Posts

Ko To K' awon Mimo Beru / The Saints Should Never Be Dismayed

Author: Cowper William Ko to k' awon mimo beru, Ki nwon so 'reti nu; 'Gba nwon ko reti 'ranwo Re, Olugbala yio de. Nigbati Abram mu obe, Olorun ni, "Duro;" Agbo ti o wa lohun ni Y'o dipo omo na." Dafid' dabi eran Soolu; Sugbon gbo! ota de! Soolu yi owo re pada Lati ja fun 'le naa. Gba Jona ri sinu omi, Ko ro lati yo mo; Sugbon Olorun ran eja T' o gbe lo s' ebute. B' iru ipa at' ife yi Ti po l' oro Re to! Emi ba ma k' aniyan mi Le Oluwa lowo! E duro de iranwo Re, B' o tile pe, duro; B' ileri na tile fa 'le Sugbon ko le pe de. Source: Stanzas 1, 2, 4, 5 & 6 from YBH #579 Stanza 3 translated by Ayobami Temitope Kehinde (08/16/2019) The saints should never be dismayed, Nor sink in hopeless fear; For when they least expect His aid, The Savior will appear. This Abr’am found: he raised the knife; God saw, and said, Forb

Jesu, Agbara Mi / Jesus, My Strength, My Hope

Words:  Charles Wesley ,  Hymns and Sacred Poems  1742. Jesu, agbara mi, Iwo l' aniyan mi, Emi fi igbagbo w' oke, Iwo l' O ngb'adua. Jeki nduro de O, Ki nle se ife Re, Ki Iwo Olodumare K'o so mi di otun. Fun mi l' okan 'rele, Ti 'ma se ara re; Ti ntemole, ti ko nani Ikekun Satani: Okan t' ara re mo Irora at' ise; T' o nfi suru at' igboya Ru agbelebu re. Fun mi l' eru orun, Oju t' o mu hanhan, T'y'o wo O n'gb' ese sunmole, K' o ri b' Esu ti nsa. Fun mi ni emi ni, T' O ti pese tele. Emi t' o duro gangan lai T' o nf' adura s' ona. Mo fokan adura, Adura n'gba gbogbo, Ki n ma se kun s' ibawi Re, Ki n farada 'soro. 'Bukun to ga julo: Ki n gbadura n'gba gbogbo Lati 'nu ibu mo ke pe O, Ki n ma se rewesi. Mo fe 'bowo tooto, Ete kan to duro, Laifotape, emi o duro Fun O, f'oruko Re. Itara to gbona

Ohun Gbogbo Tàn, Ó Lẹ́wà / All Things Bright And Beautiful

Author: Mrs Cecil Alexander Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (15/08/2019) 1. Ohun gbogbo tàn,  o lẹwa Ẹda nla, kekere Ohun gbogbo gbọ́n, ó n yanu Ọlọ́run dá gbogbo wọn.  2. 'Tanna kekere to ṣi Ẹyẹ bintin to n kọrin O da awọ didan wọn, Iyẹ wọn tintinni. Ohun gbogbo tan...  3. Ọlọ́rọ̀ 'nu gọ̀bì rẹ, Talaka lẹnu ọna rẹ, O da wọn nipo depo, O paṣẹ ipo wọn. Ohun gbogbo tan...  4. Oke ese aluko, Odo tí n ṣàn lọ, Ìrọ̀lẹ́ àt' òwúrọ̀, T'o n mofurufu tan. Ohun gbogbo tan...     5. Iji tutu n'nu ọyẹ, Orun igba ẹrun, Èso pipọn ni ọgbà,- Ó dá wọn lọkọ̀ọ̀kan. Ohun gbogbo tan...  6. Igi giga ninu 'gbo Ọdan ta ti n ṣere Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ẹ̀bá omi, Tá n pé jọ lójúmọ́. Ohun gbogbo tan...  7. O fojú fun wa lati ri Àt' ètè̀ ká lè sọ B'Edumare ti tobi to, To mohun gbogbo dara. Ohun gbogbo tan...  (Amin) 1. All things bright and beautiful, All creatures great and small, All things wise

Iwo Lo Ye / Thou Art Worthy

Author: Pauline Mills Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde Ìwọ ló yẹ, Ìwọ ló yẹ, 'Wọ ló yẹ, Olúwa Láti gba ògo, ògo àt' ọlá Ògo, ọlá, agbára. 'Torí Ìwọ ló dá ohun gbogbo 'Wọ ló dá ohun gbogbo Àti fún 'fẹ̀ Rẹ ni O ṣe dá wọn 'Wọ ló yẹ, Olúwa. Thou art worthy, Thou art worthy, Thou art worthy, O Lord. To receive glory, glory and honour Glory and honor and power. For Thou hast created, hast all things created, For Thou hast created all things. And for Thy pleasure they are created; Thou art worthy, O Lord.

