Posts

Gbo 'gbe ayo! Oluwa de / Hark! The Glad Sound

Author:Philip Doddridge Gbo 'gbe ayo! Oluwa de, Jesu t' a seleri; Ki gbogbo okan mura de, K' ohun mura ko ' rin O de lati t' onde sile, L' oko eru Esu; 'Lekun 'de fo niwaju Re, Sekeseke 'rin da.     O delarin 'baje aiye Lati tan 'mole Re, Lati fun awon afoju N' iriran f' oju  won. O de! 'Tunu f' okan 'rora, Iwosan f' agbogbe; O de pel' opo 'sura Re Fun awon talaka. Hosanna wa, Oba 'lafia Ao kede bibo Re; Gbogbo orun y'o ma korin Oruko t' a feran. Source: YBH #90 Hark, the glad sound! The Savior comes, the Savior promised long! Let ev'ry heart prepare a throne, and ev'ry voice a song. He comes the pris'ners to release, in Satan’s bondage held; the gates of brass before Him burst, the iron fetters yield. He comes from thickest films of vice To clear the mental ray And on the eyeballs of the blind To pour celestial day. ...

Okan Mi Sunmo 'Te Anu / Approach, My Throne, The Mercy Seat

Author:John Newton Okan mi, sunmo 'te anu, Nibi Jesu ngb' ebe, F' irele wole l' ese Re, 'Wo ko le gbe nibe. Ileri Re ni ebe mi, Eyi ni mo mu wa; Iwo npe okan t' eru npa, Bi emi, Oluwa. Eru ese wo mi l' orun, Esu nse mi n' ise; Ogun l' ode, eru ninu, Mo wa isimi mi. Se Apata at' Asa mi, Ki nfi O se abo; Ki ndoju ti Olufisun, Ki nso pe Kristi ku. Ife iyanu! Iwo ku, Iwo ru itiju; Ki elese b' iru emi, Le be l' oruko Re. Source: YBH #212 Approach, my soul, the mercy seat where Jesus answers prayer; there humbly fall before his feet, for none can perish there. Thy promise is my only plea; with this I venture nigh: thou callest burdened souls to thee, and such, O Lord, am I. Bowed down beneath a load of sin, by Satan sorely pressed, by war without and fears within, I come to thee for rest. Be thou my shield and hiding place, that, sheltered near thy side, I...

Oro Ogbologbo / Ancient Words

Ronnie C. Jr. Freeman / Tony W. Wood Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde (08/19/2019) Oro mimo, ogbologbo Fun 'rin wa, laye yii, Won fokan Olorun han Je k'oro atijo nipa. Oro iye, ireti Fun wa ni agbara Ninu aye ti a wa yi Or' atijo mu wa dele. Egbe: Oro otito atijo O n yi wa pada, A si okan wa paya Je koro atijo nipa Oro mimo t'igbagbo wa Ta fi le wa lowo Nipase irubo Teti sor' otito Kristi Oro mimo, ogbologbo Fun 'rin wa, laye yii, Won f'okan Olorun han Je k'oro atijo nipa. Egbe Eje awon Mataya, Won ku fun igbagbo yii Gbohun won lodun dodun E moro yii lokukudun. Egbe Holy words long preserved For our walk in this world, They resound with God’s own heart. Oh let the ancient words impart. Words of Life, words of Hope Give us strength, help us cope In this world, where e’er we roam Ancient words will guide us Home. CHORUS: Ancient words ever true Changing me and changing you, We ...

Ekun Ko Le Gba Mi / Weeping Will Not Save Me (None But Jesus)

Author: Robert Lowry Ekun ko le gba mi, Bi mo le f'ekun we 'ju; Ko le mu eru mi tan, Ko le we ese mi nu; Ekun ko le gba mi. Egbe Jesu sun, o ku fun mi, O jiya lori igi Lati so mi d' ominira, On na l'O le gba mi. Ise ko le gba mi; Ise mi to dara ju, Ero mi t'o mo julo, Ko le so 'kan mi d'otun Ise ko le gba mi; (Egbe) 'Duro ko le gba mi, Enit'o junu ni mi; L'eti mi l'anu nke pe, Bi mo ba duro n o ku; 'Duro ko le gba mi, (Egbe) Igbagbo le gba mi, Jeki ngbeke l'Omo Re; Jeki ngbekele 'se Re, Jeki nsa si apa Re, Igbagbo le gba mi, (Egbe) . Source: YBH #193 Weeping will not save me Tho' my face were bathed in tears, That could not allay my fears, Could not wash the sins of years Weeping will not save me. Refrain: Jesus wept and died for me; Jesus suffered on the tree; Jesus waits to make me free; He alone can save me. Working will not save me Purest ...

