Posts

Si Ọ Olutunu Ọrun/To Thee, O Comforter Divine

Author: Frances Ridley Havergal 1. Si O, Olutunu orun, Fun ore at’ agbara Re, A nko Alleluya. 2. Si O, ife enit’ o wa Ninu majemu Olorun, A nko Alleluya. 3. Si O, Ohun Eniti npe Asako kuro n’nu ese, A nko Alleluya. 4. Si O, agbara Eniti O n weni mo, t’ o nwo ni san, A nko Alleluia. 5. Si O, ododo Eniti Gbogbo ’leri Re je tiwa, A nko Alleluia. 6. Si O, Oluko at’ Ore, Amona wa toto d’ opin, A nko Alleluya. 7. Si O, Eniti Kristi ran, Ade o'n gbongbo ebun Re, A nko Alleluia. 8. Si O, Enit’ o je okan Pelu Baba ati Omo, A nko Alleluya. Amin. Source: Iwe Orin Mimo #278 1. To Thee, O Comforter divine, For all Thy grace and power benign, Sing we Alleluia! 2. To Thee, Whose faithful love had place In God's great covenant of grace, Sing we Alleluia! 3. To Thee, Whose faithful voice doth win The wandering from the ways of sin, Sing we Alleluia! 4. To Thee, Whose faithful power doth heal, Enlighten, sanctify, and seal, Sing we Alleluia! 5. To Thee, Whose faithful truth is shown By every pr...

Ki N Le Rin Sun Mọ Ọ Sii / Just A Closer Walk With Thee

Author: Unknown   Mo ṣaarẹ, O lagbara Jesu gba mi lọw’ ẹṣẹ N o nitẹlọrun n’wọn ’gba Mo ba Ọ rin, jẹ ki n le ba Ọ rin Egbe: Ki n le rin sun mọ Ọ sii Jesu, f’ ẹ̀bẹ̀ yii fun mi Ki n ba Ọ rin lojumọ  Je ko ṣẹ, Oluwa, je ko ṣẹ Laye 'ṣẹ́, ìkẹkùn yii Tí m' ba kùnà ta lo kan?  Ta ló ń bá mi gbẹ́rù mi Kò sí o, Oluwa, Ìwọ ni.  ’Gbà ’yé àíléra mi pin Tí ’gba mi láyé dópin Tọ́jú mi títí délé  ’Jọba Rẹ̀, àní ìjọba Rẹ Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 20/05/2024 I am weak but Thou art strong; Jesus, keep me from all wrong; I'll be satisfied as long As I walk, let me walk close to Thee. Refrain: Just a closer walk with Thee, Grant it, Jesus, is my plea, Daily walking close to Thee, Let it be, dear Lord, let it be. Thro' this world of toil and snares, If I falter, Lord, who cares? Who with me my burden shares? None but Thee, dear Lord, none but Thee. [Refrain] When my feeble life is o'er, Time for me will be no more; Gui...

Ọkàn, O Ha Ń Ṣàárẹ̀ / O Soul, Are You Weary

Author: Lemmel, Helen Howarth Ọkàn, o ha ń ṣàárẹ̀, o ń dààmú Òkùn ṣú kò sí ìmọ́lẹ̀ 'Mọ́lẹ̀ wà t'o bá w'Olùgbàlà 'Yè lọ́pọ̀lọpọ̀ àt' ọ̀fẹ́  Kọ ojú rẹ sí Jésù  Wò ojú ìyanu Rẹ̀  Àwọn nǹkan ayé yóò si di bàìbàì  N'nú 'mọ́lẹ̀ ògo, or' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Láti 'kú lọ s' íyè àínìpẹ̀kun O kọjá, a sì tẹ̀le lọ Lórí i wa ẹ̀ṣẹ̀ kò lágbára  Àwá ju aṣẹ́gun lọ  Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ k'yo' kùnà, Ó lérí Gbà á gbọ́, yóò dára fún ọ  Sì lọ sí ayé tí ń kú lọ  Sọ ti ìgbàlà pípé' Rẹ̀  Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 12th April, 2024 O soul, are you weary and troubled? No light in the darkness you see? There’s light for a look at the Saviour, And life more abundant and free! Turn your eyes upon Jesus, Look full in His wonderful face, And the things of earth will grow strangely dim, In the light of His glory and grace. Through death into life everlasting He passed, and we follow Him there; O’er us sin no more h...

