Posts

Showing posts from April, 2017

Jesu O Seun/ Jesus Thank You

Writer:Pat Sczebel Adiitu agbelebu ko ye mi sibẹ, Irora ti Kalfari-- Ìwọ t'O pe t'O si mọ lu Ọmọ Rẹ T'O m'ago ikoro to yẹ ki n mu. Chorus Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ti wẹṣẹ mi nu, Jesu O seun. Irunu Ọlọrun walẹ pata, Jesu O seun. Mo ti jọta Rẹ ri, Wayi mo n ba Ọ jeun, Jesu O seun. Nipa 'rubọ pipe Rẹ la fi fa mi, O s' ọta Rẹ dọrẹ Rẹ; Ọrọ or'ọfẹ ologo Rẹ lo tu jade, Aanu at' inu're Rẹ ko lopin. Bridge Olufẹ́ ọkan mi, Mo fẹ́ ma wa fun Ọ. Translated by Ayobami Temitope  Kehinde (21/04/2017) The mystery of the cross I cannot comprehend The agonies of Calvary-- You the perfect Holy One, crushed Your Son, Who drank the bitter cup reserved for me. CHORUS Your blood has washed away my sin Jesus, thank You The Father’s wrath completely satisfied Jesus, thank You Once Your enemy, now seated at Your table Jesus, thank You By Your perfect sacrifice I’ve been brought near, Your enemy You’ve made Your friend; Pouring out the riches of Yo...

Lojoojo, Oluwa/ Day By Day, Dear Lord

Image
Author:Richard of Chichester (1197 – 3 April 1253) Lojoojo, Oluwa Ohun meta mo beere K'emi le ri O sii Ki n le nife Re sii K'emi le tele O sii Lojoojo Translation by Ayobami Temitope (19/04/2017) Day by day, dear Lord of you Three things I pray: To see you more clearly, To love you more dearly, To follow you more nearly, Day by day. Source here

Olurapada, Olugbala, Ore/ Redeemer, Saviour, Friend

Image
Author: Darrell Evans Mo mo pe mo wa lokan Re 'Gba t'O gori oke lo 'Tor' O foju ayérayé ri mi 'Gba mo si wa'nu ese Olurapada, Olugbala, Ore Refrain: Olurapada, tun r'okan mi pada Olugbala, wa bo mi ki n ma dese Iwo mo ailera mi O s'otito dopin Olurapada, Olugbala, Ore Gbogbo ina t'a fi b'eyin Re je At'egun to w' ori Re Iso ta kan mo'wo ailabawon So pe 'fe Re ko lopin Olurapada, Olugbala, Ore Tor' eyi or' ofe Re laye mi Yoo ma je fun iyin Re Pel'ayo n o f'awon ade mi lele F'oruko ta fi gba mi la(x2) Translated by Ayobami Temitope Kehinde (19/04/017) I know You had me on Your mind When You climbed up on that hill For You saw me with eternal eyes While I was yet in sin Redeemer, Saviour, Friend Refrain: Redeemer redeem my heart again Savior come and shelter me from sin You're familiar with my weakness Devoted to the end Redeemer, Saviour, Friend Every stripe ...

Emi Anu, Oto, Ife/ Spirit of Mercy, Truth And Love

Author Unknown Emi anu, oto, ife, Ran agbara Re t' oke wa; Mu iyanu ojo oni, De opin akoko gbogbo. Ki gbogbo orile-ede, Ko orin ogo Olorun, Ki a si ko gbogbo aiye, N' ise Olurapada wa. Olutunu at' Amona, Joba ijo enia Re, K'araiye mo ibukun Re, Emi anu, oto, ife. Source: Baptist Hymnal #156 Spirit of mercy, truth and love, O shed Thine influence from above, And still from age to age convey The wonders of this sacred day. Be God’s amazing glory sung; Let all the listening earth be taught The wonders by our Savior wrought. Still o’er Thy holy Church preside; Unfailing Comfort, heavenly  Guide, In every clime, by every tongue, Still let mankind Thy blessings prove, Spirit of mercy, truth and love. Source here .