Mimo, Mimo / Holy, Holy

Author: Jimmy Owens (1972)  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde Mimo, mimo, mimo, mimo, Mimo, mimo, Olodumare; A gbokan wa soke si O lati fi ife wa han, Mimo, mimo, mimo, mimo. Baba Oloore, Baba Oloore A soriire p'a je omo Re, Baba Oloore; A gbori wa soke si O lati fi ife wa han, Baba Oloore, Baba Oloore. Jesu owon, Jesu owon A yo pupo p'O ra wa pada, Jesu owon; A gbowo wa soke si O lati fi ife wa han, Jesu owon, Jesu owon.    Emi Mimo, Emi Mimo, Wa kunnu okan wa lotun, Emi Mimo; A gbohun wa soke si O lati fi ife wa han, Emi Mimo, Emi Mimo. Holy, holy, holy, holy, Holy, holy, Lord God Almighty; And we lift our hearts before You as a token of our love, Holy, holy, holy, holy. Gracious Father, gracious Father, We're so blest to be Your children, gracious Father; And we lift our heads before You as a token of our love, Gracious Father, gracious Father. Precious Jesus, precious Jesus, We're so glad that You

Halleluyah! Ogo Ni Fun Baba / Hallelujah! Glory To The Father

Author Unknown  Translated to English by Ayobami Temitope Kehinde Ẹ jẹ ka jumọ f'ọpẹ f'Ọlorun  Orin iyin, at'ọpẹ lo yẹ wa   Iyanu n'ifẹ Rẹ si gbogbo wa   Ẹ kọrin 'yin s'  Ọba Olore wa    Chorus:   Halleluyah! Ogo ni fun Baba   A f'ijo ilu yin Ọlọrun wa   Alaye ni o yin Ọ bo ti yẹ   Halleluyah! Ogo ni fun Baba     Ki l'a fi san j'awọn t'iku ti pa?   Iwọ lo f'ọwọ wọ wa di oni   'Wọ lo n sọ wa to n gba wa lọw'ewu   Ẹ kọrin 'yin s'Olutọju wa     Ohun wa ko dun to lati kọrin   Ẹnu wa ko gboro to fun ọpẹ   B'awa n'ẹgbẹrun ahọn nikọkan   Wọn kere ju lati gb'ọla Rẹ ga Let us give thanks to God together Songs of praises and thanks are befitting Marvelous is Your love to all of us Oh sing praises to our Gracious King Chorus: Hallelujah! Glory to the Father We praise our God with dances and drums Only the living will praise you properly Hallelujah! Glory to the F

Laarin Gbungbun Oye/ In The Bleak Midwinter

Image
Author: Christina Rossetti Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìjì dídì ń sọkún Ayé le bí irin Omi bí òkúta Yìnyín bọ́ lórí yìnyín Lórí yìnyín Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Lọ́jọ́ ọjọ́un Ọlọ́run wa, ọ̀run kò gbàá,  Ayé kò lè gbée ró Ọ̀run, ayé yóò kọjá lọ 'Gb' Ó bá wá jọba. Láàrín gbùngbùn ọyẹ́ Ìbùjẹ́ ẹran tó fún Olúwa Alágbára Jésù Kristi.  Ó tó f' Ẹni tí Kérúbù Ń sìn lọ́saǹ lóru: Ọmú tó kuń fún wàrà Koríko ilé ẹran Ó tó f' Ẹni t'Angel' Ń wólẹ̀ fún o, Màálù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ràkúnmí Tí ń júbà Rẹ̀ Angel' nípò dépò 'Bá péjọ síbẹ̀ Kérúbù, Séráfù 'Bá wa 'nú afẹ́fẹ́; Ṣùgbọn Màmá Rẹ̀ nìkan, Wúndíá pẹ̀l' áyọ́ Fi ìfẹnukonu Sin Àyànfẹ́. Kínni mo lè fi fún Un, Èmi òṣì, àre Ǹ bá j' olúṣ'àgùntàn, Ǹ bá  fún Un l' ọ̀d'àgùntàn Ǹ bá jẹ́ Amòye Ǹ bá sápá tèmi, — Síbẹ ohun mo ní, mo fún Un, — Ọkàn mi. Trans