MO FERAN RE JESU / MY JESUS I LOVE THEE

Authors: James H. Duffel (1862); William R. Featherston (1862) Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi Mo feran re Jesu ju t'ateyin wa  Mo feran Re ni iye ati ni iku  N o ma yin Oruko Re gba m' ba wa laye  Gba temi mi ba n lo tojo mi n buse  Sibe n o feran Re tit'ojo aye mi  Ile ewa wonni bo ti dara to  N o dapo mawon mimo lati maa yin o Pelu ade wura lem'o ma yin O N o feran Re Jesu laye ati lorun  Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi  N o feran Re ju tateyin lo. Source: Orin Duru My Jesus, I love thee, I know thou art mine; For thee all the follies of sin I resign; My gracious Redeemer, my Saviour art thou; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I love thee because thou hast first loved me And purchased my pardon on Calvary’s tree; I love thee for wearing the thorns on thy brow; If ever I love...

Jesu to Lewa Ju/ Fairest Lord Jesus

Author: Unknown Jesu to lẹwa ju, adari ẹda gbogbo Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan N o mọ riri Rẹ, n o bu ọla fun Ọ 'Wọ, ogo, ayọ, ade ọkan mi. Didara lawọn ọdan, sibẹ igi 'gbo dara ju Ta wọ pel' ogo igba 'ruwe Jesu dara julọ, Jesu funfun julọ O mọkan 'banujẹ kọrin Didara ni oorun, sibẹ oṣupa dara ju, Ati awọn irawọ ti n tan Jesu mọlẹ ju wọn, Jesu tan ju wọn lọ Ju gbogbo angẹli ni ọrun Olugbala arẹwa, Oluwa ilẹ gbogbo, Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan! Ogo ati ọla, iyin ati' juba, Ko jẹ Tirẹ titi lailai. Translated by Ayọbami Temitọpẹ Kẹhinde on 3rd April, 2024 Fairest Lord Jesus, ruler of all nature O thou of God and man the Son Thee will I cherish, Thee will I honour Thou, my soul's glory, joy, and crown Fair are the meadows, fairer still the woodlands Robed in the blooming garb of spring Jesus is fairer, Jesus is purer Who makes the woeful heart to sing Fair is the sunshine, fairer still the moonlight And all the ...

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yo Ninu Erofo/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Henry J. Zelley Author (refrain): H. L. Gilmour Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbọgbẹ labẹ 'binu  Jehofa, Ninu ọgbun ti ẹṣẹ mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu ẹrọfọ, T'O fi 'yọnu fa mi yọ sọjọ wura Egbe: O fa mi yọ ninu ẹrọfọ  O gbẹsẹ mi sori apata O f'orin sin' ọkan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata ẹgbẹ Rẹ, Iṣise mi mulẹ, n o duro nibi; Ko sewu iṣubu 'gba mo wa nihin, Ṣugbọn n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owurọ, l'alẹ n o maa kọọ titi ni; Ọkan mi fo fayọ, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o kọrin aanu iyanu Rẹ si mi, N o yin tit' aye yoo fi mo p'O dara; N o kọrin 'gbala nile lẹyin odi, K'ọpọ le gbotitọ Rẹ k'ọn si gbaa gbọ. N o royin ọgbun ati okunkun rẹ, N o yin Baba mi to gbọ adura mi; N o kọrin titun, orin ayọ t'ifẹ, N o si gberin pẹl' awọn mimọ loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. ...