Posts

Ọkàn, O Ha Ń Ṣàárẹ̀ / O Soul, Are You Weary

Author: Lemmel, Helen Howarth Ọkàn, o ha ń ṣàárẹ̀, o ń dààmú Òkùn ṣú kò sí ìmọ́lẹ̀ 'Mọ́lẹ̀ wà t'o bá w'Olùgbàlà 'Yè lọ́pọ̀lọpọ̀ àt' ọ̀fẹ́  Kọ ojú rẹ sí Jésù  Wò ojú ìyanu Rẹ̀  Àwọn nǹkan ayé yóò si di bàìbàì  N'nú 'mọ́lẹ̀ ògo, or' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Láti 'kú lọ s' íyè àínìpẹ̀kun O kọjá, a sì tẹ̀le lọ Lórí i wa ẹ̀ṣẹ̀ kò lágbára  Àwá ju aṣẹ́gun lọ  Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ k'yo' kùnà, Ó lérí Gbà á gbọ́, yóò dára fún ọ  Sì lọ sí ayé tí ń kú lọ  Sọ ti ìgbàlà pípé' Rẹ̀  Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 12th April, 2024 O soul, are you weary and troubled? No light in the darkness you see? There’s light for a look at the Saviour, And life more abundant and free! Turn your eyes upon Jesus, Look full in His wonderful face, And the things of earth will grow strangely dim, In the light of His glory and grace. Through death into life everlasting He passed, and we follow Him there; O’er us sin no more h...

MO FERAN RE JESU / MY JESUS I LOVE THEE

Authors: James H. Duffel (1862); William R. Featherston (1862) Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi Mo feran re Jesu ju t'ateyin wa  Mo feran Re ni iye ati ni iku  N o ma yin Oruko Re gba m' ba wa laye  Gba temi mi ba n lo tojo mi n buse  Sibe n o feran Re tit'ojo aye mi  Ile ewa wonni bo ti dara to  N o dapo mawon mimo lati maa yin o Pelu ade wura lem'o ma yin O N o feran Re Jesu laye ati lorun  Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi  N o feran Re ju tateyin lo. Source: Orin Duru My Jesus, I love thee, I know thou art mine; For thee all the follies of sin I resign; My gracious Redeemer, my Saviour art thou; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I love thee because thou hast first loved me And purchased my pardon on Calvary’s tree; I love thee for wearing the thorns on thy brow; If ever I love...

Jesu to Lewa Ju/ Fairest Lord Jesus

Author: Unknown Jesu to lẹwa ju, adari ẹda gbogbo Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan N o mọ riri Rẹ, n o bu ọla fun Ọ 'Wọ, ogo, ayọ, ade ọkan mi. Didara lawọn ọdan, sibẹ igi 'gbo dara ju Ta wọ pel' ogo igba 'ruwe Jesu dara julọ, Jesu funfun julọ O mọkan 'banujẹ kọrin Didara ni oorun, sibẹ oṣupa dara ju, Ati awọn irawọ ti n tan Jesu mọlẹ ju wọn, Jesu tan ju wọn lọ Ju gbogbo angẹli ni ọrun Olugbala arẹwa, Oluwa ilẹ gbogbo, Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan! Ogo ati ọla, iyin ati' juba, Ko jẹ Tirẹ titi lailai. Translated by Ayọbami Temitọpẹ Kẹhinde on 3rd April, 2024 Fairest Lord Jesus, ruler of all nature O thou of God and man the Son Thee will I cherish, Thee will I honour Thou, my soul's glory, joy, and crown Fair are the meadows, fairer still the woodlands Robed in the blooming garb of spring Jesus is fairer, Jesus is purer Who makes the woeful heart to sing Fair is the sunshine, fairer still the moonlight And all the ...

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yo Ninu Erofo/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbogbe labe 'binu  Jehofa, Ninu ogbun ti ese mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu erofo, T'O fi 'yonu fa mi yo sojo wura Egbe: O fa mi yo ninu erofo O gbese mi sori apata O f'orin sin' okan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata egbe Re, Isise mi mule, n o duro nibi; Ko sewu isubu 'gba mo wa nihin, Sugbon n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owuro, l'ale n o maa koo titi ni; Okan mi kun fayo, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o korin aanu iyanu Re si mi, N o yin tit' aye yoo fi mo p'O dara; N o korin 'gbala nile leyin odi, K'opo le gbotito Re k'ọn si gbaa gbo. N o royin ogbun ati okunkun re, N o yin Baba mi to gbo adura mi; N o korin titun, orin ayo t'ife, N o si gberin pel' awon mimo loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. My heart was distressed ...

FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH

Image
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye,  Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka  Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun.  Fun iyanu wakati  Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan,  Ọmọ 'ya, obi, ọmọ,  Ọrẹ aye, ọrẹ oke,  Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ  Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ,  Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth  For the glory of the skies,  For the love which from our birth  Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise,  This our hymn of grat...

E Yin! E Yin!/Praise Him! Praise Him!

Author: Fanny J. Crosby (1869) E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'orin aye, e kede 'fe nla Re! E kii! E kii! Eyin angeli ologo; F'ipa at'ola f'oruko Re mimo! B'Olus'aguntan, Jesu yoo s'awon 'mo Re, Lapa Re lo n gbe won lojojumo. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! Fun ese wa, o jiya, o si ku. Apata wa, ireti 'gbala ailopin, E kii! E kii! Jesu t'a kan mo'gi. E ro iyin Re! O ru ibanuje wa; Ife nla, to yanu, to jin, to ki. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'iro hosanna ko gba orun kan! Jesu Olugbala joba titi aye; E dee lade! Woli, Al'fa, Oba! Krist' n pada bo! Lori aye n'isegun, Agbara, ogo - t'Oluwa nii se. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (06/06/2023) Praise Him! Praise Him!  Jesus, our blessed Redeeme...