Ogo Fun Olorun Baba/ Glory Be To God The Father

Author: Horatius Bonar Ogo fun Olorun Baba, Ogo f' Olorun Omo, Ogo fun Olorun Emi, Jehofa, Metalokan; Ogo, ogo. B' aiyeraiye ti nkoja. Ogo fun Enit' o few a, T' o we abawon wa nu; Ogo fun Enit' o ra wa, T' o mu wa ba Onj' oba; Ogo, ogo, Fun Od'-agutan t' a pa. "Ogo, 'bukun, iyin lailai!" L' awon ogun orun nko; "Ola, oro, ipa, 'joba!" L' awon eda fi nyin I, Ogo, ogo, Fun Oba awon oba. Source: Baptist Hymnal #157 Glory be to God the Father, Glory be to God the Son, Glory be to God the Spirit: Great Jehovah, Three in One! Glory, glory While eternal ages run! Glory be to him who loved us, Washed us from each spot and stain; Glory be to him who bought us, Made us kings with him to reign! Glory, glory To the Lamb that once was slain! Glory to the King of angels, Glory to the Church’s King, Glory to the King of nations; Heaven and earth, your praises brin...

A Fiyin Aiku Fun

Writer: Isaac Watts A f' iyin aiku fun 'Fe Olorun Baba, Fun itunu t' aiye, At' ireti t' orun: O ran 'Mo Re aiyeraiye Lati ku fun ese t' a da. T' Olorun Omo ni Ogo lailai pelu, T' o f' eje Re ra wa N'nu egbe ainipekun : O ye, O joba nisiyi, O si nri eso iya Re. Wole fun oruko, Olorun emi lai, Enit' agbara Re So elese d' aye: On l' o par' ise 'gbala wa, L' o si f' ayo orun k' okan. 'Wo Olodumare, L' ola ye titi lai, Eni Metalokan, T' O tobi, t' O l' ogo: Nibiti ipa ero pin, 'Gbagbo bori, ife sin yin. Source: Baptist Hymnal #158 We give immortal praise To God the Father’s love, For all our comforts here, And better hopes above; He sent His own eternal Son, To die for sins that man had done. To God the Son belongs Immortal glory too, Who bought us with His blood From everlasting woe: And now He lives, and now He r...

Fun Aanu To Po B'iyanrin

Writer: John Newton Fun aanu t' o po b' iyanrin, Ti mo ngba lojojo Lat' odo Jesu Oluwa, Kili emi le tun? Kili ohun ti mo le fun un Lat' inu okan mi? Ese ti ba gbogbo re je, Ofo li o si je. Eyi l' ohun t' emi o se, F' ohun t' O se fun mi; Em' o mu ago igbala, Ngo kepe Olorun. Eyi l'ope ti mo le da, Emi osi, are; Ngo f' ebun Re se iyanju Lati ma bere si. Emi ko le sin b' o ti to, Nko n' ise kan t' o pe; Sibe ngo du ki nsogo pe Gbese mi l' o po ju. Source: Baptist Hymnal #303 For mercies, countless as the sands, Which daily I receive From Jesus, my Redeemer's hands, My soul what canst thou give? Alas! from such a heart as mine, What can I bring him forth? My best is stained and dyed with sin, My all is nothing worth. Yet this acknowledgment I'll make For all he has bestowed; Salvation's sacred cup I'll take And call ...

Halleluyah, Halleluyah

Writer:  Christopher Wordsworth (1807-1885), 1862 Halleluyah, Halleluyah, E gbe ohun ayo ga, E korin inudidun, K' e si yin olorun wa, Enit'a kan m'agbelebu, T' o jiya fun ese wa; Jesu Kristi Oba ogo Jinde kuro n'nu oku. Irin idabu se kuro Kristi ku, O sit un ye, O mu iye at aiku Wa l'oro ajinde Re; Krist' ti' segun, awa segun Nipa agbara nla Re, Awa o jinde pelu Re, A o ba wo 'nu ogo. Kristi jinde, akobi ni Ninu awon t' o ti sun, Awon yi ni y' o ji dide, Ni abo Re ekeji; Ikore ti won ti pon tan Nwon  nreti  Olukore, Eniti y'o mu won kuro, Ninu isa oku won. Awa jinde pelu Kristi T'O nfun wa l' ohun gbogbo Ojo, iri, ati ogo To ntan jade l' oju Re; Oluwa b' a ti wa l'aiye, Fa okan wa s'odo Re, K'awon maleka saw a jo, Ki  nwon  ko wa d,odo Re. Halleluyah, Halleluyah! Ogo ni fun Olorun; Halleluyah f' Olugbala Enit' Osegun iku....

