Posts

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yo Ninu Erofo/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbogbe labe 'binu  Jehofa, Ninu ogbun ti ese mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu erofo, T'O fi 'yonu fa mi yo sojo wura Egbe: O fa mi yo ninu erofo O gbese mi sori apata O f'orin sin' okan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata egbe Re, Isise mi mule, n o duro nibi; Ko sewu isubu 'gba mo wa nihin, Sugbon n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owuro, l'ale n o maa koo titi ni; Okan mi kun fayo, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o korin aanu iyanu Re si mi, N o yin tit' aye yoo fi mo p'O dara; N o korin 'gbala nile leyin odi, K'opo le gbotito Re k'ọn si gbaa gbo. N o royin ogbun ati okunkun re, N o yin Baba mi to gbo adura mi; N o korin titun, orin ayo t'ife, N o si gberin pel' awon mimo loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. My heart was distressed ...

FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH

Image
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye,  Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka  Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun.  Fun iyanu wakati  Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan,  Ọmọ 'ya, obi, ọmọ,  Ọrẹ aye, ọrẹ oke,  Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ  Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ,  Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth  For the glory of the skies,  For the love which from our birth  Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise,  This our hymn of grat...

E Yin! E Yin!/Praise Him! Praise Him!

Author: Fanny J. Crosby (1869) E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'orin aye, e kede 'fe nla Re! E kii! E kii! Eyin angeli ologo; F'ipa at'ola f'oruko Re mimo! B'Olus'aguntan, Jesu yoo s'awon 'mo Re, Lapa Re lo n gbe won lojojumo. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! Fun ese wa, o jiya, o si ku. Apata wa, ireti 'gbala ailopin, E kii! E kii! Jesu t'a kan mo'gi. E ro iyin Re! O ru ibanuje wa; Ife nla, to yanu, to jin, to ki. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'iro hosanna ko gba orun kan! Jesu Olugbala joba titi aye; E dee lade! Woli, Al'fa, Oba! Krist' n pada bo! Lori aye n'isegun, Agbara, ogo - t'Oluwa nii se. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (06/06/2023) Praise Him! Praise Him!  Jesus, our blessed Redeeme...

Ilu Wura /Golden City

Laipe idamu yin yoo pin Owo anu yoo gbe yin ga E o ri iran kedere Ilekun si ile miran Egbe A o pade ni ilu wura Ni Jerusalem' tuntun Gbogbo 'rora, omije wa ko ni si mọ́ A o dúró pẹ̀lú ogun ọrún A o ke mímọ̀ l'Oluwa  A o sin, a o juba Rẹ títí ayé.  Baba yoo ki wa ku abo Igbasoke lo sile Iduro wa ti de opin A wole ni ite Re Ka ma rii, agbara okunkun Tabi iku tabi iye Ko si oun to le ya Kuro n'nu 'fe Oluwa Afara Mimo, mimo l'Odo Aguntan (Mimo, mimo l'Odo Aguntan) (Mimo ni O) Mimo, mimo l'Odo Aguntan Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 23/05/2021 Soon your trials will be over Offered up by mercy's hand A better view than where you're standing A doorway to another land The sweetest welcome from the Father Gathered up and carried home We are past this time of waiting Come let us bow before Your throne Refrain We will meet in the Golden City in the New Jerusalem All our pain and all our tears will be...

Onibu Ore /Giver of All

  Author: Christopher Wordsworth Oluwa ọrún oun aye Wo n'iyin at’ope ye fun Bawo la ba ti fe O to! Onibu ore Orun ti n ran at’afefe Gbogbo eweko nso ’fe Re Wo lo nmu irugbin dara Onibu ore Fun ara lile wa gbogbo Fun gbogbo ibukun aye Awa yin O, a si dupe Onibu ore O ko du wa ni omo re O fi fun aye ese wa Pelu Re l'ofe l'O n fun wa L' ohun gbogbo. O fun wa l'Emi Mimo Re Emi iye at’agbara O ro’jo ekun ’bukun Re Le wa lori   Fun idariji ese wa, Ati fun ireti orun, Ki lohun ta ba fi fun O, Onibu ore?   Owo ti a n na, ofo ni, Sugbon eyi ta fi fun O O je isura tit’ aye Onibu ore Ohun ta bun O, Oluwa Wo o san le pada fun wa Layo la ta O lore Onibu ore. Ni odo Re l’a ti san wa, Olorun Olodumare, Je ka le ba O gbe titi Onibu ore. Amin. Source: CAC YORUBA&ENGLISH HYMNAL #662 O Lord of heaven and earth and sea, To Thee all praise and glory be; How shall we show our love to Thee, Giver of all? The golden sunshine, vernal air, Sweet flowers and fruits, Thy love declare Wher...

Alleluya! Kọrin sí Jésù! / Alleluia! Sing to Jesus!

Author: William Chatterton Dix (1866) Alleluya! Kọrin sí Jésù!  Tirẹ̀ lọ̀pá, Tirẹ̀ nìtẹ́;  Alleluya! Ó jagunmólú,  Tirẹ̀ nìkan ni ìsẹ́gun  Gbọ́! orin Sion' 'írọ̀rùn  Sán àrá bí ìgbì omi Jésù láti ilẹ̀ gbogbo Rà wá padà pẹ̀l' ẹ́jẹ̀ Rẹ̀.  Allelúyà! Kò fi wá sílẹ̀  Láti ṣọfọ bí òrukàn  Alleluya! O súnmọ́ wa  'Gbàgbọ́ kìí bèèrè pé báwo:  Bí 'kukù tilẹ̀ bojúu Rẹ̀  Lẹ́yìn ogójì ọjọ́  A óò ha gbàgbé ìlérí Rẹ̀,  'Mo wà pẹ̀lú yín dópin.' Alleluya! Àkàrà ángẹ́l',  'Wọ lóunjẹ àti wíwà wa Alleluya! Níhìn ẹlẹ́ṣẹ̀— Ń sá tọ́ Ọ́ ní ojúmọ́:  Olùbẹ̀bẹ̀, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́sẹ,  Olùràpadà, bẹ̀bẹ̀ fún mi,  Níb' orin àwọn ẹni mímọ́  Ti n la òkun krístálì jà.  Alleluya! Ọba àìkú,  Olúwa àwọn olúwa tiwa;  Alleluya! Ọmọ Mary,  Ayé nìtisẹ̀, ọ̀run nìtẹ́:  Ìwọ gba ikele kọjá  Olórí Àlùfáà wa; Àlùfáà àti ìrúbọ Ni àsè Yúkárístì.  Translated t...