Posts

MO FERAN RE JESU / MY JESUS I LOVE THEE

Authors: James H. Duffel (1862); William R. Featherston (1862) Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi Mo feran re Jesu ju t'ateyin wa  Mo feran Re ni iye ati ni iku  N o ma yin Oruko Re gba m' ba wa laye  Gba temi mi ba n lo tojo mi n buse  Sibe n o feran Re tit'ojo aye mi  Ile ewa wonni bo ti dara to  N o dapo mawon mimo lati maa yin o Pelu ade wura lem'o ma yin O N o feran Re Jesu laye ati lorun  Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi  N o feran Re ju tateyin lo. Source: Orin Duru My Jesus, I love thee, I know thou art mine; For thee all the follies of sin I resign; My gracious Redeemer, my Saviour art thou; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I love thee because thou hast first loved me And purchased my pardon on Calvary’s tree; I love thee for wearing the thorns on thy brow; If ever I love...

Jesu to Lewa Ju/ Fairest Lord Jesus

Author: Unknown Jesu to lẹwa ju, adari ẹda gbogbo Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan N o mọ riri Rẹ, n o bu ọla fun Ọ 'Wọ, ogo, ayọ, ade ọkan mi. Didara lawọn ọdan, sibẹ igi 'gbo dara ju Ta wọ pel' ogo igba 'ruwe Jesu dara julọ, Jesu funfun julọ O mọkan 'banujẹ kọrin Didara ni oorun, sibẹ oṣupa dara ju, Ati awọn irawọ ti n tan Jesu mọlẹ ju wọn, Jesu tan ju wọn lọ Ju gbogbo angẹli ni ọrun Olugbala arẹwa, Oluwa ilẹ gbogbo, Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan! Ogo ati ọla, iyin ati' juba, Ko jẹ Tirẹ titi lailai. Translated by Ayọbami Temitọpẹ Kẹhinde on 3rd April, 2024 Fairest Lord Jesus, ruler of all nature O thou of God and man the Son Thee will I cherish, Thee will I honour Thou, my soul's glory, joy, and crown Fair are the meadows, fairer still the woodlands Robed in the blooming garb of spring Jesus is fairer, Jesus is purer Who makes the woeful heart to sing Fair is the sunshine, fairer still the moonlight And all the ...

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yo Ninu Erofo/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Henry J. Zelley Author (refrain): H. L. Gilmour Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbọgbẹ labẹ 'binu  Jehofa, Ninu ọgbun ti ẹṣẹ mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu ẹrọfọ, T'O fi 'yọnu fa mi yọ sọjọ wura Egbe: O fa mi yọ ninu ẹrọfọ  O gbẹsẹ mi sori apata O f'orin sin' ọkan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata ẹgbẹ Rẹ, Iṣise mi mulẹ, n o duro nibi; Ko sewu iṣubu 'gba mo wa nihin, Ṣugbọn n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owurọ, l'alẹ n o maa kọọ titi ni; Ọkan mi fo fayọ, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o kọrin aanu iyanu Rẹ si mi, N o yin tit' aye yoo fi mo p'O dara; N o kọrin 'gbala nile lẹyin odi, K'ọpọ le gbotitọ Rẹ k'ọn si gbaa gbọ. N o royin ọgbun ati okunkun rẹ, N o yin Baba mi to gbọ adura mi; N o kọrin titun, orin ayọ t'ifẹ, N o si gberin pẹl' awọn mimọ loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. ...

FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH

Image
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye,  Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka  Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun.  Fun iyanu wakati  Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan,  Ọmọ 'ya, obi, ọmọ,  Ọrẹ aye, ọrẹ oke,  Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ  Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ,  Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth  For the glory of the skies,  For the love which from our birth  Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise,  This our hymn of grat...

E Yin! E Yin!/Praise Him! Praise Him!

Author: Fanny J. Crosby (1869) E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'orin aye, e kede 'fe nla Re! E kii! E kii! Eyin angeli ologo; F'ipa at'ola f'oruko Re mimo! B'Olus'aguntan, Jesu yoo s'awon 'mo Re, Lapa Re lo n gbe won lojojumo. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! Fun ese wa, o jiya, o si ku. Apata wa, ireti 'gbala ailopin, E kii! E kii! Jesu t'a kan mo'gi. E ro iyin Re! O ru ibanuje wa; Ife nla, to yanu, to jin, to ki. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'iro hosanna ko gba orun kan! Jesu Olugbala joba titi aye; E dee lade! Woli, Al'fa, Oba! Krist' n pada bo! Lori aye n'isegun, Agbara, ogo - t'Oluwa nii se. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (06/06/2023) Praise Him! Praise Him!  Jesus, our blessed Redeeme...

Ilu Wura /Golden City

Laipe idamu yin yoo pin Owo anu yoo gbe yin ga E o ri iran kedere Ilekun si ile miran Egbe A o pade ni ilu wura Ni Jerusalem' tuntun Gbogbo 'rora, omije wa ko ni si mọ́ A o dúró pẹ̀lú ogun ọrún A o ke mímọ̀ l'Oluwa  A o sin, a o juba Rẹ títí ayé.  Baba yoo ki wa ku abo Igbasoke lo sile Iduro wa ti de opin A wole ni ite Re Ka ma rii, agbara okunkun Tabi iku tabi iye Ko si oun to le ya Kuro n'nu 'fe Oluwa Afara Mimo, mimo l'Odo Aguntan (Mimo, mimo l'Odo Aguntan) (Mimo ni O) Mimo, mimo l'Odo Aguntan Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 23/05/2021 Soon your trials will be over Offered up by mercy's hand A better view than where you're standing A doorway to another land The sweetest welcome from the Father Gathered up and carried home We are past this time of waiting Come let us bow before Your throne Refrain We will meet in the Golden City in the New Jerusalem All our pain and all our tears will be...