Krist' Oluwa Ji Loni

Writer:  Charles Wesley Krist' Oluwa ji loni, - Halleluyah, Eda at' Angeli nwi - Hal. Gb' ayo at' isegun ga - Hal. K' orun at' aiye gberin! - Hal. Ise ti idande tan; - Hal. O jija, O ti segun; - Hal. Wo, 'ponju orun koja - Hal. Ko wo sinu eje mo - Hal. Lasan n' iso at' ami, - Hal. Krist' woo run apadi; - Hal Lasan l' agbara iku, - Hal. Krist, si Paradise. - Hal. O tun wa, Oba ogo: - Hal. "Iku itani re wa?" - Hal. Lekan l' O ku k' O gba wa, - Hal. "'Boji, isegun re wa?" - Hal. E je k' awa goke lo, - Hal. Sodo Kristi Ori wa, - Hal. A sa jinde pelu Re, - Hal. Bi a ti ku pelu Re. - Hal. Oluwa t' aiye t' orun, - Hal. Tire ni gbogbo iyin, - Hal. A wole niwaju Re - Hal. 'Wo Ajinde at' Iye. - Hal. Source: Baptist Hymnal #118 Christ the Lord is ris’n today, Alleluia! Sons of men and angels say, Alleluia! Raise your joys an...

O KU! ORE ELESE KU / HE DIES! THE FRIEND OF SINNERS DIES!

Writer:  Isaac Watts O ku! - Ore elese ku; Omobirin Salem' sokun; Okunkun bo oju orun, Ile wariri lojiji. Ife at' ikanu l; eyi Oluwa Ogo ku f'enia! Sugbon ayo wo l'a ri yi - Jesu t' Oku tun ji dide! Olorun ko boji sile, O  lo s'agbala Baba Re. Ogun Angeli sin lo 'le, Nwon si fi ayo gba s' oke, Ma sokun mo, enyin mimo, K' e so giga ijoba Re; Korin b' O ti segun Esu, T' O si de iku li ewon. E wipe, "Oba wa titi, Enit' a bi lati gba la!" E b' iku pe, "Oro re da?" Isa-oku, "'Segun re da?" Source: Baptist Hymnal #119 He dies! the Friend of sinners dies! Lo! Salem’s daughters weep around; A solemn darkness veils the skies, A sudden trembling shakes the ground. Come, saints, and drop a tear or two For Him who groaned beneath your load: He shed a thousand drops for you, A thousand drops of richer blood. Here’s love and grief...

E JE KA FINU DIDUN

Writer:  John Milton (1608-1674), 1623 E je k' a f' inu didun, Yin Oluwa Olore; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. O'n, nipa agbara Re, F' imole s' aiye titun; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. O mbo awon alaini, Ati gbogbo alaye; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. O bukun ayanfe Re Li aginju iparun; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. E je k' a f' inu didun, Yin Oluwa Olore; Anu Re, o wa titi, L' ododo dajudaju. Source: Baptist Hymnal #79 Let us, with a gladsome mind, praise the Lord, for he is kind: Refrain: for his mercies aye endure, ever faithful, ever sure. Let us blaze his Name abroad, for of gods he is the God: He with all commanding might filled the new-made world with light: He the gold-tressèd sun caused all day his course to run:  The horned moon to shine by night, mid her spangled sisters bright: All things livi...

N'nu Krist' Nikan/ In Christ Alone

Authors: Stuart Townend & Keith Getty N'nu Krist' nikan nireti mi, O'n n'imọlẹ, agbar', orin mi; Igun-ile yii, Apata yii, Wa sibẹ nin' ọda 'ti'ji. Ifẹ giga, ibalẹ okan, 'Gbati 'bẹru, idamu pin! Olutunu, Oun ni mo ni, Nihin mo duro 'n'fẹ Kristi . N'nu Krist' nikan, t'O wa leeyan Ọlọrun to wa bí ìkókó! Ẹbun 'fẹ yii at' ododo T'awọn t'O wa gbala kẹgan: Lori igi ti Jesu ku, Irunu Ọlọrun walẹ- Tori pẹ'ṣẹ wa lo gberu; Nihin mo ye n'nu 'ku Kristi. Nibẹ 'nu 'lẹ l'oku Rẹ wa Imọlẹ aye t'ookun pa: Lẹyin eyi lọjọ ologo O ji dide kuro 'nu oku! B'O si ti duro n'iṣẹgun Mo bọ lọwọ egun ẹṣẹ, Mo jẹ Tirẹ, Oun temi- Emi ta fẹjẹ Kristi ra. Niye, niku, ko si 'foya, Agbara Kristi 'nu mi ni; Lati 'bẹrẹ titi dopin, Jesu gba ayanmo mi mu. Ogun eṣu, ete aye Ki yoo le gba mi lowo Rẹ, 'Ti y' O fi de, tabi pe mi Nihin n o 'ró n'nú ...