Posts

Onibu Ore /Giver of All

  Author: Christopher Wordsworth Oluwa ọrún oun aye Wo n'iyin at’ope ye fun Bawo la ba ti fe O to! Onibu ore Orun ti n ran at’afefe Gbogbo eweko nso ’fe Re Wo lo nmu irugbin dara Onibu ore Fun ara lile wa gbogbo Fun gbogbo ibukun aye Awa yin O, a si dupe Onibu ore O ko du wa ni omo re O fi fun aye ese wa Pelu Re l'ofe l'O n fun wa L' ohun gbogbo. O fun wa l'Emi Mimo Re Emi iye at’agbara O ro’jo ekun ’bukun Re Le wa lori   Fun idariji ese wa, Ati fun ireti orun, Ki lohun ta ba fi fun O, Onibu ore?   Owo ti a n na, ofo ni, Sugbon eyi ta fi fun O O je isura tit’ aye Onibu ore Ohun ta bun O, Oluwa Wo o san le pada fun wa Layo la ta O lore Onibu ore. Ni odo Re l’a ti san wa, Olorun Olodumare, Je ka le ba O gbe titi Onibu ore. Amin. Source: CAC YORUBA&ENGLISH HYMNAL #662 O Lord of heaven and earth and sea, To Thee all praise and glory be; How shall we show our love to Thee, Giver of all? The golden sunshine, vernal air, Sweet flowers and fruits, Thy love declare Wher...

Alleluya! Kọrin sí Jésù! / Alleluia! Sing to Jesus!

Author: William Chatterton Dix (1866) Alleluya! Kọrin sí Jésù!  Tirẹ̀ lọ̀pá, Tirẹ̀ nìtẹ́;  Alleluya! Ó jagunmólú,  Tirẹ̀ nìkan ni ìsẹ́gun  Gbọ́! orin Sion' 'írọ̀rùn  Sán àrá bí ìgbì omi Jésù láti ilẹ̀ gbogbo Rà wá padà pẹ̀l' ẹ́jẹ̀ Rẹ̀.  Allelúyà! Kò fi wá sílẹ̀  Láti ṣọfọ bí òrukàn  Alleluya! O súnmọ́ wa  'Gbàgbọ́ kìí bèèrè pé báwo:  Bí 'kukù tilẹ̀ bojúu Rẹ̀  Lẹ́yìn ogójì ọjọ́  A óò ha gbàgbé ìlérí Rẹ̀,  'Mo wà pẹ̀lú yín dópin.' Alleluya! Àkàrà ángẹ́l',  'Wọ lóunjẹ àti wíwà wa Alleluya! Níhìn ẹlẹ́ṣẹ̀— Ń sá tọ́ Ọ́ ní ojúmọ́:  Olùbẹ̀bẹ̀, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́sẹ,  Olùràpadà, bẹ̀bẹ̀ fún mi,  Níb' orin àwọn ẹni mímọ́  Ti n la òkun krístálì jà.  Alleluya! Ọba àìkú,  Olúwa àwọn olúwa tiwa;  Alleluya! Ọmọ Mary,  Ayé nìtisẹ̀, ọ̀run nìtẹ́:  Ìwọ gba ikele kọjá  Olórí Àlùfáà wa; Àlùfáà àti ìrúbọ Ni àsè Yúkárístì.  Translated t...

Jesu, Ise Re L'o/Thy Works, Not Mine, O Christ

Author: George R. Prynne JESU, ise Re l'o Fi ayo s'okan mi, Nwon ni, o ti pari, Ki eru mi ko tan: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Jesu, ogbe Re l'o Le m'okan mi jina; N'nu 'ya Re ni mo ri Iwosan f'ese mi: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Agbelebu Tire L'o gbe eru ese, T'enikan ko le gbe, Lehin Om'Olorun: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Ki se iku t'emi L'o san irapada; Egbarun bi t'emi Ko to, o kere ju; Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Source: YBH 238 Thy works, not mine, O Christ, Speak gladness to this heart; They tell me all is done; They bid my fear depart. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee?  Thy pains, not mine, O Christ, Upon the shameful tree, Have paid the law’s full price And purchased peace for me. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee? Thy cross, not mine, O Christ,...

Jésù Onírẹ̀lẹ̀/Jesus, Meek and Gentle

Author: George R. Prynne Jesu Onirele, Omo Olorun: Alanu, Olufe, Gbo 'gbe omo Re. Fi ese wa jin wa Si da wa n' ide; Fo gbogbo orisa, Ti mbe l' okan wa. Fun wa ni omnira, F' ife s' okan wa; Fa wa Jesu mimo, S' ibugbe l' oke. To wa l' ona ajo, Si je ona wa; Ja okunkun aiye, S' imole orun. Jesu Onirele Omo Olorun, Alanu, olufe, Gbo gbe omo Re. Source: YBH #549 Jesus, meek and gentle, Son of God most High, Pitying, loving Savior, Hear Thy children’s cry. Pardon our offences, Loose our captive chains, Break down every idol Which our soul detains. Give us holy freedom, Fill our heart with grace; Lead us on our journey, Till we win the race. Jesus, meek and gentle, Son of God most high, Pitying, loving Savior, Hear Thy children’s cry. Source  

Gbayé Mi, Darí Mi o / Take My Life, Lead Me Lord

Author: R. Maines Rawls Gbayé mi, dar í mi o, Gbayé mi,  dar í mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi,  dar í mi o, Gbayé mi,  dar í mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi, kọ́ mi o, Gbayé mi, kọ́ mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi, kọ́ mi o, Gbayé mi, kọ́ mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Èmi rèé, rán mi o,  Èmi rèé, rán mi o,  Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ. Èmi rèé, rán mi o,  Èmi rèé, rán mi o,  Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ. Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (08/06/2020) Take my life, lead me Lord, Take my life, lead me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, lead me Lord, Take my life, lead me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, teach me Lord, Take my life, teach me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, teach me Lord, Take my life, teach me Lord, Make my life useful to Thee. Here am I, send...

Káàkiri Ayé / All Over The World world

Image
Káàkiri ayé Ẹ̀mí ń rábabà,   Káàkiri ayé báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Káàkiri ayé ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Yíká ìjọ Rẹ̀ Ẹ̀mí ń rábabà,   Yíká ìjọ Rẹ̀ báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Yíká ìjọ Rẹ̀ ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Ní ìhín yìí Ẹ̀mí ń rábabà,   Ní ìhín yìí báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Ní ìhín yìí ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (02/06/2020) All over the world the Spirit is moving, All over the world as the prophet said it would be; All over the world there's a mighty revelation Of the glory of the Lord, as the waters cover the sea. All over His church God's Spirit is moving, All over His church as the prophet said it would be; All over His church there's a mighty revelation Of the glory of the Lord, as the waters cover the sea. Right here in this place...

Olurapada Kan Wa / There Is A Redeemer

Image
Olurapada Kan wa Jésù, Ọm' Ọlọ́run  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Ẹni Mímọ́  Jésù Olùràpadà mi Orúkọ tó j' orúkọ lọ  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Tí a pa f' ẹlẹ́ṣẹ̀  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Gba m' bá dúró logo  N o rí ojú Rẹ  Níbẹ̀, n o sin Ọba mi títí  Ni ibi mímọ́ yẹn.  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Olurapada Kan wa Jésù, Ọm' Ọlọ́run  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Ẹni Mímọ́  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (28/05/2020) There is a redeemer Jesus, God's own Son Precious Lamb of God, Messiah Holy One Jesus my redeemer Name above all names Precious Lamb of God, Messiah Oh, for sinners slain Thank you, oh my fathe...