Ko To K' awon Mimo Beru / The Saints Should Never Be Dismayed

Author: Cowper William Ko to k' awon mimo beru, Ki nwon so 'reti nu; 'Gba nwon ko reti 'ranwo Re, Olugbala yio de. Nigbati Abram mu obe, Olorun ni, "Duro;" Agbo ti o wa lohun ni Y'o dipo omo na." Dafid' dabi eran Soolu; Sugbon gbo! ota de! Soolu yi owo re pada Lati ja fun 'le naa. Gba Jona ri sinu omi, Ko ro lati yo mo; Sugbon Olorun ran eja T' o gbe lo s' ebute. B' iru ipa at' ife yi Ti po l' oro Re to! Emi ba ma k' aniyan mi Le Oluwa lowo! E duro de iranwo Re, B' o tile pe, duro; B' ileri na tile fa 'le Sugbon ko le pe de. Source: Stanzas 1, 2, 4, 5 & 6 from YBH #579 Stanza 3 translated by Ayobami Temitope Kehinde (08/16/2019) The saints should never be dismayed, Nor sink in hopeless fear; For when they least expect His aid, The Savior will appear. This Abr’am found: he raised the knife; God saw, and said, Forb...

Jesu, Agbara Mi / Jesus, My Strength, My Hope

Words:  Charles Wesley ,  Hymns and Sacred Poems  1742. Jesu, agbara mi, Iwo l' aniyan mi, Emi fi igbagbo w' oke, Iwo l' O ngb'adua. Jeki nduro de O, Ki nle se ife Re, Ki Iwo Olodumare K'o so mi di otun. Fun mi l' okan 'rele, Ti 'ma se ara re; Ti ntemole, ti ko nani Ikekun Satani: Okan t' ara re mo Irora at' ise; T' o nfi suru at' igboya Ru agbelebu re. Fun mi l' eru orun, Oju t' o mu hanhan, T'y'o wo O n'gb' ese sunmole, K' o ri b' Esu ti nsa. Fun mi ni emi ni, T' O ti pese tele. Emi t' o duro gangan lai T' o nf' adura s' ona. Mo fokan adura, Adura n'gba gbogbo, Ki n ma se kun s' ibawi Re, Ki n farada 'soro. 'Bukun to ga julo: Ki n gbadura n'gba gbogbo Lati 'nu ibu mo ke pe O, Ki n ma se rewesi. Mo fe 'bowo tooto, Ete kan to duro, Laifotape, emi o duro Fun O, f'oruko Re. Itara to gbona...

Ohun Gbogbo Tàn, Ó Lẹ́wà / All Things Bright And Beautiful

Author: Mrs Cecil Alexander Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (15/08/2019) 1. Ohun gbogbo tàn,  o lẹwa Ẹda nla, kekere Ohun gbogbo gbọ́n, ó n yanu Ọlọ́run dá gbogbo wọn.  2. 'Tanna kekere to ṣi Ẹyẹ bintin to n kọrin O da awọ didan wọn, Iyẹ wọn tintinni. Ohun gbogbo tan...  3. Ọlọ́rọ̀ 'nu gọ̀bì rẹ, Talaka lẹnu ọna rẹ, O da wọn nipo depo, O paṣẹ ipo wọn. Ohun gbogbo tan...  4. Oke ese aluko, Odo tí n ṣàn lọ, Ìrọ̀lẹ́ àt' òwúrọ̀, T'o n mofurufu tan. Ohun gbogbo tan...     5. Iji tutu n'nu ọyẹ, Orun igba ẹrun, Èso pipọn ni ọgbà,- Ó dá wọn lọkọ̀ọ̀kan. Ohun gbogbo tan...  6. Igi giga ninu 'gbo Ọdan ta ti n ṣere Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ẹ̀bá omi, Tá n pé jọ lójúmọ́. Ohun gbogbo tan...  7. O fojú fun wa lati ri Àt' ètè̀ ká lè sọ B'Edumare ti tobi to, To mohun gbogbo dara. Ohun gbogbo tan...  (Amin) 1. All things bright and beautiful, All creatures great and small,...