Wọn Yoo Ṣe 'Ranti / Only Remembered
Author: Horatius Bonar A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀ T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo, Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. ÈGBÈ: Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe, Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa, Lati maa kore oko t' a ti gbìn?, Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe. Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé, Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii, Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa, Eso ikore at' on t' a ti ṣe. 'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀, T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn, 'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀, T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe. Source: Facebook Fading away like the stars of t...