Ìyanu, Aláàánú Olùgbàlà / Wonderful, Merciful Saviour
  Authors: Dawn Rodgers / Eric Wyse      Ìyanu, Olùgbàlà  aláàánú,  Olùràpadà , ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n  Ta ni 'bá rò p' Ọ̀d'àgùntàn  Lè gbọkàn èèyàn là  Àní, O gbọkàn ènìyàn là    Olùdámọ̀ràn, Olùtùnú, Olùpamọ́  Ẹ̀mí ta fẹ́ fà mọ́ra  O fún wa n'rètí gbọkàn wa  Ti rìnnà ṣáko lọ   Àní, a ti rìnnà ṣáko lọ.    Ègbè    Ìwọ l' Ẹni tí a yìn  Ìwọ l' Ẹni tí a júbà   O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́  Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún  Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún   Èdùmàrè, Baba àìlópin,   O fẹ́ wa ní òtítọ́   N'nú àìlera wa la wólẹ̀   Níwájú ìtẹ́ Rẹ   Àní, ní iwájú ìtẹ́ Rẹ    Ègbè    Ìwọ l' Ẹni tí a yìn  Ìwọ l' Ẹni tí a júbà   O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́  Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún  Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún    Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (30/04/2020)              Wonderful, merciful Saviour  Precious Redeemer and Friend  Who would've thought t...