Wọn Yoo Ṣe 'Ranti / Only Remembered
  Author: Horatius Bonar A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀ T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo,  Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,  A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  ÈGBÈ:  Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe,  Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,  A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa, Lati maa kore oko t' a ti gbìn?,  Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀,   A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé,  Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii,  Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa,  Eso ikore at' on t' a ti ṣe.  'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀,  T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn,  'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀,  T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe. Source: Facebook    Fading away like the stars of t...