Ìyanu, Aláàánú Olùgbàlà / Wonderful, Merciful Saviour
Authors: Dawn Rodgers / Eric Wyse Ìyanu, Olùgbàlà aláàánú, Olùràpadà , ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n Ta ni 'bá rò p' Ọ̀d'àgùntàn Lè gbọkàn èèyàn là Àní, O gbọkàn ènìyàn là Olùdámọ̀ràn, Olùtùnú, Olùpamọ́ Ẹ̀mí ta fẹ́ fà mọ́ra O fún wa n'rètí gbọkàn wa Ti rìnnà ṣáko lọ Àní, a ti rìnnà ṣáko lọ. Ègbè Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Èdùmàrè, Baba àìlópin, O fẹ́ wa ní òtítọ́ N'nú àìlera wa la wólẹ̀ Níwájú ìtẹ́ Rẹ Àní, ní iwájú ìtẹ́ Rẹ Ègbè Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (30/04/2020) Wonderful, merciful Saviour Precious Redeemer and Friend Who would've thought t...