  Aleluya!  N o j‘isena fun o ore mi; Ise lat‘ oke wa ni; Aleluya! Jesu so, mo mo pe oto ni. A n‘owo iye si O, Aleluya! A o fi ‘ye ailopin fun O; T‘o ba wo Jesu nikan, Aleluya! Wo o, On nikan l‘o le gbala. Ma wi fun o bi mo se wa, Aleluya! Sodo Jesu to so mi dotun Mo gbagbo n'nu oruko Re, Aleluya! Mo gbekele O si gb'okan mi. Egbe  Source: Verses 1-3 from CAC Hymnal #208 Verse 4 translated by Ayobami Temitope Kehinde, October 23, 2018 I’ve a message from the Lord, hallelujah! This message unto you I’ll give, ’Tis recorded in His word, hallelujah! It is only that you “look and live.” Refrain: "Look and live", my brother live Look to Jesus now, and live; ’T...

Gbagbo Awon 'Ya Wa / Faith of Our Mothers

Author:  Arthur Bardwell Patten 'Gbagbo awon 'ya wa, 'gbagbo aaye Nn' orin at'adura, ale; N' alo at' ife eba ina, Ibagbe re si wa yi wa ka, 'Gbagbo' awon 'ya wa, aaye ni, Ao di o mu titi d'opin. 'Gbagbo awon 'ya wa, t'ifẹ ni, 'Bi 'gbekele 't' or'ofe ti nwa Yiya si mimo re ba a le je, 'Bere iran olola nla; Igbagbo 'ya wa, ife ni, Ao di o mu titi d'opin. 'Gbagbo awon 'ya wa nfona han ni, Nnu 'reti at' aigbagbo odo, B'oju at'ona wa tile sookun, T'ao ko tile le r'itoju Re. 'Gbagbo Iya wa, ti Kristi ni, Ao di o mu titi d'opin. 'Gbagbo Iya wa, ti Kristi ni, N'otito to ta 'jewo way o, O ntoju 'le o si gba ijo la, Iwa wa si nf' emi re han; 'Gbagbo 'ya wa ti Kristi ni, Ao di o mu titi d'opin. Source: Yoruba Baptist Hymnal #619 Faith of our mothers, living still  In cradle song and bedtime prayer, In...